Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
November 15, 2012
© 2012 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. All rights reserved.
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
DECEMBER 24-30, 2012
OJÚ ÌWÉ 3 • ÀWỌN ORIN: 69, 120
DECEMBER 31, 2012–JANUARY 6, 2013
Jésù Kọ́ Wa Láti Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
OJÚ ÌWÉ 10 • ÀWỌN ORIN: 84, 82
JANUARY 7-13, 2013
OJÚ ÌWÉ 15 • ÀWỌN ORIN: 26, 68
JANUARY 14-20, 2013
Kí Lo Gbọ́dọ̀ Ṣe Tó O Bá Fẹ́ Kí Jèhófà Dárí Jì Ẹ́?
OJÚ ÌWÉ 21 • ÀWỌN ORIN: 67, 91
JANUARY 21-27, 2013
OHUN TÁWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ DÁ LÉ
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 OJÚ ÌWÉ 3 sí 7
Dáfídì, Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ka orúkọ Jèhófà àti àwọn nǹkan tí Ọlọ́run pinnu láti ṣe sí pàtàkì gan-an. Àpilẹ̀kọ́ yìí fi hàn pé ó mọ àwọn ìlànà tó wà nínú Òfin Ọlọ́run, ó sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run kọ́ òun láti máa ṣe ìfẹ́ Rẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí tún jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká máa ronú lórí ohun tí Ọlọ́run máa fẹ́ ká ṣe.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2 àti 3 OJÚ ÌWÉ 10 sí 19
Torí pé àwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù, wọ́n mọ̀ pé ó yẹ káwọn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ bá a ṣe lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, ká lè máa tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. Àpilẹ̀kọ kejì ṣàlàyé bá a ṣe lè máa hùwà bí ẹni tó kéré jù nínú ohun gbogbo tá a bá ń ṣe.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4 àti 5 OJÚ ÌWÉ 21 sí 30
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí i pé ó máa ń wu Jèhófà láti dárí jì wá, kódà tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì. Ó lè ṣòro fún wa nígbà míì láti dárí jini. Àmọ́, àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa dárí jini.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
8 ÀṢẸ́KÙSÍLẸ̀ WỌN DÍ ÀÌNÍTÓ KAN
20 ÌBÉÈRÈ LÁTI ỌWỌ́ ÀWỌN ÒǸKÀWÉ
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Akéde yìí ń wàásù ní Albarracín, abúlé kékeré kan tó wà ní orílẹ̀-èdè Sípéènì. Ní ìpínlẹ̀ ìwàásù Ìjọ Teruel tó ní akéde méjìdínlọ́gọ́rin [78] ni abúlé kékeré yìí wà. Àwọn ìlú àti abúlé mìíràn tó jẹ́ igba ó dín méjìlá [188] sì tún wà níbẹ̀
SÍPÉÈNÌ
IYE ÈÈYÀN
47,042,900
IYE AKÉDE
111,101
ÀWỌN TÓ WÁ SÍBI ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI LỌ́DÚN 2012
192,942