ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 7/1 ojú ìwé 5-8
  • Èéṣe Tí A Fi Ń Wá Òtítọ́ Kiri?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èéṣe Tí A Fi Ń Wá Òtítọ́ Kiri?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Ojú-Ìwòye Èyí-Wù-Mí-Ò-Wù-Ọ́ Ń Náni
  • Kí Ni Òtítọ́?
  • Òtítọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́
  • Ìṣúra kan Tí Kò Ṣeé Díyelé
  • Àwọn Kristẹni Ń jọ́sìn Ní Ẹ̀mí Àti Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • “Èmi Yóò Máa Rìn Nínú Òtítọ́ Rẹ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Fífarawé Ọlọ́run Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Òtítọ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 7/1 ojú ìwé 5-8

Èéṣe Tí A Fi Ń Wá Òtítọ́ Kiri?

Ọ̀PỌ̀ àwọn ètò-àjọ onísìn ń jẹ́wọ́ pé àwọn ń sọ òtítọ́, wọ́n sì máa ń fi lọ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ìháragàgà. Bí ó ti wù kí ó rí, láàárín wọn wọ́n ń fúnni ní “òtítọ́” tí ń kó ṣìbáṣìbo púpọ̀ báni. Èyí ha jẹ́ ẹ̀rí mìíràn pé èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ ni gbogbo òtítọ́ jẹ́ bí, pé kò sí òtítọ́ pọ́ńbélé? Rárá.

Nínú ìwé rẹ̀ The Art of Thinking, Ọ̀jọ̀gbọ́n V. R. Ruggiero sọ ìyàlẹ́nu rẹ̀ jáde pé àwọn olóye ènìyàn pàápàá nígbà mìíràn máa ń sọ pé èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ ni òtítọ́. Ó ronú pé: “Bí ẹnì kan bá pinnu òtítọ́ ti ara rẹ̀, nígbà náà kò sí èrò ẹnì kankan tí ó lè dára ju ti ẹlòmíràn lọ. Ọgbọọgba ni gbogbo rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́. Bí gbogbo èrò bá sì jẹ́ ọgbọọgba, ìdí wo ni ó wà fún ṣíṣe ìwádìí nípa kókó-ẹ̀kọ́ èyíkéyìí? Èéṣe tí a fi ń walẹ̀ fún ìdáhùn sí ìbéèrè àwọn awalẹ̀pìtàn? Èéṣe tí a fi ń fimú fínlẹ̀ láti mọ ohun tí ó fa sábàbí pákáǹleke ní Middle East? Èéṣe tí a fi ń wá ìwòsàn fún jẹjẹrẹ? Èéṣe tí a fi ń rin ìrìn-àjò lọ sínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀? Àwọn ìgbòkègbodò wọ̀nyí bọ́gbọ́n mu kìkì bí àwọn ìdáhùn kan bá dára ju òmíràn lọ, bí òtítọ́ bá jẹ́ ohun kan tí ó yàtọ̀ sí ojú-ìwòye ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ojú-ìwòye ẹnìkọ̀ọ̀kan kò sì ní ipa ìdarí lórí òtítọ́ náà.”

Níti tòótọ́, kò sí ẹnì kankan tí ó gbàgbọ́ níti gidi pé kò sí òtítọ́ kankan. Nígbà tí ó bá di ọ̀ràn àwọn ohun tí a lè fojúrí níti gidi, irú bí ìmọ̀-ìṣègùn, ìṣirò, tàbí àwọn òfin physics, alátìlẹyìn gbágbágbá jùlọ fún ojú-ìwòye èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ yóò gbàgbọ́ pé àwọn ohun kan jẹ́ òtítọ́. Ta ni nínú wa tí yóò gbìdánwò wíwọ ọkọ̀ òfúúrufú bí a kò bá ronú pé àwọn òfin ìmọ̀ ìfẹ́-síwá-sẹ́yìn-afẹ́fẹ́ jẹ́ òtítọ́ pọ́nńbélé? Àwọn òtítọ́ tí a ti jẹ́rìí sí ń bẹ; wọ́n wà láyìíká wa, ìgbésí-ayé wa sì rọ̀ mọ́ wọn.

