ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jd orí 14 ojú ìwé 179-191
  • ‘Ìbùkún Títí Kì Yóò Fi Sí Àìní Mọ́’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ìbùkún Títí Kì Yóò Fi Sí Àìní Mọ́’
  • Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀKÓKÒ ÌFỌ̀MỌ́ TẸ̀MÍ
  • ‘Ẹ JỌ̀WỌ́, Ẹ DÁN MI WÒ’
  • ORÚKỌ RẸ NÍNÚ ÌWÉ ÌYÈ
  • ÌGBÀGBỌ́ YÓÒ YỌRÍ SÍ ÌGBÀLÀ
  • ÀPẸẸRẸ BÍ PÁRÁDÍSÈ YÓÒ ṢE RÍ
  • Àwọn Wo Ni Yóò La Ọjọ́ Jèhófà Já?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • “Ẹ Mú Gbogbo Idamẹwaa Wá Sí Ile-Iṣura”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ibukun Jehofa Níí Múniílà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Jèhófà—Ọlọ́run Tó Ń sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Sì Ń mú Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣẹ
    Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
Àwọn Míì
Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
jd orí 14 ojú ìwé 179-191

Orí Kẹrìnlá

‘Ìbùkún Títí Kì Yóò Fi Sí Àìní Mọ́’

1, 2. (a) Àwọn ohun tó ṣàǹfààní wo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè yàn? (b) Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ wo ló ní í ṣe pẹ̀lú ìbùkún tá a lè rí gbà?

ÀKÒKÓ ìdájọ́ àti ìbùkún la wà yìí. Ó jẹ́ àkókò táwọn ìsìn ń bà jẹ́ bàlùmọ̀ àti àkókò tá a mú ìjọsìn tòótọ́ bọ̀ sípò. Ó dájú pé wàá yàn láti rí ìbùkún ìmúbọ̀sípò ìjọsìn tòótọ́, tó fi mọ́ àwọn àbájáde rere tó ń wá látinú ìmúbọ̀sípò yìí nísinsìnyí àtàwọn èyí tó máa wá lọ́jọ́ iwájú! Àmọ́ báwo lo ṣe lè rí i dájú pé àwọn ohun rere yìí kàn ọ́? Ìdáhùn ìbéèrè yìí ní í ṣe pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ní ìmúṣẹ rẹ̀ tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ láìpẹ́ lẹ́yìn tí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. (2 Tímótì 3:1) Bí Málákì ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà rèé: “‘Olúwa tòótọ́ [Jèhófà] yóò sì wá sí tẹ́ńpìlì Rẹ̀, . . . ẹni tí ẹ ń wá, àti ońṣẹ́ májẹ̀mú náà, ẹni tí ẹ ní inú dídùn sí. Wò ó! Dájúdájú, òun yóò wá,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.”—Málákì 3:1.

2 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tó ní ìtumọ̀ pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ wà nínú èyí tó gbẹ̀yìn lára àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ méjìlá náà. Bí àgbéyẹ̀wò tá à ń ṣe nínú àwọn ìwé náà ṣe ń parí lọ, ó ṣe pàtàkì pé ká gbé àkọsílẹ̀ Málákì yẹ̀ wò. Nínú ìwé Málákì, a óò rí ìtọ́ni pàtàkì tó máa mú kí ìwọ àtàwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mìíràn ‘rí ìbùkún gbà títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’ (Málákì 3:10) Jẹ́ ká gbé orí 3 ìwé Málákì yẹ̀ wò kínníkínní.

ÀKÓKÒ ÌFỌ̀MỌ́ TẸ̀MÍ

3. Kí làwọn èèyàn Ọlọ́run ayé ọjọ́un ṣe tí Ọlọ́run fi pa wọ́n tì tó sì yan “Ísírẹ́lì Ọlọ́run”?

3 Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún lẹ́yìn tí Málákì gbé ayé, Jèhófà, tí Kristi (ẹni tí í ṣe “ońṣẹ́ májẹ̀mú [Ábúráhámù]”) ṣojú fún, wá sí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù láti ṣèdájọ́ àwọn èèyàn Rẹ̀ tó bá dá májẹ̀mú. Orílẹ̀-èdè náà lódindi fi hàn pé òun ò lẹ́tọ̀ọ́ sí ojú rere Ọlọ́run mọ́, ni Jèhófà bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Mátíù 23:37, 38) O lè rí ẹ̀rí ìyẹn nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. Dípò orílẹ̀-èdè náà, ẹ̀rí àrídájú wà pé Jèhófà yan “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” tó jẹ́ orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, ìyẹn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì èèyàn tá a mú láti gbogbo orílẹ̀-èdè. (Gálátíà 6:16; Róòmù 3:25, 26) Àmọ́, kì í ṣe ibi tí ìmúṣe àsọtẹ́lẹ̀ Málákì parí sí nìyẹn. Àsọtẹ́lẹ̀ náà tún tọ́ka sí ìgbà tiwa yìí ó sì ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó ò ń retí láti rí gbà lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn ‘ìbùkún títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’

4. Ìbéèrè wo ló ń fẹ́ ìdáhùn lẹ́yìn tí Jésù gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914?

