ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 4/1 ojú ìwé 8
  • Ǹjẹ́ Ó Ṣe Pàtàkì Kí Á Mọ Ìdáhùn Tó Tọ̀nà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ó Ṣe Pàtàkì Kí Á Mọ Ìdáhùn Tó Tọ̀nà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Òtítọ́ Yóò Dá Yín Sílẹ̀ Lómìnira’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ṣé Òtítọ́ Ṣì Lérè?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àwọn Kristẹni Ń jọ́sìn Ní Ẹ̀mí Àti Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Báwo Lo Ṣe Lè Wà Láàyè Títí Láé?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 4/1 ojú ìwé 8

Ǹjẹ́ Ó Ṣe Pàtàkì Kí Á Mọ Ìdáhùn Tó Tọ̀nà?

“Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—JÒHÁNÙ 8:32.

ÒTÍTỌ́ tó lè mú kí á bọ́ lọ́wọ́ onírúurú èrò tó ń rúni lójú nípa Jésù tàbí èrò tó tiẹ̀ lòdì nípa rẹ̀, wà nínú Bíbélì. Àmọ́, ohun yòówù kéèyàn gbà gbọ́ nípa Jésù, ǹjẹ́ ìyẹn tiẹ̀ ṣe pàtàkì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe pàtàkì. Ó ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. Ó ṣe pàtàkì lójú Jésù. Ó sì yẹ kó ṣe pàtàkì lójú àwa náà.

● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì lójú Jèhófà? Ní kúkúrú, ìdí ni pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ṣe ni Jèhófà fẹ́ ká wà láàyè títí láé, ká sì máa láyọ̀. Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé [aráyé] tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ . . . lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé kó wá rà wá pa dà, kó sì mú kí ó lè ṣeé ṣe fún wa láti máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé títí láé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ó ń wu Ọlọ́run láti fi ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn tó bá mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọmọ rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n mọ̀ yẹn.—Róòmù 6:23.

● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì lójú Jésù? Jésù náà fẹ́ràn aráyé. Ìfẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ tó ní yìí ló mú kó fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. (Jòhánù 15:13) Ó mọ̀ pé ohun tí òun ṣe yẹn ló máa jẹ́ kí ọ̀nà kan ṣoṣo tí aráyé lè gbà rí ìgbàlà ṣí sílẹ̀. (Jòhánù 14:6) Ǹjẹ́ ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Jésù fẹ́ kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn jàǹfààní ẹbọ ìràpadà òun? Ó tì o. Ìyẹn ló fi sọ pé kí àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn òun lọ máa kọ́ àwọn èèyàn kárí ayé nípa ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run àti gbogbo ète rẹ̀.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.

● Kí nìdí tó fi yẹ kó ṣe pàtàkì lójú tiwa? Ronú ná nípa àwọn nǹkan tó dájú pé ó jẹ ọ́ lógún gan-an, ìyẹn ìlera rẹ àti ti ìdílé rẹ. Ǹjẹ́ ó máa ń wù ọ́ gan-an pé kí ara ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ le koko kí ẹ sì máa gbádùn ayé yín? Jèhófà tipasẹ̀ Jésù nawọ́ àǹfààní ńlá kan sí ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ, ìyẹn àǹfààní láti ní ìlera pípé, kí ẹ sì máa gbé nínú ayé tuntun títí láé, níbi tí kò ti ní sí ìrora àti ìyà mọ́. (Sáàmù 37:11, 29; Ìṣípayá 21:3, 4) Ṣé wàá fẹ́ láti máa gbé nínú irú ayé bẹ́ẹ̀? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ohun kan wà tí o ní láti ṣe.

Tún pa dà wo ẹsẹ Bíbélì tí a kọ sí ìsàlẹ̀ àkòrí àpilẹ̀kọ yìí lókè, èyí tó sọ pé: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” Tí a bá mọ òtítọ́ nípa Jésù àti ipa tí ó ń kó nínú bí ète Ọlọ́run ṣe ń ṣẹ, èyí lè dá wa nídè kúrò nínú ìsìnrú tó burú jù lọ, ìyẹn kúrò nínú oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àmọ́ ṣá o, kí o tó lè rí ìdáǹdè yẹn gbà, o ní láti “mọ òtítọ́.” Nítorí náà, o ò ṣe túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa òtítọ́ yìí àti bí ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ ṣe lè jàǹfààní nínú rẹ̀? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́