ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 12/1 ojú ìwé 11
  • Ǹjẹ́ Orúkọ Rẹ Wà Nínú “Ìwé Ìrántí” Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Orúkọ Rẹ Wà Nínú “Ìwé Ìrántí” Ọlọ́run?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídé Ojú Ìwọ̀n Ohun Tí Ọlọ́run Béèrè Ń Gbé Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • ‘Ìbùkún Títí Kì Yóò Fi Sí Àìní Mọ́’
    Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
  • Àwọn Wo Ni Yóò La Ọjọ́ Jèhófà Já?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Jèhófà Kórìíra Ìwà Àdàkàdekè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 12/1 ojú ìwé 11

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Ǹjẹ́ Orúkọ Rẹ Wà Nínú “Ìwé Ìrántí” Ọlọ́run?

ǸJẸ́ Jèhófà máa ń kíyè sí bí àwọn tó ń sìn ín ṣe ń sapá kí wọ́n lè ṣe ohun tó fẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa ń kíyè sí i! Àmọ́ o, kì í ṣe bí wọ́n ṣe ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe ń yìn ín nìkan ló máa ń wò. Ó tún máa ń fiyè sí bí àwọn tó ń sìn ín ṣe ń ronú lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n mọyì rẹ̀. Yàtọ̀ sí ìyẹn, Jèhófà kò jẹ́ gbàgbé àwọn èèyàn rẹ̀ láé, kò ní gbàgbé gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe nítorí tirẹ̀. Kí ló jẹ́ kí èyí dá wa lójú? Ìdáhùn rẹ̀ wà nínú ọ̀rọ̀ tí wòlí ì Málákì kọ sílẹ̀.​—⁠Ka Málákì 3:⁠16.

Nígbà tí Málákì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọgọ́rùn-⁠ún ọdún karùn-⁠ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìwà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ìjọsìn wọn burú jáì. Àwọn àlùfáà pa iṣẹ́ wọn tì, àwọn èèyàn tó kù náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ oṣó, wọ́n ń ṣe panṣágà, wọ́n ń lu jìbìtì. (Málákì 2:⁠8; 3:⁠5) Pẹ̀lú bí ìwà ìbàjẹ́ ṣe gbòde kan tó nígbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan wà tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run. Kí ni wọ́n wá ń ṣe ní tiwọn?

Málákì sọ pé: “Àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì.” Ó dára kéèyàn ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Àwọn tí Málákì ń sọ pé ó bẹ̀rù Jèhófà níbí yìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run lọ́nà tó jinlẹ̀, tí wọn kò sì fẹ́ ṣe ohunkóhun tí inú Jèhófà kò ní dùn sí. Kíyè sí i pé àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run yìí ń “bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì.” Ó hàn gbangba pé àwọn wọ̀nyí kó ara wọn jọ láti fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba ara wọn níyànjú, kí àwọn oníwà ìbàjẹ́ má bàa mú wọn rẹ̀wẹ̀sì tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kó èèràn ràn wọ́n.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olóòótọ́ yìí tún fi ìfọkànsìn wọn sí Jèhófà hàn lọ́nà mí ì tó ṣe pàtàkì. Wọ́n “ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.” Ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn sọ pé wọ́n “ń gbé orúkọ Rẹ̀ ga.” Kódà nínú èrò wọn pàápàá, àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run wọ̀nyí ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà. Nínú ọkàn wọn lọ́hùn-⁠ún wọ́n ń ṣàṣàrò, tàbí ká sọ pé wọ́n ń ronú nípa Jèhófà àti orúkọ ńlá rẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n mọyì rẹ̀. Ǹjẹ́ Jèhófà tiẹ̀ rí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yìí?

Málákì sọ pé: “Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀.” Jèhófà tẹ́tí sí wọn láti orí ìtẹ́ rẹ̀ gíga, ó ń gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ ìyìn tí àwọn tó ń sìn ín ń bá ara wọn sọ. Ó tún ń fiyè sí ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ń rò nínú ọkàn rẹ̀. (Sáàmù 94:11) Kì í ṣe pé Jèhófà kàn fiyè sí ohun tí wọ́n ń sọ àti èrò wọn nìkan, ó ń ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Málákì tún sọ pé: “Ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ níwájú rẹ̀.” Àkọsílẹ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n ṣe ìfẹ́ Jèhófà láìyẹsẹ̀ ló wà nínú ìwé náà. Kíyè sí i pé “ìwé ìrántí” ni ìwé yìí.a Èyí fi hàn pé Jèhófà kò ní gbàgbé àwọn tó ń fi òótọ́ inú sìn ín láé, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀, èrò àti gbogbo nǹkan rere tí wọ́n ń ṣe láti fi yìn ín. Àmọ́ ó ní ìdí tí Ọlọ́run fi ń rántí wọn. Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn tí òun bá ti kọ orúkọ wọn sínú ìwé náà lọ́nà tí kò ṣeé pa rẹ́, máa wà láàyè títí láé.b​—⁠Sáàmù 37:⁠29.

Ẹ ò rí bó ṣe tuni nínú tó láti mọ̀ pé Jèhófà mọyì gbogbo ìsapá tí à ń ṣe láti sìn ín lọ́nà tó fẹ́! Ohun tó wà nínú Málákì 3:16 jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fi ara balẹ̀ ronú lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó dáa ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ orúkọ mi wà nínú “ìwé ìrántí” Ọlọ́run?’ Orúkọ wa máa wà níbẹ̀ tí a bá ń sa ­gbogbo ipá wa lójoojúmọ́ láti máa hùwà, láti máa sọ̀rọ̀ ká sì máa ronú lọ́nà tí Jèhófà fi máa rántí wa sí rere.

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún December:

Náhúmù 1-3–Málákì 1-4

a Lédè Hébérù, ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “ìrántí” níhìn-ín ní ìtumọ̀ tó ju pé kéèyàn kàn rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Ó tún lè túmọ̀ sí kéèyàn gbé ìgbésẹ̀ lórí ohun tó rántí.

b Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ìyè ayérayé tí Ọlọ́run ṣèlérí, ka orí 3 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́