4 Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ní ọdún 1914, Jèhófà fi Jésù Kristi jẹ Ọba Ìjọba rẹ̀ ọ̀run. Ni àkókò bá tó fún Jésù láti fi àwùjọ àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà hàn. Ta ló máa yege ìdánwò yẹn, èyí tó máa fi àwùjọ àwọn Kristẹni tó mọ́ nípa tẹ̀mí hàn? Wàá rí i pé ọ̀rọ̀ tí Málákì sọ fi ìdáhùn hàn, ó ní: “Ta ni ó lè fara da ọjọ́ dídé rẹ̀, ta sì ni ẹni tí yóò dúró nígbà tí ó bá fara hàn? Nítorí òun yóò dà bí iná ẹni tí ń yọ́ nǹkan mọ́.” (Málákì 3:2) Ìgbà wo ni Jèhófà wá sí “tẹ́ńpìlì” rẹ̀ fún ìdájọ́, báwo ló sì ṣe wá?

5, 6. (a) Nígbà tí Jèhófà wá sínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀ láti ṣe àbẹ̀wò, kí ló rí láàárín ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó sọ pé olùjọsìn rẹ̀ làwọn? (b) Kí làwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Ọlọ́run nílò?

5 Ó hàn gbangba pé kì í ṣe inú tẹ́ńpìlì téèyàn fi ọwọ́ kọ́ ni Ọlọ́run wá. Ọdún 70 Sànmánì Kristẹni ni èyí tó kẹ́yìn lára irú tẹ́ńpìlì àfọwọ́kọ́ bẹ́ẹ̀ tó wà fún ìjọsìn tòótọ́ pa run. Nítorí náà, inú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ni Jèhófà wá, tẹ́ńpìlì tẹ̀mí náà sì ni ètò tí Ọlọ́run ṣe kí èèyàn fi lè sún mọ́ Ọlọ́run kó sì jọ́sìn rẹ̀ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. (Hébérù 9:2-10, 23-28) Ó dájú pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kọ́ ló para pọ̀ di tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yẹn, nítorí pé gbogbo wọn lápapọ̀ jẹ́ ètò ẹ̀sìn tó jẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ tó sì ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó tẹ̀mí, tó jẹ́ pé ẹ̀kọ́ èké ló ń gbé lárugẹ dípò ìjọsìn tòótọ́. Jèhófà di “ẹlẹ́rìí yíyára kánkán lòdì sí” irú ètò ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀, kò sì sí àní-àní pé ó dá ọ lójú pé ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe fún wọn bá òdodo mu. (Málákì 3:5) Àmọ́, lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀, àwùjọ àwọn Kristẹni tòótọ́ kan wà tí wọ́n ń sin Ọlọ́run nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀. Àwọn Kristẹni tòótọ́ náà fi hàn pé ti Ọlọ́run làwọn nípa fífara da àdánwò láìfi Ọlọ́run sílẹ̀. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyẹn ṣì nílò ìfọ̀mọ́ díẹ̀. Àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ méjìlá náà tọ́ka sí ìyẹn, nítorí pé nínú wọn, a rí àwọn ìlérí amọ́kànyọ̀ nípa ìmúbọ̀sípò tara àti tẹ̀mí láàárín àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Málákì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn kan á wà tí Jèhófà yóò ‘sọ di mímọ́ kedere bíi wúrà àti bíi fàdákà, dájúdájú, wọn yóò di àwọn ènìyàn tí ń mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn wá fún Jèhófà nínú òdodo.’—Málákì 3:3.

6 Bí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ṣe fi hàn, àtọdún 1918 ni Jèhófà ti ń ṣe ìfọ̀mọ́ tó pọn dandan, ó ṣe àfọ̀mọ́ ìjọsìn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, àṣà wọn àti ẹ̀kọ́ wọn.a Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyẹn àti “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó dara pọ̀ mọ́ wọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ti jàǹfààní tó pọ̀. (Ìṣípayá 7:9) Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ tó wà níṣọ̀kan, wọ́n ń bá a nìṣó láti máa mú ‘ọrẹ ẹbọ wá nínú òdodo,’ ọrẹ náà sì ń “mú inú Jèhófà dùn.”—Málákì 3:3, 4.