Ohun Tí Ojú-Ìwòye Èyí-Wù-Mí-Ò-Wù-Ọ́ Ń Náni

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, nínú ilẹ̀ àkóso ìwàhíhù, ni ibi tí àwọn àṣìṣe ojú-ìwòye èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ ti hàn gbangba jùlọ, nítorí pé níhìn-ín ni irú ìrònú bẹ́ẹ̀ ti ṣe ìpalára tí ó pọ̀ jùlọ. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ kókó yìí pé: “A ti ṣe iyèméjì gan-an nípa rẹ̀ bóyá ìmọ̀, tàbí òtítọ́ tí a mọ̀, jẹ́ ohun tí ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn lè tó . . . Bí ó ti wù kí ó rí, ó dájú pé, ìgbàkígbà tí èrò méjì ti òtítọ́ àti ìmọ̀ bá di èyí tí a kọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó jẹ́ èrò-orí lásán tàbí tí ó lè panilára, ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn yóò bàjẹ́.”

Bóyá o ti kíyèsí irú ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀kọ́ ìwàhíhù ti Bibeli, èyí tí ó sọ kedere pé ìwà pálapàla takọtabo lòdì, ni a kò tilẹ̀ kà sí òtítọ́ mọ́. Ètò ìlànà ìwàhíhù tí a gbékarí àyíká ipò—“pinnu ohun tí ó tọ́ lójú ara rẹ”—ni àṣà tí ó lòde. Ẹnikẹ́ni ha lè sọ pé ìbàjẹ́ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà kò tí ì jẹyọ láti inú ojú-ìwòye alábàá èrò orí èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ yìí bí? Dájúdájú àjàkálẹ̀ àrùn kárí-ayé ti àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ takọtabo ń tàtaré rẹ̀, àwọn ilé tí ó ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, àti oyún àwọn ọmọ tí kò tí ì tó ogún ọdún ń fúnni ní ẹ̀rí tí ó pọ̀ tó.

Kí Ni Òtítọ́?

Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a fi odò dúdú kirikiri ti àbá èrò orí èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ sílẹ̀ kí a ṣàyẹ̀wò ní ṣókí ohun tí Bibeli ṣàpèjúwe bí omi mímọ́ gaara ti òtítọ́. (Johannu 4:14; Ìṣípayá 22:17) Nínú Bibeli, “òtítọ́” kì í ṣe èrò ìpìlẹ̀ dídíjú, tí kò jámọ́ nǹkankan tí àwọn ọlọ́gbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn ń jiyàn lé lórí.

Nígbà tí Jesu sọ pé gbogbo ète òun nínú ìgbésí-ayé ni láti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́, ó ń sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tí àwọn Júù olùṣòtítọ́ ti kà sí iyebíye fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Nínú àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ ọlọ́wọ̀ wọn, tipẹ́tipẹ́ ni àwọn Júù ti kà nípa “òtítọ́” gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí ó ṣe gidi, kì í ṣe àbá èrò orí lásán. Nínú Bibeli, “òtítọ́” túmọ̀ ọ̀rọ̀ Heberu náà “ʼemethʹ,” èyí tí ó dúró fún ohun tí ó dúró gbọn-in gbọn-in, tí ó fìdí múlẹ̀, àti, èyí tí ó ṣeé ṣe kí ó ṣe pàtàkì jùlọ, ó ṣeé gbáralé.

Àwọn Júù ní ìdí rere láti wo òtítọ́ lọ́nà yẹn. Wọ́n pe Ọlọrun wọn, Jehofa, ní “Ọlọrun òtítọ́.” (Orin Dafidi 31:5) Èyí jẹ́ nítorí pé gbogbo ohun tí Jehofa sọ pé òun yóò ṣe, ni ó ṣe. Nígbà tí ó bá ṣe ìlérí, ó ń mú wọn ṣẹ. Nígbà tí ó bá mí sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀, wọ́n máa ń ní ìmúṣẹ. Nígbà tí ó bá sọ ìdájọ́ ìkẹyìn jáde, a máa ń mú wọn ṣẹ. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ Israeli ti jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí àwọn òtítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí. Àwọn òǹkọ̀wé Bibeli tí a mí sí kọ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn òkodoro òtítọ́ ọ̀rọ̀-ìtàn tí kò ṣeé jáníkoro. Láì dàbí àwọn ìwé mìíràn tí a gbà pé ó jẹ́ mímọ́ ọlọ́wọ̀, a kò gbé Bibeli karí àwọn ìpìlẹ̀ àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́ tàbí ìtàn àròfọ̀. A fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú àwọn òkodoro òtítọ́ tí a jẹ́rìí gbè lẹ́yìn—ìjótìítọ́ gidi ti ọ̀rọ̀-ìtàn, ìwalẹ̀pìtàn, ìmọ̀-ìjìnlẹ̀, àti àjọṣepọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Abájọ tí onipsalmu náà fi sọ nípa Jehofa pé: “Òtítọ́ ni òfin rẹ. . . . Òtítọ́ sì ni gbogbo àṣẹ rẹ. . . . Òtítọ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ”!—Orin Dafidi 119:142, 151, 160.

