‘Òtítọ́ Yóò Dá Yín Sílẹ̀ Lómìnira’
“Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” Ohun tí Jésù sọ nìyẹn nígbà tí ó ń kọ́ ògìdìgbó ènìyàn nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. (Jòhánù 8:32) Àwọn àpọ́sítélì Jésù lè tètè mọ̀ pé òtítọ́ ni àwọn ohun tí Jésù ń fi kọ́ni. Wọ́n ti rí ẹ̀rí púpọ̀ tí ń fi hàn pé ọ̀run ni olùkọ́ àwọn ti wá.
BÍ Ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lónìí, ó lè ṣòro fún àwọn kan láti mọ òtítọ́ tí Jésù sọ nípa rẹ̀. Bí ó ti rí nígbà ayé wòlíì Aísáyà, “àwọn tí ń sọ pé ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára, àwọn tí ń fi òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ dípò òkùnkùn, àwọn tí ń fi ohun kíkorò dípò dídùn àti ohun dídùn dípò kíkorò” tún wà lónìí. (Aísáyà 5:20) Bí a ti ń ṣagbátẹrù ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò, àbá èrò orí, àti ọ̀nà ìgbésí ayé lóde òní, ọ̀pọ̀ ènìyàn lérò pé gbogbo nǹkan ló láàlà, àti pé kò sí ohun tí ń jẹ́ òtítọ́.
Nígbà tí Jésù wí fún àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ pé òtítọ́ yóò dá wọn sílẹ̀ lómìnira, wọ́n fún un lésì pé: “Ọmọ Ábúráhámù ni wá, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí. Èé ti rí tí o fi wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?” (Jòhánù 8:33) Wọn kò ronú pé àwọn nílò ẹnì kan tàbí ohunkóhun tí yóò dá àwọn sílẹ̀ lómìnira. Àmọ́, Jésù ṣàlàyé pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Olúkúlùkù ẹni tí ń dá ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.” (Jòhánù 8:34) Òtítọ́ tí Jésù ń sọ nípa rẹ̀ lè ṣínà fúnni láti di òmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Jésù sọ pé: “Bí Ọmọ bá dá yín sílẹ̀ lómìnira, ẹ ó di òmìnira ní ti gidi.” (Jòhánù 8:36) Nítorí náà, òtítọ́ tí ń dá àwọn ènìyàn sílẹ̀ lómìnira ni òtítọ́ nípa Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run. Kìkì nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìwàláàyè pípé ti Jésù ni ẹnikẹ́ni fi lè di òmìnira lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.
Ní àkókò mìíràn, Jésù wí pé: “Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Òtítọ́ tí ó lè dáni sílẹ̀ lómìnira lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti ìjọsìn èké ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a kọ sínú Bíbélì. Bíbélì sọ òtítọ́ tí ń sún àwọn ènìyàn láti lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, tí ó sì ń ṣínà ìrètí amọ́kànyọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la sílẹ̀. Ó mà dára láti mọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run o!
Báwo ni mímọ òtítọ́ ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó? Lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìsìn ń sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé Bíbélì, àbá èrò orí àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn ló pọ̀ jù lára ohun tí ń darí wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń jọ pé bí ìhìn iṣẹ́ àwọn aṣáájú ìsìn ṣe péye sí kò jẹ wọ́n lógún tó bí àwọn ènìyàn ṣe ń gbé àwọn fúnra wọn gẹ̀gẹ̀. Àwọn kan lérò pé kò sí ìsìn tí kò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn, kí ó sá ti jẹ́ tọkàntọkàn. Àmọ́ Jésù Kristi ṣàlàyé pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, ìsinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.”—Jòhánù 4:23.
Bí a bá fẹ́ sin Ọlọ́run lọ́nà tí ó ṣètẹ́wọ́gbà, a gbọ́dọ̀ mọ òtítọ́. Ọ̀ràn yìí ṣe pàtàkì. Ayọ̀ ayérayé wa sinmi lé e. Nítorí náà, olúkúlùkù gbọ́dọ̀ bi ara rẹ̀ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ọ̀nà ìjọsìn mi bí? Ǹjẹ́ mo fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tinútinú bí? Tàbí mo ha ń bẹ̀rù ohun tí ìwádìí tí a fìṣọ́ra ṣe lè gbé yọ bí?’