ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 6/1 ojú ìwé 4
  • Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Máa Ń Ṣẹ Pátápátá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Máa Ń Ṣẹ Pátápátá
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta ni Yóò Ṣàkóso Ayé?
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Máa Fiyè Sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Fún Ọjọ́ Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • B9 Àwọn Agbára Ayé Tí Dáníẹ́lì Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Wọn
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Wíwá Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ṣeé Gbára Lé Kiri
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 6/1 ojú ìwé 4

Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Máa Ń Ṣẹ Pátápátá

“Kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín.”—JÓṢÚÀ 23:14.

KÍ NI BÍBÉLÌ FI YÀTỌ̀? Àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa pé, láyé àtijọ́, tí àwọn woṣẹ́woṣẹ́ tàbí àwọn ọlọ́pẹ̀lẹ̀ bá ń sọ ohun tí wọ́n rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ṣe ni wọ́n sábà máa ń sọ ọ́ lọ́nà tó fi máa ní ìtumọ̀ tó pọ̀, wọn kò sì ṣeé gbára lé. Lónìí náà, àwọn awòràwọ̀ kò ṣeé gbára lé. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ sì ni àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la sábà máa ń gbé àsọbádé wọn kà, wọn kì í sì í lè sọ ní pàtó pé àwọn nǹkan báyìí-báyìí ló máa ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ ní ti Bíbélì, ó máa ń sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó kúnrẹ́rẹ́, tó sì máa ń ṣẹ láìyẹ̀, kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé “ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn [ló ti] sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.”—Aísáyà 46:10.

ÀPẸẸRẸ: Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wòlíì Dáníẹ́lì rí ìran kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ìjọba Gíríìsì ṣe máa ṣẹ́gun ìjọba Mídíà àti Páṣíà ní wàrà-ǹ-ṣeṣà. Àsọtẹ́lẹ̀ náà tún sọ pé kété lẹ́yìn tí ọba ilẹ̀ Gíríìsì tó ṣẹ́gun yẹn bá ti “di alágbára,” ìjọba rẹ̀ yóò “ṣẹ́.” Ta ló máa wá rọ́pò rẹ̀? Dáníẹ́lì sọ pé: “Ìjọba mẹ́rin ni yóò dìde láti orílẹ̀-èdè rẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú agbára rẹ̀.”—Dáníẹ́lì 8:5-8, 20-22.

OHUN TÍ ÀWỌN ÒPÌTÀN SỌ: Ní èyí tó ju igba [200] ọdún lọ lẹ́yìn ìgbà ayé Dáníẹ́lì, Alẹkisáńdà Ńlá di ọba ilẹ̀ Gíríìsì. Láàárín ọdún mẹ́wàá, Alẹkisáńdà ṣẹ́gun Ilẹ̀ Ọba Mídíà àti Páṣíà, ó sì mú kí Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì gbòòrò dé Odò Íńdọ́sì (tó wà ní orílẹ̀-èdè Pakísítánì lónìí). Àmọ́, ó kú lójijì nígbà tó wà ní ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n [32]. Níkẹyìn, ogun tó wáyé nítòsí ìlú Ipisọ́sì, tó wà ní Éṣíà Kékeré, jẹ́ kí ilẹ̀ ọba rẹ̀ pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ni àwọn mẹ́rin tó jagun ṣẹ́gun níbi ogun yẹn bá pín Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì mọ́ra wọn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó lágbára bíi ti Alẹkisáńdà.

KÍ LÈRÒ RẸ? Ǹjẹ́ ìwé míì tún wà tó sọ irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀, tó sì ní ìmúṣẹ bíi ti Bíbélì yìí? Ǹjẹ́ ti Bíbélì kò yàtọ̀ gédégbé?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì . . . pọ̀ ré kọjá ohun tí èèyàn fi lè máa rò pé ṣe ni wọ́n kàn ṣèèṣì ń ṣẹ.”​—A LAWYER EXAMINES THE BIBLE, LÁTI ỌWỌ́ IRWIN H. LINTON

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

© Robert Harding Picture Library/SuperStock

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́