Ìdí Tóo Fi Lè Gbára Lé Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì
ỌBA PÍRỌ́SÌ ti Epirus ní àríwá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Gíríìsì ti ń bá Ilẹ̀ Ọba Róòmù jà ọjọ́ ti pẹ́. Nígbà tó gbékútà pé dandan ni kí òun mọ ibi tí ogun náà yóò jálẹ̀ sí, ló bá gba ilé òrìṣà Delphi lọ. Ṣùgbọ́n ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ táa lè gbà lóye èsì tó gbọ́ lọ́hùn-ún rèé: (1) “Mo sọ pé ìwọ ọmọ Æacus yóò ṣẹ́gun àwọn ará Róòmù. Wàá lọ, Wàá bọ̀, oò ni bógun lọ.” (2) “Mo sọ pé àwọn ará Róòmù yóò ṣẹ́gun rẹ, ìwọ ọmọ Æacus. Àlọ rẹ̀ nìkan la óò rí, a ò ní rábọ̀ rẹ, wàá ṣègbé sójú ogun.” Ó gbé òye rẹ̀ nípa ohun táwọn olóòṣà sọ ka èsì àkọ́kọ́, ló bá gbógun dìde sí Róòmù. Àmọ́, wọ́n ṣẹ́gun Pírọ́sì pátápátá.
Irú àwọn ọ̀ràn báwọ̀nyí fi àsọtẹ́lẹ̀ àwọn olóòṣà ayé ọjọ́un hàn gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, tó sì díjú. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ńkọ́? Àwọn aṣelámèyítọ́ kan sọ pé kò sóhun táwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì fi sàn ju àsọtẹ́lẹ̀ àwọn olóòṣà lọ. Àwọn aṣelámèyítọ́ wọ̀nyí méfò pé ṣe ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wulẹ̀ lo àwọn èèyàn ọlọ́gbọ́n féfé àti onílàákàyè láti fọgbọ́n sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la, àwọn èèyàn wọ̀nyí sì sábà máa ń wà nínú ẹgbẹ́ àlùfáà. Wọ́n sọ pé, ìrírí tàbí àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí n lò láti lè rí ọ̀nà tí àwọn nǹkan kan yóò gbà ṣẹlẹ̀. Nípa fífi onírúurú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wé èyí táwọn olóòṣà sọ, yóò túbọ̀ ṣeé ṣe fún wa láti dé ìparí èrò tó yẹ.
Àwọn Ìyàtọ̀ Tó Wà Ńbẹ̀
Ohun kan táa sábà fi ń mọ ọ̀rọ̀ táwọn olóòṣà bá sọ ni pé ó máa ń lọ́jú pọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní Delphi, ọ̀nà táa gbà fúnni lésì ọ̀rọ̀ kò tiẹ̀ yéni rárá. Ìdí abájọ rèé táwọn olóòṣà fi gbọ́dọ̀ túmọ̀ ọ̀rọ̀ wọn, tí wọ́n a sì máa fúnni ní àwọn ẹsẹ tó lè ní ìtumọ̀ tó yàtọ̀. Àpẹẹrẹ kan táa lè lò fún èyí ni èsì táa fún Croesus, ọba Lìdíà. Nígbà tó lọ sí ilé òrìṣà, ohun táa sọ fún un ni pé: “Bí Croesus bá fi lè ré Halys kọjá pẹ́rẹ́, yóò pa ilẹ̀ ọba ńlá kan run.” Pagidarì, ilẹ̀ ọba tìrẹ alára ni “ilẹ̀ ọba ńlá” táa ní yóò pa run! Nígbà tí Croesus ré odò Halys kọjá láti gbógun ti Kapadókíà, ọwọ́ Kírúsì ará Páṣíà ló kó sí, ìyẹn sì ṣẹ́gun rẹ̀.
Ní ìyàtọ̀ gédégédé sí àsọtẹ́lẹ̀ àwọn olóòṣà, a mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì bí ẹni mowó pé wọ́n máa ń péye, wọ́n sì máa ń ṣe kedere. Àpẹẹrẹ kan ni ti àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú Bábílónì, èyí táa kọ sínú Bíbélì, nínú ìwé Aísáyà. Nǹkan bí igba ọdún ṣáájú kí ọ̀ràn yìí tó ṣẹlẹ̀ ni wòlíì Aísáyà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́, tó sì péye nípa bí ilẹ̀ Mídíà òun Páṣíà yóò ṣe ṣẹ́gun Bábílónì. Àsọtẹ́lẹ̀ náà jẹ́ ká mọ̀ pé Kírúsì ni orúkọ ẹni tí yóò ṣẹ́gun, ó sì tún ṣí i payá pé, wọn yóò lo ọgbọ́n fífa odò tó dà bí adágún tó yí ìlú náà ká gbẹ, wọn yóò sì bá ẹnubodè ìlú olódi tí yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀ gbayawu wọlé. Gbogbo èyí ló nímùúṣẹ lọ́nà tó péye. (Aísáyà 44:27–45:2) A tún sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ lọ́nà tó tọ́ pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín Bábílónì kò ní lólùgbé mọ́.—Aísáyà 13:17-22.
