ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp18 No. 2 ojú ìwé 3
  • Ohun Táwọn Kan Sọ Nípa Ọjọ́ Iwájú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Táwọn Kan Sọ Nípa Ọjọ́ Iwájú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tóo Fi Lè Gbára Lé Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ti Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
  • Wíwá Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ṣeé Gbára Lé Kiri
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ta Ló Mọ Ọjọ́ Ọ̀la?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
wp18 No. 2 ojú ìwé 3
Ọkùnrin kan ń sọ bí ojú ọjọ́ ṣe máa rí fún ọ̀sẹ̀ kan

Ohun Táwọn Kan Sọ Nípa Ọjọ́ Iwájú

Ṣé o máa ń ronú nípa bí ọjọ́ ọ̀la ìwọ àti ìdílé rẹ ṣe máa rí? Ó ṣeé ṣe kó o máa bi ara rẹ pé, ṣé nǹkan máa ṣẹnuure fún wa? Ṣé ìfẹ́ máa wà láàárín wa àbí ńṣe ni kálukú á máa ṣe tiẹ̀? Ṣé ẹ̀mí mi á gùn àbí kò ní gùn? Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń ronú lórí irú àwọn ìbéèrè yìí.

Lóde òní, àwọn kan máa ń ṣèwádìí nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń lọ láyé, ìyẹn ni wọ́n á fi pinnu bí nǹkan ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára ohun tí wọ́n sọ máa ń rí bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ àwọn nǹkan míì wà tí wọ́n sọ tí kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1912, ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Guglielmo Marconi, tó kọ́kọ́ ṣe ẹ̀rọ alátagbà tí kò lo wáyà, sọ pé: “Táyé bá ti dayé ẹ̀rọ alátagbà tí kò lo wáyà, ogun ò ní wáyé mọ́.” Àpẹẹrẹ míì ni ti ọkùnrin kan tó jẹ́ aṣojú fún ilé iṣẹ́ Decca Record Company, tó kọ̀ láti gbé orin jáde fún ẹgbẹ́ olórin kan tó ń jẹ́ Beatles lọ́dún 1962. Ọkùnrin náà sọ pé òun gbà pé láìpẹ́ gbogbo àwọn tó ń fi gìtá kọrin máa kógbá sílé.

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń lo agbára abàmì láti wádìí àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Àwọn kan máa ń béèrè fún ìmọ̀ràn lọ́wọ́ àwọn awòràwọ̀ tó máa ń fi àwọn àmì ọjọ́ ìbí sọ àsọtẹ́lẹ̀. Púpọ̀ nínú ohun tí wọ́n máa ń sọ sábà máa ń wà nínú àwọn ìwé ìròyìn. Àwọn míì máa ń kàn sí aríran tàbí àwọn woṣẹ́woṣé tó gbà pé àwọn mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Lára ohun tí wọ́n máa ń lò ni àwọn káàdì ìwoṣẹ́, ọpọ́n, dígí, yanrìn, nọ́ńbà tàbí ilà ọwọ́.

Tipẹ́tipẹ́ làwọn èèyàn ti máa ń fẹ́ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àwọn kan láyé àtijọ́ máa ń lọ bá àwọn abọ̀rìṣà kí wọ́n lè bá wọn wádìí lọ́dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́ pé Ọba Croesus ti ilẹ̀ Lydia kó ẹ̀bùn iyebíye ránṣẹ́ sí òrìṣà tó wà ní Delphi, nílẹ̀ Gíríìsì, ó fẹ́ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí òun bá lọ gbógun ja Kírúsì ti ilẹ̀ Páṣíà. Òrìṣà yẹn wá sọ fún Croesus pé ó máa pa “ilẹ̀ ọba kan” run tó bá lọ bá Kírúsì jagun. Ìyẹn ló jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé òun máa ṣẹ́gun, Croesus sì lọ jagun yẹn. Àmọ́, ilẹ̀ ọba tiẹ̀ gangan ló pa run!

Ìtumọ̀ méjì ni ọ̀rọ̀ tí òrìṣà yẹn sọ ní, yálà Croesus ṣẹ́gun tàbí kò ṣẹ́gun, ṣe ló máa dà bíi pé òótọ́ ni òrìṣà yẹn sọ. Croesus pàdánù gbogbo nǹkan tó ní, torí ó gbẹ́kẹ̀ lé ohun tí òrìṣà yẹn sọ. Lónìí ńkọ́? Ṣe làwọn tó lọ ń wádìí nípa ọjọ́ iwájú ń fi ara wọn sínú ewu.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́