10 Wọ́n ń sọ fún àwọn aríran pé, ‘Ẹ má ṣe ríran,’
Àti fún àwọn olùríran pé, ‘Ẹ má sọ àwọn ìran tó jẹ́ òótọ́ fún wa.+
Ọ̀rọ̀ dídùn ni kí ẹ bá wa sọ; ìran ẹ̀tàn ni kí ẹ máa rí.+
11 Ẹ yà kúrò lọ́nà; ẹ fọ̀nà sílẹ̀.
Ẹ má fi Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì síwájú wa mọ́.’”+