Pẹ̀lúpẹ̀lù, tún ṣàgbéyẹ̀wò bí ìkìlọ̀ tí a tẹnu wòlíì Jónà ṣe ti ṣe kedere tó, ó wí pé: “Kìkì ogójì ọjọ́ sí i, a ó sì bi Nínéfè ṣubú.” (Jónà 3:4) Kò sí ohunkóhun tó díjú nínú ọ̀rọ̀ yìí! Ìhìn iṣẹ́ náà jẹ́ amúnijígìrì, tó sì ṣe kedere tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé lójú ẹsẹ̀ ni àwọn ọkùnrin Nínéfè “bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pòkìkí ààwẹ̀, wọ́n sì gbé asọ àpò ìdọ̀họ wọ̀.” Nítorí tí wọ́n ronú pìwà dà, Jèhófà kò mú àjálù wá sórí àwọn ará Nínéfè mọ́ ní àkókò yẹn.—Jónà 3:5-10.
Àsọtẹ́lẹ̀ àwọn olóòṣà tún máa ń jẹ́ ọ̀nà àtilo agbára ìṣèlú lórí ẹni. Àwọn alákòóso àti àwọn olórí ogun sábà máa ń tọ́ka sí ìtumọ̀ tí wọ́n fara mọ́, kí wọ́n bàa lè gbé ire ara wọn àti ìdáwọ́lé wọn lárugẹ, wọ́n sì máa ń tipa bẹ́ẹ̀ mú káwọn èèyàn gbà gbọ́ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ohun tí Ọlọ́run fi pa mọ́.” Ṣùgbọ́n, àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run kò mọ ọba, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìjòyè.
Láti ṣàkàwé: Nátánì, wòlíì Jèhófà kò fà sẹ́yìn láti bá Dáfídì Ọba tó hùwà àìtọ́ wí. (2 Sámúẹ́lì 12:1-12) Nígbà ìṣàkóso Jèróbóámù Kejì lórí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, wòlíì Hóséà àti Ámósì gbé ìwà àìdáa tí àwọn ọlọ̀tẹ̀ ọba wọ̀nyí àti àwọn alátìlẹ́yìn wọn ń hù kò wọ́n lójú lọ́nà tó gbóná janjan nítorí ìwà ìpẹ̀yìndà àti ìṣe wọn tó tàbùkù sí Ọlọ́run. (Hóséà 5:1-7; Ámósì 2:6-8) Èyí tó tiẹ̀ tún dótùútù pani jù lọ ni ìkìlọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà tí a tẹnu wòlíì Ámósì sọ fún ọba yìí pé: “Èmi yóò si fi idà dìde sí ilé Jèróbóámù.” (Ámósì 7:9) A pa ilé Jèróbóámù run ráúráú.—1 Ọba 15:25-30; 2 Kíróníkà 13:20.
Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé owó tẹ́nìkan bá san ni yóò pinnu àsọtẹ́lẹ̀ àwọn olóòṣà. Ẹni bá gbówó ńlá kalẹ̀ ni yóò gbọ́ ohun tí yóò múnú rẹ̀ dùn lẹ́nu àwọn olóòṣà. Owó táwọn tó ṣèbẹ̀wò sí ilé òrìṣà Delphi ń san fún ìsọfúnni tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ kò kéré, ohun ló fà á tí tẹ́ńpìlì Apollo àti àwọn ilé òrìṣà mìíràn fi kún fún àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àwòyanu. Lọ́nà tó yàtọ̀ pátápátá, a kì í fi àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti ìkìlọ̀ rẹ̀ gbowó lówọ́ ẹni, bẹ́ẹ̀ sì la kì í fi ṣojúsàájú. Ipò yòówù kí ẹni tọ́ràn náà kàn wà, bó ṣe wù kónítọ̀hún jẹ́ ọlọ́rọ̀ tó, bó ṣe máa ń rí níyẹn nítorí pé, wòlíì tòótọ́ kò jẹ́ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Abájọ tí wòlíì Sámúẹ́lì, tó tún jẹ́ onídàájọ́ fi lè fi tọkàntọkàn béèrè pé: “Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó mẹ́numọ́, tí mo fi ní láti fi í pa ojú mi mọ́?”—1 Sámúẹ́lì 12:3.
Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ó láwọn ibi pàtó tí wọ́n kọ́ ilé òrìṣà sí, kí ẹnì kan tó lè gbọ́ nǹkan kan láti ibẹ̀ yóò múra gidigidi láti lè rìnrìn àjò lọ síbẹ̀. Fáwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ibi bẹ́ẹ̀ ló ṣòro láti dé nítorí pé àwọn àgbègbè bí Dodona lórí Òkè Tomarus ní Epirus àti Delphi ní àwọn àgbègbè olókè gíga ní àárín gbùngbùn Gíríìsì ni wọ́n wà. Lọ́pọ̀ ìgbà, kìkì àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn ọ̀tọ̀kùlú ló láǹfààní láti lọ ṣèwádìí ọ̀rọ̀ ní àwọn ilé òrìṣà bẹ́ẹ̀. Ní àfikún sí i, ìwọ̀nba ọjọ́ díẹ̀ láàárín ọdún la fi ń ṣí “ìfẹ́ àwọn ọlọ́run” payá. Ní òdìkejì pátápátá, Jèhófà Ọlọ́run rán àwọn wòlíì, tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn ènìyàn ní tààràtà, kí wọ́n lè polongo àsọtẹ́lẹ̀ tó yẹ kí wọ́n gbọ́. Fún àpẹẹrẹ, nígbà táwọn Júù wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì, ó kéré tán, Ọlọ́run ní wòlíì mẹ́ta tí ń sìn láàárín àwọn èèyàn rẹ̀—Jeremáyà wà ní Jerúsálẹ́mù, Ìsíkíẹ́lì wà pẹ̀lú wọn nígbèkùn, Dáníẹ́lì sì wà ní olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Bábílónì.—Jeremáyà 1:1, 2; Ìsíkíẹ́lì 1:1; Dáníẹ́lì 2:48.
Ní gbogbo gbòò, ìdákọ́ńkọ́ làwọn olóòṣà ti sábà máa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn, kí onítọ̀hún bàa lè lo ìsọfúnni náà fún àǹfààní ara rẹ̀. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, gbangba-gbàǹgbà la máa ń sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kí gbogbo èèyàn bàa lè fetí ara wọn gbọ́ ọ, kí wọ́n sì lóye ohun tó túmọ̀ sí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wòlíì Jeremáyà sọ̀rọ̀ ní gbangba ní Jerúsálẹ́mù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé àwọn àgbààgbà ìlú náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ kò fojúure wo òun.—Jeremáyà 7:1, 2.
Lónìí, a ka àsọtẹ́lẹ̀ àwọn olóòṣà sí apá kan ìtàn ìjímìjí. Wọn kò ṣàǹfààní kankan fún àwọn tí ń gbé ní àkókò tiwa tó le koko yìí. Kò sí èyíkéyìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn olóòṣà tó ní í ṣe pẹ̀lú àkókò wa tàbí ọjọ́ ọ̀la wa. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ apá kan “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run [tí ó] yè, [tí] ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti nímùúṣẹ jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ lò, ó sì jẹ́ ká mọ àwọn apá pàtàkì nínú ète àti ìwà rẹ̀. Láfikún sí i, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì tó wà nínú Bíbélì yóò ní ìmúṣẹ láìpẹ́. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń ṣàlàyé ohun tí ń bẹ níwájú, ó kọ̀wé pé: “Ọ̀run tuntun [Ìjọba Mèsáyà lókè ọ̀run] àti ilẹ̀ ayé tuntun [àwùjọ ènìyàn olódodo] wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:13.
Ìfiwéra ṣókí táa ti ṣe nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti àsọtẹ́lẹ̀ èké táwọn olóòṣà sọ lè jẹ́ kí ìwọ pẹ̀lú dorí ìparí èrò tó jọ ti ìwé náà táa pe àkọlé rẹ̀ ní The Great Ideas, ó wí pé: “Táa bá ń sọ̀rọ̀ nípa òye ẹ̀dá ènìyàn nípa ọjọ́ ọ̀la, àwọn wòlíì Hébérù kò láfiwé. Wọn kò dà bí àwọn woṣẹ́woṣẹ́ tàbí adáhunṣe, àwọn abọ̀rìṣà, . . . kò dìgbà tí wọ́n bá lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tàbí ọgbọ́n àyínìke kí wọ́n tó lè mọ àṣírí tí Ọlọ́run fẹ́ fi hàn wọ́n. . . . Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àsọtẹ́lẹ̀ àwọn olóòṣà wọ̀nyẹn, èyí tó pọ̀ jù lọ lára ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n sọ ni kò díjú. Ó kéré tán, ó ṣeé ṣe láti mọ̀ pé wọn kò fẹ́ fi ète Ọlọ́run pa mọ́ lórí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí Òun Alára fẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí òun yóò ṣe lọ́jọ́ iwájú.”
Ṣé Wàá Gbára Lé Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì?