Picture on pages 180, 181

Jèhófà ń ṣe àfọ̀mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ lápapọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan. Ǹjẹ́ kálukú wa ò ṣì ní àwọn ìhà kan tó ti yẹ ká ṣe àfọ̀mọ́?

7. Kí ló yẹ ká bi ara wa nípa bá a ṣe ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run sí?

7 Ohun tá a gbé yẹ̀ wò yìí ṣẹlẹ̀ sí gbogbo èèyàn Ọlọ́run lápapọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, àmọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ńkọ́? Ó dáa, o lè béèrè pé: ‘Ṣé mi ò ní àwọn ìwà àti ìṣe kan tó ṣì nílò àtúnṣe? Ṣé mo ṣì ní láti ṣe àfọ̀mọ́ ìwà mi, bí Jèhófà ṣe ṣe àfọ̀mọ́ àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀?’ A ti rí i tẹ́lẹ̀ nínú ìwé yìí pé àwọn wòlíì méjìlá náà mẹ́nu kan àwọn ànímọ́ àti ìṣe tó dára, àti àwọn èrò àti ìwà tí kò dára. Sísọ tí wọ́n sọ èyí mú kó ṣeé ṣe fún ọ láti mọ ohun tí Jèhófà “ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ.” (Míkà 6:8) Kíyè sí awẹ́ gbólóhùn náà, “láti ọ̀dọ̀ rẹ.” Ìyẹn tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ kí kálukú wa yẹ ara rẹ̀ wò láti mọ̀ bóyá ó yẹ kóun ṣe àwọn ìfọ̀mọ́ kan.

‘Ẹ JỌ̀WỌ́, Ẹ DÁN MI WÒ’

8. Kí ni Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n ṣe?

8 Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Jèhófà tún gbẹnu Málákì sọ ní Málákì orí 3 ẹsẹ 10. Ó sọ tìfẹ́tìfẹ́ pé: “‘Ẹ mú gbogbo ìdá mẹ́wàá wá sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́, kí oúnjẹ bàa lè wà nínú ilé mi; kí ẹ sì jọ̀wọ́, dán mi wò nínú ọ̀ràn yìí,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘bóyá èmi kì yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún yín, kí èmi sì tú ìbùkún dà sórí yín ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’” Ohun tí Ọlọ́run sọ yìí kan gbogbo èèyàn Ọlọ́run lápapọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan. Ǹjẹ́ o rí i pé ó kan ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan?

9. Irú àwọn ẹbọ àti ìdá mẹ́wàá wo lo lè máa fún Jèhófà?

9 Báwo lo ṣe lè fún Jèhófà ní “ìdá mẹ́wàá”? Ká sòótọ́, o ò sí lábẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti máa san ìdámẹ́wàá irú èyí tí Òfin Mósè sọ. Ẹbọ ìṣàpẹẹrẹ ni Ọlọ́run ń béèrè báyìí. Ní Orí Kẹtàlá ìwé yìí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe iṣẹ́ ìjẹ́rìí tó ò ń ṣe ní ẹbọ. (Hóséà 14:2) Ẹ̀yìn náà ni àpọ́sítélì náà mẹ́nu kan oríṣi ẹbọ mìíràn nínú ìwé tó kọ, ó ní: “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan [ìní tara] pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” (Hébérù 13:15, 16) Nípa bẹ́ẹ̀, ó hàn gbangba pé “ìdá mẹ́wàá” tí Málákì 3:10 mẹ́nu kàn dúró fún àwọn ohun tẹ̀mí àti tara tá a fi ń rúbọ. Bó o ṣe jẹ́ Kristẹni tó ti ṣèrìbọmi, o ti ya ara rẹ sí mímọ́ pátápátá fún Jèhófà, àmọ́ ìdá mẹ́wàá rẹ dúró fún ìpín kan nínú àwọn ohun tó jẹ́ tìrẹ tó o lè fi fún Jèhófà tàbí tó o lè lò nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Èyí kan àkókò rẹ, okun rẹ, àwọn ohun ìní rẹ àti ọrẹ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

