Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
October 15, 2012
© 2012 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. All rights reserved.
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
NOVEMBER 26, 2012–DECEMBER 2, 2012
Bá A Ṣe Lè Máa Fi Ìgboyà Kojú Ìpọ́njú Lóde Òní
DECEMBER 3-9, 2012
OJÚ ÌWÉ 12 • ÀWỌN ORIN: 122, 124
DECEMBER 10-16, 2012
Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Kí O sì Jàǹfààní Nínú Àwọn Ìlérí Tó Fi Ìbúra Ṣe
OJÚ ÌWÉ 22 • ÀWỌN ORIN: 129, 95
DECEMBER 17-23, 2012
OHUN TÁWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ DÁ LÉ
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 OJÚ ÌWÉ 7 sí 11
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń pọ́n aráyé lójú ní àkókò tá a wà yìí. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn èèyàn tí wọ́n dojú kọ àwọn ipò tó le koko láyé àtijọ́ àti lóde òní. Ó sì tún máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè jẹ́ onígboyà ká sì ní èrò tó dáa láìka àdánwò tó lè dé bá wa sí.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2 OJÚ ÌWÉ 12 sí 16
Lónìí, dípò ẹ̀mí tó ń gbéni ró, ẹ̀mí tó ń múni rẹ̀wẹ̀sì ló kúnnú ayé. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, kọ́ bó o ṣe lè máa sá fún àwọn ìwà àti ìṣe tó lè dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ àti bó o ṣe lè ní ẹ̀mí tó máa mú kó o ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 àti 4 OJÚ ÌWÉ 22 sí 31
Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ ṣàlàyé àwọn ìlérí tó ṣeyebíye tí Ọlọ́run ti búra pé òun máa mú ṣẹ. Ká lè jàǹfààní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí i, ká sì jẹ́ olóòótọ́. Àpilẹ̀kọ kejì fún wa ní àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni wọn jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni, ó sì tún fún àwọn Kristẹni tó ti ṣe ìrìbọmi níṣìírí pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Bẹ́ẹ̀ ni tó ṣe pàtàkì jù lọ tí wọ́n ṣe.—Mát. 5:37.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Brazil
17 Wọ́n Ti Ń Bára Wọn Ṣọ̀rẹ́ Bọ̀ Láti Ọgọ́ta Ọdún, Síbẹ̀ Wọ́n Ṣẹ̀ṣẹ̀ Bẹ̀rẹ̀ Ni
32 Ìṣírí “Láti Ẹnu Àwọn Ọmọdé”
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà yìí ń ti kẹ̀kẹ́ tí wọ́n pàtẹ ìwé ìròyìn sí kiri bí wọ́n ti ń jẹ́rìí lágbègbè ibi tí ọkọ ti ń lọ ti ń bọ̀ nínú ìlú náà
TIMES SQUARE, MANHATTAN, ÌLÚ NEW YORK CITY
600
AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ Ń ṢIṢẸ́ NÍ IBI
12
NÍ MANHATTAN
55
IYE ÌJỌ TÓ WÀ NÍ MANHATTAN