Émọ́sì
2 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘“Nítorí ìdìtẹ̀* mẹ́ta Móábù+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí pé ó jó egungun ọba Édómù láti fi ṣe ẹfun.
2 Torí náà, màá rán iná sí Móábù,
Á sì jó àwọn ilé gogoro tó láàbò ti Kíríọ́tì+ run;
Móábù á kú sínú ariwo,
Nígbà tí ariwo bá sọ nítorí ogun, tí ìró ìwo sì dún.+
3 Màá mú alákòóso* kúrò ní àárín Móábù
Màá sì pa gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ pẹ̀lú alákòóso rẹ̀,”+ ni Jèhófà wí.’
4 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta Júdà+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí pé wọn kò tẹ̀ lé òfin* Jèhófà
Àti nítorí pé wọn kò pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́;+
Irọ́ tí àwọn baba ńlá wọn tọ̀ lẹ́yìn ti mú kí wọ́n ṣìnà.+
6 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta Ísírẹ́lì+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Torí wọ́n ta olódodo nítorí fàdákà
Àti tálákà nítorí iye owó bàtà ẹsẹ̀ méjì.+
Ọkùnrin kan àti bàbá rẹ̀ bá ọmọbìnrin kan náà ní àṣepọ̀,
Wọ́n sì ń sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́.
8 Orí àwọn ẹ̀wù tí wọ́n gbà láti fi ṣe ìdúró*+ ni wọ́n ń sùn gbalaja sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo pẹpẹ;+
Owó ìtanràn tí wọ́n gbà ni wọ́n fi ra wáìnì tí wọ́n ń mu ní ilé* àwọn ọlọ́run wọn.’
9 ‘Ṣùgbọ́n èmi ni mo pa Ámórì rẹ́ ní ìṣojú wọn,+
Ẹni tó ga bí igi kédárì, tó sì ní agbára bí àwọn igi ràgàjì;*
Mo pa èso rẹ̀ run lókè àti gbòǹgbò rẹ̀ nísàlẹ̀.+
10 Mo mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+
Ogójì (40) ọdún ni mo fi mú yín la aginjù já,+
Kí ẹ lè gba ilẹ̀ Ámórì.
11 Mo yan àwọn kan lára àwọn ọmọkùnrin yín láti jẹ́ wòlíì+
Àti lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín láti jẹ́ Násírì.+
Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì?’ ni Jèhófà wí.
13 Nítorí náà, màá tẹ̀ yín rẹ́ ní ibùgbé yín,
Bíi kẹ̀kẹ́ tó kó ọkà gígé ṣe ń tẹ ohun tó wà lábẹ́ rẹ̀ ní àtẹ̀rẹ́.
14 Asáré tete kò ní rí ibi sá sí,+
Alágbára kò ní lókun mọ́,
Kò sì ní sí jagunjagun tó máa lè gba ẹ̀mí* ara rẹ̀ là.
15 Tafàtafà kò ní lè dúró,
Asáré tete kò ní lè sá àsálà,
Bẹ́ẹ̀ ni agẹṣin kò ní lè gba ẹ̀mí* ara rẹ̀ là.