10. Báwo lo ṣe lè ‘dán Jèhófà wò’ lọ́nà tó yẹ?

10 O ò rí i pé ìfẹ́ àti ẹ̀mí fífara-ẹni-fún-Ọlọ́run pátápátá ló yẹ kó o máa fi fún Jèhófà ní irú àwọn ìdámẹ́wàá ìṣàpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀! Ó sì yẹ kó o máa ṣe bẹ́ẹ̀ láìfàkókò ṣòfò. O mọ̀ pé ọjọ́ ńlá Jèhófà ń yára sún mọ́lé, o sì tún mọ̀ pé ọjọ́ náà yóò jẹ́ “amúnikún-fún-ẹ̀rù gan-an.” (Jóẹ́lì 2:1, 2, 11) Ẹ̀mí àwọn èèyàn wà nínú ewu. Ọlọ́run pe ìpè kan tí ìwọ alára lè jẹ́. Ó ní ‘kó o dán òun wò.’ Ká sòótọ́, kò yẹ kí ẹ̀dá èèyàn kankan gbójúgbóyà láti dán Ọlọ́run wò bíi pé Ọlọ́run ò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. (Hébérù 3:8-10) Àmọ́, o lè fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ dán Ọlọ́run wò lọ́nà tó yẹ. Ọ̀nà wo lo lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣó o rí i, nígbà tó o bá ń gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu, ńṣe lò ń dán an wò; àfi bíi pé ò ń béèrè pé, ‘Ṣé á bù kún mi?’ Òun náà á sì dá ọ lóhùn nípa sísọ ọ́ di dandan fún ara rẹ̀ láti bù kún ọ, ṣé o kúkú mọ̀ pé ó ti ṣèlérí tẹ́lẹ̀ pé òun á bù kún ọ, kò sì lè ṣaláì mú ìlérí náà ṣẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, bí Ọlọ́run ṣe fàyè gbà ọ́ láti ‘dán òun wò’ jẹ́ kó túbọ̀ dá ọ lójú pé yóò bù kún ọ lọ́pọ̀ jaburata.

11, 12. Àwọn ọ̀nà wo lo ti fojú ara rẹ rí tí Jèhófà ń gbà bù kún àwọn èèyàn rẹ̀?

11 Wàá ti rí i pé àwa èèyàn Jèhófà ń fi àwọn ohun tẹ̀mí àti tara rúbọ, àti pé ẹ̀mí ọ̀làwọ́ la fi ń ṣe é. Jèhófà sì ti tú ‘ìbùkún jáde títí tí kò fi sí àìní mọ́.’ Ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé Ọlọ́run ń bù kún àwa èèyàn rẹ̀, èyí tó hàn nínú bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń yára pọ̀ sí i látìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún títí dòní olónìí. Síwájú sí i, o ti rí bí òye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” ṣe ń pọ̀ sí i láìdáwọ́dúró. (1 Kọ́ríńtì 2:10; Òwe 4:18) Àmọ́ o, ronú nípa kókó yìí lọ́nà mìíràn, kó o béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: Àǹfààní wo ni èyí ti ṣe fún èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan?

12 Nígbà kan, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣọ́ọ̀ṣì lò ń lọ, tàbí kó jẹ́ pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Nígbà yẹn, báwo ni ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o mọ̀ ṣe pọ̀ tó? Wá fi ohun tó o mọ̀ nígbà yẹn wé ohun tó o ti mọ̀ báyìí tó o sì lè fi hàn nínú Ìwé Mímọ́. Tàbí kó o ronú nípa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ tó o ti lóye, tó fi mọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ń nímùúṣẹ báyìí. Tún ronú nípa ìtẹ̀síwájú tó o ti ní nínú fífi àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sílò láwọn ìhà pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé rẹ. O ò rí i pé o ti tẹ̀ síwájú gan-an! Pẹ̀lú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ yìí, o lè sọ ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ, pé: “A ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a túbọ̀ mú dáni lójú.” (2 Pétérù 1:19) Kókó ibẹ̀ ni pé: Ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ti di ẹni tí “a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,” o wà láàárín àwọn èèyàn tó ń ṣe ìsìn Kristẹni tòótọ́, o sì fẹ́ láti sin Jèhófà títí láé. (Aísáyà 54:13) Ní báyìí, o lè sọ lọ́nà tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ pé Jèhófà ti bù kún ọ gan-an.

ORÚKỌ RẸ NÍNÚ ÌWÉ ÌYÈ

13. Báwo lorúkọ èèyàn ṣe lè wọnú ìwé ìrántí Ọlọ́run?

13 Wàá tún rí ìbùkún mìíràn nínú ohun tí Jèhófà sọ ní Málákì 3:16, pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì, olúkúlùkù pẹ̀lú alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀. Ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ níwájú rẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.” Àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá ń fi hàn pé àwọn fi gbogbo ọkàn àwọn “bẹ̀rù Jèhófà.” Ǹjẹ́ o ò kà á sí àǹfààní bàǹtà-banta pé o jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pé o jẹ́ ara àwọn èèyàn aláyọ̀ tí wọn ń ronú lórí orúkọ Jèhófà tí wọ́n sì ń gbé e ga jákèjádò ayé? O ò rí i pé ayọ̀ ńlá lo ní bó ṣe dá ọ lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé ìṣòtítọ́ rẹ!—Hébérù 6:10.