O lè gbára lé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì dáadáa. Kódà, ó lè jẹ́ kí Jèhófà àti ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ máa darí ìgbésí ayé rẹ. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kì í ṣe àkọsílẹ̀ tí kò gbéṣẹ́ mọ́, táwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ti nímùúṣẹ tán. Ọ̀pọ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ táa lè rí nínú Ìwé Mímọ́ ló ń nímùúṣẹ nísinsìnyí tàbí tí yóò nímùúṣẹ láìpẹ́. Táa bá ronú lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, a lè nígbọkànlé tó dájú pé àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú yóò nímùúṣẹ. Níwọ̀n bí irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti dá lórí àwọn ọjọ́ wa, tó sì ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ ọ̀la wa, yóò dára táa bá lè fojú pàtàkì wò wọ́n.
Má ṣiyè méjì rárá, o lè gbára lé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó wà nínú Aísáyà 2:2, 3 pé: “Yóò . . . ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá . . . Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà, . . . òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’” Lónìí, lóòótọ́ ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ń fara mọ́ ìjọsìn Jèhófà táa ti gbé ga, tí wọ́n sì ń kọ́ láti rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀. Ìwọ yóò ha tẹ́wọ́ gba àǹfààní náà láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà Ọlọ́run, kí o sì gba ìmọ̀ pípéye nípa rẹ̀ àti nípa àwọn ète rẹ̀ kí o bàa lè rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀ bí?—Jòhánù 17:3.
Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yòókù ń béèrè ìgbésẹ̀ kánjúkánjú látọ̀dọ̀ wa. Nípa ọjọ́ ọ̀la, onísáàmù náà kọ àsọtẹ́lẹ̀ náà lórin pé: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò . . . Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́.” (Sáàmù 37:9, 10) Kí lo rò pé ó yẹ ní ṣíṣe táa bá fẹ́ yẹra fún ìparun àwọn aṣebi tó ń rọ̀dẹ̀dẹ̀ yìí, títí kan àwọn tí ń bẹnu àtẹ́ lu àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì? Sáàmù kan náà fèsì pé: “Àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 37:9) Láti nírètí nínú Jèhófà túmọ̀ sí láti gbára lé ìlérí rẹ̀ pátápátá, kí a sì jẹ́ kí ìgbésí ayé wa bá ìlànà rẹ̀ mu.—Òwe 2:21, 22.
Báwo ni ìgbésí ayé yóò ṣe rí nígbà táwọn tó nírètí nínú Jèhófà bá jogún ayé? Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ọjọ́ ọ̀la ológo wà ní ìpamọ́ fún àwọn ènìyàn onígbọràn. Wòlíì Aísáyà kọ̀wé pé: “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde. Nítorí pé omi yóò ti ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀.” (Aísáyà 35:5, 6) Àpọ́sítélì Jòhánù kọ ọ̀rọ̀ afinilọ́kànbalẹ̀ wọ̀nyí: “[Jèhófà] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ. Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: . . . ‘Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.’”—Ìṣípayá 21:4, 5.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé Bíbélì jẹ́ ìwé tí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣeé gbára lé. Wọ́n sì fi gbogbo ara gbà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìṣílétí àpọ́sítélì Pétérù tó wí pé: “A ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a túbọ̀ mú dáni lójú; ẹ sì ń ṣe dáadáa ní fífún un ní àfiyèsí gẹ́gẹ́ bí fún fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn, títí tí ojúmọ́ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́ yóò sì yọ, nínú ọkàn-àyà yín.” (2 Pétérù 1:19) A nírètí láìmikàn pé àwọn ìfojúsọ́nà rere tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé yóò wáyé ní ọjọ́ ọ̀la yóò mú inú rẹ dùn!
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
ILÉ ÒRÌṢÀ DELPHI jẹ́ èyí tó lókìkí jù lọ ní Gíríìsì ìgbàanì.
Ooru gbígbóná tí ń pani bí ọtí ló ń mú kí ẹ̀mí gun ìyálóòṣà
[Àwọn àwòrán]
Ìyálóòṣà ló wà lórí pẹpẹ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta yìí, tó ń sọ ohun tí òrìṣà rẹ̀ wí
Wọ́n gbà gbọ́ pé ohun tí ìyá yìí ń sọ jẹ́ ìṣípayá láti ọ̀dọ̀ ọlọ́run náà, Apollo
[Àwọn Credit Line]
Pẹpẹ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta: Láti inú ìwé náà Dictionary of Greek and Roman Antiquities; Apollo: The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Kò séyìí tó ṣeé gbára lé rárá nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n ń sọ ní ilé òrìṣà Delphi
[Credit Line]
Delphi, Gíríìsì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
O lè ní ìgbọ́kànlé kíkún rẹ́rẹ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ayé tuntun