Wíwá Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ṣeé Gbára Lé Kiri
KÉTÉ tí ọba Makedóníà táa wá mọ̀ sí Alẹkisáńdà Ńlá gorí ìtẹ́ lọ́dún 336 ṣááju Sànmánì Tiwa, ni ó gba ilé òrìṣà ti Delphi lọ, èyí tó wà ní àárín gbùngbùn Gíríìsì. Gbogbo ohun tó ṣáà ń lépa ni pé kóun lè ṣẹ́gun apá tó pọ̀ jù lọ nínú ayé ìgbà náà. Ṣùgbọ́n, ó fẹ́ rí ìdánilójú látọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé òun á ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ bàǹtà-banta tí òun dáwọ́lé. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtẹnudẹ́nu ti sọ, lọ́jọ́ tó lọ sílé òrìṣà ti Delphi yìí, òòṣà náà kò fọre, bẹ́ẹ̀ ni kò fọbi. Nítorí tí Alẹkisáńdà kò fẹ́ padà sílé lọ́wọ́ òfo, láìrí ìdáhùn sóhun tó bá wá, ló bá taku pé, dandan-ǹ-dan ìyálóòṣà gbọ́dọ̀ rí nǹkan kan sọ. Nígbà tọ́ràn náà sú ìyá oníyàá, ló bá ké gbàjarè pé: “Ìwọ ọmọdé yìí, gbégbé kan ò lè rí ẹ gbé ṣe!” Ní ọ̀dọ́mọdé ọba yìí bá gbà pé tòun ti dire nìyẹn—pé a ti ṣèlérí fóun pé bógun bá dé, dandan ni kóun ṣẹ́gun.
Àmọ́ ṣá o, ká ní Alẹkisáńdà ti lọ yẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, nínú ìwé Dáníẹ́lì wò ni, ì bá ti mọ ohun tí yóò jẹ́ àtúbọ̀tán ogun tó fẹ́ jà yìí. Pẹ̀lú ìṣerẹ́gí tó kàmàmà ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà fi sọ tẹ́lẹ̀ pé, yóò ṣẹ́gun lọ́nà yíyá kánkán. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtẹnudẹ́nu ti wí, lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Alẹkisáńdà láǹfààní láti rí ohun táa ti kọ sílẹ̀ nípa rẹ̀ nínú ìwé Dáníẹ́lì. Josephus, òpìtàn tí í ṣe Júù wí pé, nígbà tí ọba Makedóníà wọ Jerúsálẹ́mù, wọ́n fi àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì hàn án—ó ṣeé ṣe kó jẹ́ orí kẹjọ ìwé náà. (Dáníẹ́lì 8:5-8, 20, 21) Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ọ̀hún ti wí, látàrí èyí, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Alẹkisáńdà tó jẹ́ runlérùnnà, dá ìlú yìí sí.
Ohun Tí Èèyàn Máa Ń Fẹ́ Mọ̀
Ì báà jẹ́ ọba tàbí mẹ̀kúnnù, yálà ẹni ayé ọjọ́un tàbí ẹni tí ń gbé lóde ìwòyí—èèyàn máa ń fẹ́ mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣeé gbára lé nípa ọjọ́ iwájú. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá onílàákàyè, àwa èèyàn máa ń gbé ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn yẹ̀ wò, a máa ń kíyè sí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, pàápàá jù lọ a máa ń fẹ́ mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́la. Òwe àwọn ará China kan sọ pé: “Ẹní bá lè mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọ̀túnla, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni yóò fi jẹ́ ọlọ́rọ̀.”
Látọdúnmọ́dún ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ti ń gbìyànjú láti mọ bi ọ̀la óò ṣe rí nípa wíwádìí lọ́dọ̀ orísun tí wọ́n gbà pé ó lè sọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹ. Wo àpẹẹrẹ àwọn Gíríìkì ìgbàanì. Ilé òrìṣà tí wọ́n ní kò lóǹkà, irú bí ilé òrìṣà ti Delphi, ti Delos, àti ti Dodona, ibi tí wọ́n ti máa ń lọ wádìí ọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run wọn, ibẹ̀ ni wọ́n tí máa ń wádìí ọ̀ràn òṣèlú tàbí ti ogun tó fẹ́ jà àti ọ̀ràn ara ẹni, irú bí ẹni tó fẹ́ rìrìn àjò, ẹni tó fẹ́ ṣègbéyàwó, àti ọ̀ràn ọmọ. Kì í ṣe àwọn ọba àti olórí ogun nìkan ló ń wá ìtọ́sọ́nà láti ilẹ̀ ọba ẹ̀mí nípasẹ̀ àwọn òrìṣà wọ̀nyí, gbogbo ẹ̀yà náà pátá, títí kan àwọn olùgbé ìlú ńlá, ló ń ṣe bẹ́ẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n kan ti sọ, ní báyìí o “àwọn ètò àjọ táa gbé kalẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọjọ́ ọ̀la ti wá pọ̀ lọ jàra.” Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ló yàn láti má kọbi ara sí orísun àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣoṣo tó péye—ìyẹn ni Bíbélì. Wọn kì í tiẹ̀ fẹ́ẹ́ gbọ́ ọ sétí rárá pé ó ṣeé ṣe káwọn ìsọfúnni tí wọ́n ń wá kiri wọ̀nyẹn wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Kódà àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tilẹ̀ sọ pé ọ̀kan-ùnkan-ùn ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ táwọn olóòṣà sọ láyé ọjọ́un. Àwọn oníyèméjì tó sì wà lóde òní rèé, ẹ̀tanú ṣáá ni wọ́n ń fi hàn sí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì.
Jọ̀wọ́, a rọ̀ ọ́ láti fúnra rẹ yẹ àkọsílẹ̀ náà wò. Lẹ́yìn gbígbé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti tàwọn olóòṣà yẹ̀ wò fínnífínní, kí lèrò rẹ? Ǹjẹ́ o lè gbára lé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ju ti àwọn olóòṣà ayé ọjọ́un bí? Ǹjẹ́ o lè fi ìgbẹ́kẹ̀lé gbé ìgbésí ayé rẹ̀ ka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí Alẹkisáńdà yóò ṣe yára kánkán ṣẹ́gun
[Credit Line]
Cortesía del Museo del Prado, Madrid, Spain
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Alẹkisáńdà Ńlá
[Credit Line]
Musei Capitolini, Roma
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ọ̀gágun Titus àti Alẹkisáńdà Ńlá: Musei Capitolini, Roma