14. Báwo làwọn wòlíì méjìlá náà ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìṣe àti àṣà tí Jèhófà kórìíra?

14 Àmọ́ ṣá o, báwo ni ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣe lè kúnjú òṣùwọ̀n kí orúkọ rẹ lè wọ “ìwé ìrántí” yẹn, èyí tí orúkọ àwọn èèyàn ń wọnú rẹ̀ báyìí níwájú Jèhófà? Ó dáa, sọyè rántí díẹ̀ lára àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tá a ti rí nínú ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà. A ti kẹ́kọ̀ọ́ a sì ti mọ irú ìwà, ànímọ́ àti ìṣe tí Jèhófà ò fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn wòlíì náà jẹ́ ká mọ àwọn àṣà tí Ọlọ́run sọ pé kò bá ìlànà òdodo òun mu tó sì lè ba tiwa jẹ́, irú bí “ìwà àìníjàánu” àti “ẹ̀mí àgbèrè.” (Hóséà 4:12; 6:9) Ọlọ́run kórìíra àwọn tó ń ṣe àdàkàdekè sí ọkọ wọn tàbí aya wọn títí kan àwọn mìíràn tí wọ́n jọ wà nínú ìdílé pàápàá. (Málákì 2:15, 16) Jèhófà mí sí àwọn wòlíì náà láti tẹnu mọ́ ọn pé òun ò nífẹ̀ẹ́ sí ìwà ipá ní gbogbo oríṣi ọ̀nà tó pín sí. (Ámósì 3:10) Ó tún mú kí wọ́n sọ ọ́ lásọtúnsọ pé a ò gbọ́dọ̀ máa hùwà màkàrúrù nínú òwò àti ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ owó. (Ámósì 5:24; Málákì 3:5) Àwọn ìwé méjìlá náà sì tún tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn ọkùnrin tí wọ́n ń rí sí ọ̀ràn ẹjọ́ nínú ìjọ má ṣe jẹ́ kí ojúsàájú tàbí ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan mú wọn ṣèdájọ́ tí kò bá òdodo mu.—Míkà 7:3, 4.

15. Kí ni díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ ìbùkún tí wàá rí gbà tó o bá ń fi ìṣílétí àwọn wòlíì méjìlá náà sílò?

15 Àmọ́, yàtọ̀ sí pé àwọn wòlíì náà jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó yẹ ká yẹra fún, wọ́n tún jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ ìbùkún tí a óò rí gbà tá a bá ń pa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́ láìjáwọ́. Ara àwọn ìbùkún ọ̀hún ni pé àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú Jèhófà yóò túbọ̀ máa ṣe tímọ́tímọ́ sí i. (Míkà 4:5) Ìyẹn nìkan kọ́, bí òdodo bá gbilẹ̀ nínú ìjọ, àwọn ará inú ìjọ á dúró déédéé, ìjọ á sì máa ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́. Bákan náà, àjọgbé tọkọtaya á fìdí múlẹ̀ dáadáa, bàbá, ìyá, àtàwọn ọmọ á wà níṣọ̀kan, wọ́n á sì máa fi ohun tẹ̀mí ṣáájú. (Hóséà 2:19; 11:4) Kò mọ síbẹ̀ o, tá a bá ń fi òdodo àti òtítọ́ hùwà, àwọn ẹlòmíràn á máa bọ̀wọ̀ fún wa. Tá a bá ń fara wé Jèhófà, tá à ń fi àánú hàn bíi tiẹ̀, yóò ṣeé ṣe fún wa láti máa fi ìyọ́nú àti inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, àwọn náà á sì máa fi hàn sí wa. (Míkà 7:18, 19) Láfikún, àwọn ẹni tẹ̀mí ni yóò yí wa ká, ìyẹn àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà. Boríborí gbogbo rẹ̀ ni pé, a óò di ọ̀rẹ́ Jèhófà. (Sekaráyà 8:16, 19) Ǹjẹ́ o ò gbà pé ìwọ̀nyí jẹ́ ìbùkún tó o ti rí gbà?

16. Ìyàtọ̀ wo ló hàn kedere lónìí, kí ló sì máa jẹ́ àbájáde èyí ní ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà?

