Rírántí Jésù Kristi
“Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—LÚÙKÙ 22:19.
Ìdí tí àwọn kan fi ń ṣe ọdún Kérésìmesì.
Àwọn èèyàn máa ń sọ pé torí Jésù ni wọ́n ṣe ń ṣe ọdún Kérésì. Wọ́n ní ọjọ́ ìbí Jésù ni àwọn fi ń rántí.
Kí nìdí tí kì í fi í rọrùn?
Àwọn orin Kérésì tó gbajúmọ̀ àti ọ̀pọ̀ àṣà inú ọdún Kérésì kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ mọ́ Jésù Kristi. Àìmọye àwọn tó ń ṣe ayẹyẹ yìí ni kò gba Jésù gbọ́; àwọn míì ò tiẹ̀ gbà pé Jésù wà rárá. Ní ti àwọn oníṣòwò, dípò kí Kérésì jẹ́ àsìkò tí wọn yóò fi rántí Jésù, ọjà ni wọ́n ń fi ayẹyẹ náà polówó ní tiwọn.
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè tọ́ni sọ́nà?
‘Ọmọ ènìyàn wá kí ó lè fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.’ (Máàkù 10:45) Kì í ṣe àyájọ́ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù ló sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Lúùkù 22:19 tí a fà yọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, alẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la tó máa kú ló sọ ọ́. Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, ó ṣe ètò ráńpẹ́ kan láti fi sọ bó ṣe fẹ́ ká máa rántí ikú òun. Àmọ́, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọjọ́ ikú rẹ̀ ni Jésù fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa rántí dípò ọjọ́ ìbí rẹ̀? Ìdí ni pé ẹbọ ìràpadà Jésù ló jẹ́ kí àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn lára àwa èèyàn lè nírètí ìyè àìnípẹ̀kun. Bíbélì sọ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Torí náà, tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù bá ń ṣe ìrántí ikú rẹ̀ lọ́dọọdún, kì í ṣe ìgbà tó jẹ́ ọmọ jòjòló ni wọ́n máa ń fi sọ́kàn, bí kò ṣe pé Jésù Kristi jẹ́ “olùgbàlà ayé.”—Jòhánù 4:42.
“Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Tí o bá fẹ́ fi hàn pé ò ń bọlá fún Jésù, pé o sì ń rántí rẹ̀, ṣe ni kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ nígbà tó di géńdé ọkùnrin tó jẹ́ ẹni pípé àti olóye. Kó o sì tún fara balẹ̀ ronú nípa bí Jésù ṣe lo ìyọ́nú àti sùúrù àti bó ṣe ń fi ìgboyà ṣe ohun tó tọ́. Kí o sì rí i dájú pé o ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ.
“Ìjọba ayé di ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé àti láéláé.” (Ìṣípayá 11:15) Tí o bá ń rántí Jésù Kristi, máa ronú lórí ohun tó ń ṣe báyìí. Jésù jẹ́ Ọba tó ń ṣàkóso ní òkè ọ̀run báyìí. Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù, ó ní: “Yóò sì fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀, yóò sì fi ìdúróṣánṣán fúnni ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà nítorí àwọn ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 11:4) Ìkókó kò lè ní gbogbo ìwà dáadáa tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ, Jésù tó ti di Ọba alágbára ńlá ló ń tọ́ka sí.