Jesu Kristi sọ àwọn ọ̀rọ̀ psalmu wọ̀nyẹn ní àsọtúnsọ nígbà tí ó sọ nínú àdúrà rẹ̀ sí Jehofa pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Johannu 17:17) Jesu mọ̀ pé gbogbo ohun tí Bàbá òun sọ ni ó fìdímúlẹ̀ gbọn-in gbọn-in tí ó sì ṣeé gbáralé. Bákan náà, Jesu “kún fún . . . òtítọ́.” (Johannu 1:14) Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí olùfojúrí kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì kọ ọ́ sílẹ̀ fún gbogbo àtọmọdọ́mọ, pé gbogbo ohun tí ó sọ ṣeé gbíyèlé, ó sì jẹ́ òtítọ́.a

Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí Jesu sọ fún Pilatu pé òun wá sí ayé láti sọ òtítọ́, ó ní òtítọ́ kan pàtó lọ́kàn. Jesu sọ gbólóhùn yẹn ní ìdáhùnpadà sí ìbéèrè Pilatu pé: “Ọba ni ọ́ bí?” (Johannu 18:37) Ìjọba Ọlọrun, àti ipa iṣẹ́ Jesu gẹ́gẹ́ bí Ọba rẹ̀, ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Jesu gan-an, àtí kókó rẹ̀, nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀-ayé. (Luku 4:43) Pé Ìjọba yìí yóò sọ orúkọ Jehofa di mímọ́, yóò dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre, yóò sì mú ìran ènìyàn olùṣòtítọ́ padà sínú ìgbésí-ayé ayérayé àti aláyọ̀ jẹ́ “òtítọ́” tí gbogbo àwọn ojúlówó Kristian ní ìrètí nínú rẹ̀. Níwọ̀n bí ipa iṣẹ́ Jesu nínú ìmúṣẹ gbogbo ìlérí Ọlọrun ti ṣe kókó tóbẹ́ẹ̀, àti níwọ̀n bí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọrun ti di “Àmín,” tàbí òtítọ́ nítorí rẹ̀, Jesu lè sọ nígbà náà pé: “Emi ni ọ̀nà ati òtítọ́ ati ìyè.”—Johannu 14:6; 2 Korinti 1:20; Ìṣípayá 3:14.

Mímọ òtítọ́ yìí pé ó ṣeé gbáralé pátápátá jẹ́ ohun tí ó ní ìtumọ̀ gan-an fún àwọn Kristian lónìí. Ó túmọ̀ sí pé ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọrun àti ìrètí wọn nínú àwọn ìlérí rẹ̀ ní a gbékarí òkodoro òtítọ́, lórí àwọn òtítọ́ gidi.

Òtítọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́

Kò yanilẹ́nu pé, Bibeli so òtítọ́ pọ̀ mọ́ ìgbésẹ̀. (1 Samueli 12:24; 1 Johannu 3:18) Lójú àwọn Júù olùbẹ̀rù Ọlọrun, òtítọ́ kì í ṣe kókó-ẹ̀kọ́ fún ríronú lọ́nà ti ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn; ó jẹ́ ọ̀nà ìgbésí-ayé kan. Ọ̀rọ̀ Heberu náà fún “òtítọ́” tún lè túmọ̀ sí “ìṣòtítọ́” a sì lò ó láti ṣàpèjúwe ẹnì kan tí ó lè wí bẹ́ẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Jesu kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti fi ojú kan náà wo òtítọ́. Ó fi pẹ̀lú ìtara gbígbóná fi ìlòdìsí rẹ̀ hàn sí àgàbàgebè àwọn Farisi, ọ̀gbun jìngòdò tí ó wà láàárín àwọn ọ̀rọ̀ jíjẹ́ olódodo lójú ara-ẹni wọn àti ìṣe àìṣòdodo wọn. Ó sì fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ tí ó fi kọ́ni.

Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe yẹ kí ó rí fún gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. Lójú tiwọn, òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ìhìnrere amárayágágá ti Ìjọba Ọlọrun lábẹ́ ìṣàkóso Jesu Kristi, ju ìsọfúnni lásán lọ, ó jù ú lọ fíìfíì. Òtítọ́ yẹn ń sún wọn láti gbé ìgbésẹ̀, ó sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wọn láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀ kí wọ́n sì ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Fiwé Jeremiah 20:9.) Lójú ìjọ Kristian ti ọ̀rúndún kìn-ínní, ọ̀nà ìgbésí-ayé tí wọ́n gbà gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi ni a mọ̀ sí “òtítọ́” tàbí “ọ̀nà òtítọ́.”—2 Johannu 4; 3 Johannu 4, 8; 2 Peteru 2:2.