16 Àwọn ohun tá a gbé yẹ̀ wò wọ̀nyí fi hàn pé, òótọ́ pọ́ńbélé ni pé ‘ìyàtọ̀ tó wà láàárín olódodo àti ẹni burúkú,’ ìyẹn ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìsìn Kristẹni tòótọ́ àti ìsìn Kristẹni èké, ti hàn gbangba ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (Málákì 3:18) Bí àwa ṣe ń làkàkà láti máa pa àwọn ìlànà Jèhófà mọ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn èèyàn lápapọ̀ nínú ayé ṣe túbọ̀ ń rì sínú ẹrẹ̀ ìwàkiwà. O sì mọ̀ pé ìyàtọ̀ tó wà láàárín olódodo àti ẹni burúkú yìí yóò ní àbájáde pàtàkì tí “ọjọ́ ńlá Jèhófà” bá dé.—Sefanáyà 1:14; Mátíù 25:46.

17. Báwo lo ṣe lè lo ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé yìí lọ́jọ́ iwájú?

17 Nítorí náà, ó ṣe kedere pé ìmọ̀ràn àwọn wòlíì méjìlá náà ò mọ sígbà kan. Bó o bá ṣe ń dojú kọ àwọn ìṣòro pàtó kan tàbí tó o fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtó kan, á dára kó o máa tún ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé yìí gbé yẹ̀ wò. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá fi hàn pé o fẹ́ máa bá a lọ láti gba ìtọ́ni láwọn ọ̀nà Jèhófà kó o sì máa “rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.” (Míkà 4:2) Àmọ́, kì í ṣe ìsinsìnyí nìkan lo ní láti máa rìn ní ọ̀nà yẹn o. Ìfẹ́ ọkàn rẹ ni pé kí orúkọ rẹ wọ ìwé ìrántí Jèhófà kó sì wà níbẹ̀ títí láé, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ lè tẹ èyí.

ÌGBÀGBỌ́ YÓÒ YỌRÍ SÍ ÌGBÀLÀ

18. Ohun tó pọn dandan wo lo rí ní Jóẹ́lì 2:32, kí sì ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kún ohun tó pọn dandan yẹn?

18 Jóẹ́lì tẹnu mọ́ ohun pàtàkì kan tó lè mú kéèyàn rí ojú rere Ọlọ́run títí láé, ó ní: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.” (Jóẹ́lì 2:32) Àpọ́sítélì méjì, ìyẹn Pétérù àti Pọ́ọ̀lù, ṣe àtúnsọ ohun tó pọn dandan yìí. (Ìṣe 2:21; Róòmù 10:13) Pọ́ọ̀lù fi ohun mìíràn kún ìṣílétí yẹn nígbà tó béèrè pé: “Báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀?” (Róòmù 10:14) Ó dájú pé ìwọ fẹ́ máa pe orúkọ Jèhófà kó o sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nísinsìnyí àti títi láé!

Picture on page 187

Jóẹ́lì

19. Kí ni kíké pe orúkọ Jèhófà béèrè pé kéèyàn ṣe?

19 Pípe orúkọ Jèhófà kọjá pé kéèyàn sáà ti mọ orúkọ Ọlọ́run kó sì máa lò ó. (Aísáyà 1:15) Àyíká ọ̀rọ̀ Jóẹ́lì 2:32 tẹnu mọ́ ọn pé èèyàn gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà tọkàntọkàn kó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò dárí ji òun. (Jóẹ́lì 2:12, 13) Pípe orúkọ Ọlọ́run dọ́gbọ́n fi hàn pé a ní láti mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an, ká gbẹ́kẹ̀ lé e, ká máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu, ká sì máa fi í ṣáájú nígbèésí ayé wa, bẹ́ẹ̀ ni, kí sísin Jèhófà di ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wa. Ìyẹn á mú ká ní ẹ̀mí gígùn pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn tó jẹ́ ìbùkún látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.—Mátíù 6:33.

20. Ìbùkún àgbàyanu wo ni ìgbàgbọ́ tó o ní ń mú wá nísinsìnyí tó sì máa mú wá lọ́jọ́ iwájú?

20 Jèhófà gbẹnu Hábákúkù sọ pé: “Ní ti olódodo, òun yóò máa wà láàyè nìṣó nípa ìṣòtítọ́ rẹ̀.” (Hábákúkù 2:4) Rí i dájú pé o jẹ́ kí kókó yẹn fìdí múlẹ̀ lọ́kàn rẹ. Ó jẹ́ ọ̀kan lára òtítọ́ pàtàkì tó wà nínú Bíbélì. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí ẹsẹ Bíbélì yẹn nínú àwọn ìwé tó kọ lábẹ́ ìmísí Ọlọ́run.b (Róòmù 1:16, 17; Gálátíà 3:11, 14; Hébérù 10:38) Òtítọ́ yìí béèrè pé kó o ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ tí Jésù Kristi fi ara rẹ̀ rú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ . . . lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” A tún rí i kà pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16, 36) Ẹbọ yẹn ló mú ká rí ìwòsàn tó jẹ́ pé Olùràpadà wa nìkan ló lè pèsè rẹ̀. Lẹ́yìn tí Málákì ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà nípa ohun tí ọjọ́ ńlá Rẹ̀ yóò ṣe fún ayé búburú Sátánì, ó ń bá àkọsílẹ̀ rẹ̀ lọ pé: “Oòrùn òdodo yóò sì ràn dájúdájú fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, pẹ̀lú ìmúniláradá ní ìyẹ́ apá rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù yóò ràn pẹ̀lú ìmúniláradá. Èyí kan ìmúniláradá tàbí ìwòsàn tẹ̀mí tá à ń rí gbà nísinsìnyí. Tí ayé tuntun bá wá dé, yóò wò wá sàn nípa tara. Ẹ ò rí i pé ohun ayọ̀ nìyẹn!—Málákì 4:2.

