Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
May 15, 2012
© 2012 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Gbogbo ẹ̀tọ́ jẹ́ tiwa.
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
JULY 2-8, 2012
Ṣé Òótọ́ Lo Mọrírì Ìgbéyàwó Tó Jẹ́ Ẹ̀bùn Ọlọ́run?
JULY 9-15, 2012
Má Sọ̀rètí Nù Bí Ìgbéyàwó Rẹ Kò Bá Fún Ẹ Láyọ̀
JULY 16-22, 2012
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà—Ọlọ́run “Ìgbà àti Àsìkò”
OJÚ ÌWÉ 17 • ÀWỌN ORIN: 116, 135
JULY 23-29, 2012
OJÚ ÌWÉ 23 • ÀWỌN ORIN: 93, 89
OHUN TÁWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ DÁ LÉ
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 àti 2 OJÚ ÌWÉ 3 sí 12
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ ká rí àwọn ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa fi ìtọ́ni Jèhófà lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó sílò. Wọ́n máa jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa. Síwájú sí i, wọ́n máa jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká má ṣe sọ̀rètí nù bí ìgbéyàwó wa kò bá fún wa láyọ̀, wọ́n á sì ṣàlàyé bí ayọ̀ ṣe lè wà nínú ìgbéyàwó tá a bá fi ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ sílò.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 OJÚ ÌWÉ 17 sí 21
Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà jẹ́ Olùpàkókòmọ́ Ńlá náà. Tá a bá ṣe àgbéyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà, ó máa mú ká túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bákan náà, ó máa mú ká túbọ̀ dúró lórí ìpinnu wa láti máa fi ọgbọ́n lo àkókò wa bá a ṣe ń fi ìdánilójú dúró de ìgbàlà Jèhófà.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4 OJÚ ÌWÉ 23 sí 27
A nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ó sì ń wù wá pé ká máa gbé ògo rẹ̀ yọ. Àmọ́ aláìpé ni wá. Torí náà, àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ọ̀nà tá a lè máa gbà gbé ògo Jèhófà yọ. Ó sọ ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe ká lè fi ìwà jọ Ọlọ́run, ká sì máa ṣe ohun tó fẹ́. (Éfé. 5:1) Ó tún ṣàlàyé bá a ṣe lè máa bá a nìṣó láti fi ògo fún Ọlọ́run.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
13 Mo Sún Mọ́ Àwọn Àgbàlagbà Tí Wọ́n Jẹ́ Ọlọgbọ́n
22 Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
28 “Ẹ Ṣọ́ra fún Ìwúkàrà Àwọn Farisí”
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà yìí ń wàásù fún àwọn tó ń wa ọkọ̀ akẹ́rù ní ibùdókọ̀ kan ní ìlú Toulouse, lórílẹ̀-èdè Faransé. Àwọn ọkọ̀ akẹ́rù tó lé ní ẹgbẹ̀sán [1,800] láti onírúurú orílẹ̀-èdè ní ilẹ̀ Yúróòpù máa ń gba ìlú yìí kọjá lójoojúmọ́
FARANSÉ
IYE ÈÈYÀN
62,787,000
IYE AKÉDE
120,172
IYE TÍ ÀWỌN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ FI PỌ̀ SÍ I LÁÀÁRÍN ỌDÚN MÁRÙN-ÚN TÓ KỌJÁ
6,517