Ìṣúra kan Tí Kò Ṣeé Díyelé

Ní tòótọ́, títẹ́wọ́gba òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń náni ní iye-owó kan. Lákọ̀ọ́kọ́, wíwulẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lè jẹ́ ìrírí tí ń banilẹ́rù. Ìwé gbédègbéyọ̀ The Encyclopedia Americana sọ pé: “A máa ń tako òtítọ́ nígbà gbogbo, nítorí pé kì í faramọ́ ẹ̀tanú tàbí ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́.” Rírí i pé a tú àwọn èrò-ìgbàgbọ́ wa fó bí èyí tí kì í ṣe òtítọ́ lè mú ìbànújẹ́ báni, ní pàtàkì bí ó bá jẹ́ àwọn aṣáájú ìsìn tí a gbẹ́kẹ̀lé ni ó fi kọ́ni. Àwọn kan lè fi ìrírí náà wé ti rírí i pé àwọn òbí tí a gbẹ́kẹ̀lé, níti gidi, jẹ́ ọ̀daràn ní abẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n wíwá òtítọ́ ìsìn kò ha sàn ju gbígbé lábẹ́ ìgbàgbọ́ èké bí? Kò ha sàn láti mọ òkodoro ọ̀rọ̀ ju fífi irọ́ dọ́gbọ́n darí ẹni bí?b—Fiwé Johannu 8:32; Romu 3:4.

Èkejì, gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ ìsìn lè ná wa ní ìtẹ́wọ́gbà àwọn kan tí wọ́n ti jẹ́ ọ̀rẹ́ wa tẹ́lẹ̀ rí. Nínú ayé kan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti “fi irọ́ ṣe pàṣípààrọ̀ òtítọ́ Ọlọrun,” àwọn wọnnì tí wọ́n di òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun mú ṣinṣin dàbí ẹni tí ó yàtọ̀ tí a máa ń yẹra fún tí a sì máa ń ṣì lóye nígbà mìíràn.—Romu 1:25; 1 Peteru 4:4.

Ṣùgbọ́n òtítọ́ níyelórí ju ìlọ́po méjì iye-owó yìí lọ. Mímọ òtítọ́ sọ wa di òmìnira kúrò lọ́wọ́ irọ́, ìmúniṣìnà, àti ìgbàgbọ́ asán. Nígbà tí a bá sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀, òtítọ́ ń fún wa lókun láti farada ìnira. Òtítọ́ Ọlọrun ṣeé gbáralé dáradára ó sì fìdí múlẹ̀ ṣinṣin, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mí sí ìrètí wa, èyí tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin lábẹ́ ìdánwò. Abájọ tí aposteli Paulu ṣe fi òtítọ́ wé bẹ́líìtì aláwọ, tí ó fẹ̀, tàbí àmùrè, tí àwọn sójà máa ń so mọ́nú lọ sí ojú ogun!—Efesu 6:13, 14.

Ìwé Owe nínú Bibeli sọ pé: “Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á; ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́, àti ìmòye.” (Owe 23:23) Láti fẹnu ṣá òtítọ́ tì gẹ́gẹ́ bí èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ tàbí ohun tí kò sí yóò túmọ̀ sí díduni láǹfààní ìyánhànhàn tí ó ń múnilóríyá tí ó sì ń tẹ́nilọ́rùn jùlọ tí ìgbésí-ayé ń fúnni. Láti rí i yóò túmọ̀ sí rírí ìrètí; láti mọ̀ ọ́n kí a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jẹ́ láti mọ̀ kí a sì nífẹ̀ẹ́ Ẹlẹ́dàá àgbáyé àti Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo; láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀ yóò túmọ̀ sí láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ète àti àlàáfíà ọkàn, nísinsìnyí àti títí láé.—Owe 2:1-5; Sekariah 8:19; Johannu 17:3.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó lé ní 70 ibi nínú àkọsílẹ̀ Ìròyìnrere níbi tí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ pé Jesu lo gbólóhùn tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti tẹnumọ́ ìjótìítọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó máa ń sábà sọ pé “Àmín” (“Ní òótọ́,” NW) láti bẹ̀rẹ̀ gbólóhùn kan. Ọ̀rọ̀ Heberu tí ó bá a mu túmọ̀ sí “ohun tí ó dájú, ohun tí ó jẹ́ òtítọ́.” Ìwé atúmọ̀ èdè The New International Dictionary of New Testament Theology sọ pé: “Nípa bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àmín Jesu fi wọ́n hàn pé wọ́n dájú wọ́n sì ṣeé gbáralé. Ó dúró ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì mú kí wọ́n ní agbára lórí òun fúnra rẹ̀ àti àwọn olùgbọ́ rẹ̀. Wọ́n jẹ́ àwọn gbólóhùn ọlá-ńlá àti ọlá àṣẹ rẹ̀.”