21. Kí nìdí tó o fi lè ní ìgbàgbọ́ nínú agbára tí Jèhófà ní láti ṣe àwọn ohun tó ní lọ́kàn?

21 Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run lágbára láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe. Nígbà ayé wòlíì Míkà, ó ṣòro láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn èèyàn. Míkà sọ pé: “Ẹ má ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú alábàákẹ́gbẹ́. Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rẹ́ àfinúhàn.” Àmọ́ kò ṣòro fún Míkà láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kò sì yẹ kó ṣòro fún ìwọ náà. Míkà sọ pé: “Ní tèmi, Jèhófà ni èmi yóò máa wá.” (Míkà 7:5, 7) Jèhófà ò dà bí àwa èèyàn, nítorí pé kò sẹ́ni tó lè fi ìdánilójú sọ pé a óò ṣe ohun báyìí tàbí pé ohun báyìí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà báyìí, àmọ́ ní ti Jèhófà, ó wù ú, ó sì lágbára, láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn kó lè di mímọ̀ pé òun ló wà ní ipò ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run kí àwọn èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ sì lè gbádùn ìbùkún ayérayé.

22. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ń fi ìgbàgbọ́ ké pe orúkọ Jèhófà?

22 O lè fi ìdánilójú sọ ọ̀rọ̀ tí Hábákúkù sọ, pé: “Èmi yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà; èmi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Hábákúkù 3:18) Wòlíì Jóẹ́lì sọ ìdí tó fi yẹ káwọn tó ń fi ìgbàgbọ́ ké pe orúkọ Jèhófà máa yọ̀, ó ní: Wọn “yóò yè bọ́,” tàbí bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́, ‘a óò gbà wọ́n là.’ (Jóẹ́lì 2:32; Róòmù 10:13) Báwo ni wàá ṣe yè bọ́, tàbí lédè mìíràn, báwo ni a óò ṣe gbà ọ́ là? Ní báyìí ná, ìgbàgbọ́ tó o ní ti dá ọ nídè lọ́wọ́ oríṣiríṣi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tí Sátánì ń lò àti àìfararọ tó máa bá àwọn oníwàkiwà. (1 Pétérù 1:18) Yàtọ̀ síyẹn, o lè máa fi ìdánilójú retí pé wàá rí ìgbàlà nígbà tí ètò àwọn nǹkan búburú yìí bá wá sí òpin rẹ̀. Ìyẹn á mú kó ṣeé ṣe fún ọ láti gbádùn ìbùkún jaburata táwọn wòlíì méjìlá náà sọ tẹ́lẹ̀.

ÀPẸẸRẸ BÍ PÁRÁDÍSÈ YÓÒ ṢE RÍ

23, 24. (a) Kí ni díẹ̀ lára àpẹẹrẹ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní Párádísè táwọn wòlíì méjìlá náà ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀? (b) Ipa wo ni ohun táwọn wòlíì méjìlá náà kọ ní lórí èrò rẹ nípa ohun tó ò ń retí lọ́jọ́ ọ̀la?

23 Ọ̀pọ̀ ìbùkún tí kò lópin ló wà nípamọ́ fáwọn tó ń “bẹ̀rù Jèhófà.” (Málákì 3:16) Àwọn kan lára àwọn wòlíì méjìlá náà ṣe àpèjúwe tó ṣe kedere nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé báyìí, àpèjúwe tí wọ́n sì ṣe ọ̀hún á jẹ́ kí ayọ̀ rẹ kún á sì jẹ́ kó o máa fi gbogbo ọkàn retí àkókò náà. Bí àpẹẹrẹ, Míkà kọ̀wé pé: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.” (Míkà 4:4) Bẹ́ẹ̀ ni, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, wàá wà ní ààbò wàá sì jadùn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!

