Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
April 15, 2012
© 2012 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Gbogbo ẹ̀tọ́ jẹ́ tiwa.
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
MAY 28, 2012–JUNE 3, 2012
OJÚ ÌWÉ 3 • ÀWỌN ORIN: 106, 112
JUNE 4-10, 2012
Ìwà Ọ̀dàlẹ̀—Àmì Búburú Kan Tó Fi Hàn Pé À Ń Gbé ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn!
JUNE 11-17, 2012
Máa Fi Ọkàn-Àyà Pípé Sin Jèhófà
OJÚ ÌWÉ 13 • ÀWỌN ORIN: 52, 57
JUNE 18-24, 2012
Jèhófà Mọ Bó Ṣe Máa Dá Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Nídè
OJÚ ÌWÉ 22 • ÀWỌN ORIN: 133, 131
JUNE 25, 2012–JULY 1, 2012
Jèhófà Ń Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Wa Ká Lè Rí Ìgbàlà
OJÚ ÌWÉ 27 • ÀWỌN ORIN: 110, 60
OHUN TÁWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ DÁ LÉ
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 OJÚ ÌWÉ 3 sí 7
Ọ̀nà pàtàkì méjì wo ni Jésù gbà ṣí Baba payá fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àtàwọn míì? Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tá a bá fẹ́ ṣí Baba rẹ̀ payá fún àwọn èèyàn? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2 OJÚ ÌWÉ 8 sí 12
Ìwà àìṣòótọ́ wọ́pọ̀ gan-an nínú ayé tí à ń gbé lónìí, àmọ́ a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó ba àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ìdílé Kristẹni àti ìjọ jẹ́. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí i pé a lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run àti sí ara wa lẹ́nì kìíní kejì.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 OJÚ ÌWÉ 13 sí 17
Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọkàn-àyà pípé la fi ń sin Jèhófà? Ewu wo ni a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó ṣàkóbá fún ọkàn-àyà wa? Kí ló sì máa jẹ́ ká máa ní ọkàn-àyà pípé? Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4 àti 5 OJÚ ÌWÉ 22 sí 31
Nígbà “ìpọ́njú ńlá,” wọ́n máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Mát. 24:21) Kí ló lè mú kó dá wa lójú pé Jèhófà máa dá wa nídè? Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè pa ìwà títọ́ wa mọ́ bá a ṣe ń retí ìgbà tí òpin máa dé? Wàá rí àwọn ìdáhùn tó máa gbé ìgbàgbọ́ rẹ ró sáwọn ìbéèrè yìí nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
18 Àádọ́rin Ọdún Rèé Tí Mo Ti Ń Di Ibi Gbígbárìyẹ̀ Lára Aṣọ Ẹni Tí Í Ṣe Júù Mú
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Etídò Frobisher Bay tí omi ti ya wọlẹ̀ rèé. Ìlú Iqaluit ní ìpínlẹ̀ Nunavut, ní orílẹ̀-èdè Kánádà ló wà. Omi tó wà ní etídò náà ti dì gbagidi. Arábìnrin yìí ń fi ìwé pẹlẹbẹ ní èdè Inuktitut lọ ẹnì kan níbẹ̀
KÁNÁDÀ
IYE ÈÈYÀN
34,017,000
IYE AKÉDE
113,989
IṢẸ́ ÌTÚMỌ̀ ÈDÈ
Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní orílẹ̀-èdè Kánádà ń bójú tó iṣẹ́ títúmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sí méjìlá lára èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè náà