b Ọ̀rọ̀ Griki náà fún “òtítọ́,” a·leʹthei·a, ni a fàyọ láti inú ọ̀rọ̀ kan tí ó túmọ̀ sí “ohun tí a kò fi pamọ́,” nítorí náà òtítọ́ máa ń wémọ́ ṣíṣí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ tẹ́lẹ̀ payá.—Fiwé Luku 12:2.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Òtítọ́ Ha Ti Yípadà Rí Bí?

V.R. RUGGIERO ni ó gbé ìbéèrè yẹn dìde nínú ìwé rẹ̀ The Art of Thinking. Bẹ́ẹ̀kọ́ ni ìdáhùn rẹ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Ó lè rí bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn, ṣùgbọ́n nígbà tí a bá ṣàyẹ̀wò rẹ̀ fínnífínní a óò rí i pé kò rí bẹ́ẹ̀.”

Ó sọ pé: “Gbé ọ̀ràn ẹni tí ó kọ ìwé àkọ́kọ́ nínú Bibeli yẹ̀wò, ìwé Genesisi. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún àwọn Kristian àti Júù bákan náà gbàgbọ́ pé ìwé náà ní òǹkọ̀wé kan ṣoṣo. Nígbà tí ó yá ojú-ìwòye yìí ni a pè níjà, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ a sì fi èrò ìgbàgbọ́ pé òǹkọ̀wé márùn-⁠ún ni ó pawọ́pọ̀ kọ ìwé Genesisi rọ́pò rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ní 1981, ìyọrísí kúlẹ̀kúlẹ̀ àyẹ̀wò èdè ìwé Genesisi tí ó gba ọdún márùn-⁠ún ni a tẹ̀jáde, tí ó sọ pé ṣíṣeéṣe tí ó tó ìpín 82 nínú ọgọ́rùn-⁠ún wà pé òǹkọ̀wé kan ṣoṣo ni ó kọ ọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti ronú ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.

“Òtítọ́ nípa ẹni tí ó kọ ìwé Genesisi ha ti yípadà bí? Rárá o. Kìkì èrò ìgbàgbọ́ wa ni ó ti yípadà. . . . Ìmọ̀ wa tàbí àìmọ̀kan wa kò lè yí òtítọ́ padà.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọ̀wọ̀ fún Òtítọ́

“Ọ̀WỌ̀ fún òtítọ́ kì í wulẹ̀ ṣe ìfòfíntótó ṣàríwísí onímàgòmágó tí sànmánì tiwa tí ń gbìyànjú láti ‘tú’ ohun gbogbo ‘fó,’ nínú èrò ìgbàgbọ́ pé kò sí ẹnì kan kò sì sí ohun kan tí ó lè jẹ́wọ́ níti gidi pé òun jẹ́ òtítọ́. Ọ̀wọ̀ fún òtítọ́ ni ìṣarasíhùwà tí ó so ìgbọ́kànlé onídùnnú-ayọ̀ pé a lè rí òtítọ́ nítòótọ́, pọ̀ mọ́ ìjuwọ́sílẹ̀ onírẹ̀lẹ̀ fún òtítọ́ níbikíbi àti nígbàkigbà tí ó bá jẹyọ. Irú ọkàn tí ó ṣípayá sí òtítọ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn wọnnì tí ń jọ́sìn Ọlọrun òtítọ́ náà; nígbà tí ó sì jẹ́ pé ọ̀wọ̀ tí ó yẹ fún òtítọ́ ń mú àìlábòsí dánilójú nínú ìbálò ènìyàn kan pẹ̀lú àwọn aládùúgbò rẹ̀, nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Èyí ní ìṣarasíhùwà, tí a ti rí, èyí tí M[ájẹ̀mú] L[áéláé] àti M[ájẹ̀mú] T[itun] jẹ́rìí sí.”​—⁠The New International Dictionary of New Testament Theology, Ìdìpọ̀ 3, ojú-ìwé 901.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

A gbé ìtẹ̀síwájú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ karí ṣíṣí àwọn òtítọ́ ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ payá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Òtítọ́ ní Ìjọba náà àti ìbùkún rẹ̀ nínú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́