24 Ṣó o rí i, kì í ṣe àlá tí ò lè ṣẹ ni ríretí tó ò ń retí ìgbà tí òpin yóò dé bá àìsàn, ìbànújẹ́ àti ikú. Àwọn tó ti kú á jíǹde pẹ̀lú ìrètí pé wọ́n á di èèyàn pípé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Fojú inú wo bí ayọ̀ wọn á ṣe pọ̀ tó! Lórí ilẹ̀ ayé níbí, wọ́n á gbádùn ohun tí Hóséà 13:14 sọ lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́, pé: “Èmi yóò tún wọn rà padà láti ọwọ́ Ṣìọ́ọ̀lù; èmi yóò mú wọn padà láti inú ikú. Ìwọ Ikú, ìtani rẹ dà? Ìwọ Ṣìọ́ọ̀lù, ìpanirun rẹ dà?” Àjíǹde sí ọ̀run ni Pọ́ọ̀lù ṣe àyọlò ẹsẹ yẹn fún.—1 Kọ́ríńtì 15:55-57.

25. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ọ nínú ayé tuntun?

25 Kò yẹ kó ṣòro láti gbà pé Ọlọ́run á jí àwọn òkú dìde sórí ilẹ̀ ayé. (Sekaráyà 8:6) Nígbà tí Ámósì àti Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run á padà wálé láti ìgbèkùn, ó ṣeé ṣe kí ìyẹn dà bí ohun tó ṣòro láti gbà gbọ́. Àmọ́, o mọ̀ pé ọ̀rọ̀ yẹn ṣẹ. (Ámósì 9:14, 15; Míkà 2:12; 4:1-7) Nígbà táwọn ìgbèkùn náà padà, wọ́n sọ pé: “Àwa dà bí àwọn tí ń lá àlá. Ní àkókò yẹn, ẹnu wa kún fún ẹ̀rín, ahọ́n wa sì kún fún igbe ìdùnnú. . . . Jèhófà ti ṣe ohun ńlá nínú ohun tí ó ṣe fún wa. Àwa ti kún fún ìdùnnú.” (Sáàmù 126:1-3) Bí inú rẹ á ṣe dùn tí ayọ̀ rẹ á sì kún nìyẹn nínú ayé tuntun nígbà tó o bá gba ‘ìbùkún títí tí kò fi sí àìní mọ́.’

Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo ló yí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ká

26. Kí ló ń dúró de àwọn tó ń fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn?

26 Lẹ́yìn tí “ọjọ́ Jèhófà” bá ti nu ìwà ibi nù kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ‘ipò ọba yóò di ti Jèhófà’ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. (Ọbadáyà 15, 21) Ǹjẹ́ kì í ṣe ìbùkún àgbàyanu nìyẹn máa jẹ́ fáwọn èèyàn tó bá ń ṣàkóso lé lórí lákòókò náà? O sì lè wà lára àwọn tí ọ̀rọ̀ Málákì orí Kẹta yóò ṣẹ sí lára, pé: “‘Wọn yóò sì di tèmi,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, . . . ‘Èmi yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń fi ìyọ́nú hàn sí ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín.’” (Málákì 3:17) Ó hàn gbangba pé ìṣòtítọ́ rẹ, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún ọ láti rí ìgbàlà, yóò ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ọ láti gba ‘ìbùkún títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’ Dájúdájú, ìrètí ológo nìyẹn!

a Wo àfikún àlàyé nínú Ilé-ìṣọ́nà June 15, 1987, ojú ìwé 14 sí 20.

b Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Greek Septuagint, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì, níbi tí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò ti yàtọ̀ díẹ̀ sí ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.

ÀǸFÀÀNÍ WO LO TI RÍ?

  • Ọ̀nà wo lo ti gbà jàǹfààní nínú fífọ̀ tí Jèhófà fọ àwọn èèyàn rẹ̀ òde òní mọ́ nípa tẹ̀mí?—Dáníẹ́lì 12:10; Málákì 3:12.

  • Kí nìdí tó o fi fẹ́ láti fi kún ẹbọ tó ò ń rú sí Ọlọ́run?—Hóséà 14:2; 1 Pétérù 2:5.

MÁA FI ỌJỌ́ JÈHÓFÀ SỌ́KÀN

  • Kí nìdí tó o fi rò pé ó ṣe pàtàkì pé kó o fi Hábákúkù 2:4 sọ́kàn?—Hóséà 2:18, 20.

  • Báwo làwọn wòlíì méjìlá náà ṣe jẹ́ kó o túbọ̀ máa fojú sọ́nà fún àwọn ohun tó ò ń retí nínú ayé tuntun?—Sáàmù 126:1-3.

  • Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá máa fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn?—Jóẹ́lì 2:1, 2; Hábákúkù 2:2, 3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́