ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 12/1 ojú ìwé 7-12
  • Ibukun Jehofa Níí Múniílà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibukun Jehofa Níí Múniílà
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Aasiki Ti O Ṣepataki Julọ
  • Ọlà Tẹmi Lonii
  • Awọn Idamẹwaa ati Irubọ
  • “Ẹ Kiyesi Ọ̀nà Yin”
  • Jíja Jehofa Lólè
  • A Ṣedajọ Wọn Lati Ọwọ ‘Oluwa Tootọ Naa’
  • “Ẹ Mú Gbogbo Idamẹwaa Wá Sí Ile-Iṣura”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • ‘Ìbùkún Títí Kì Yóò Fi Sí Àìní Mọ́’
    Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Málákì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àwọn Wo Ni Yóò La Ọjọ́ Jèhófà Já?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 12/1 ojú ìwé 7-12

Ibukun Jehofa Níí Múniílà

“Ibukun Oluwa níí múniílà, kìí sìí fi làálàá pẹlu rẹ̀.”—OWE 10:22.

1-3. Nigba ti ọpọlọpọ ń daniyan nipa ohun-ìní ti ara, otitọ wo nipa ọlà ti ara ni o yẹ ki gbogbo wa mọ?

AWỌN eniyan kan kìí dẹ́kun sisọrọ nipa owo—tabi nipa ṣiṣaini in. Lọna ti kò mú wọn layọ, ni awọn ọdun aipẹ yii wọn ti ni ohun pupọ lati jiroro lé lori. Àní ni 1992 paapaa Iwọ-oorun ti o lọ́rọ̀ ti o si láásìkí niriiri ìfẹ́ri ọrọ̀-ajé, ti iṣẹ́ si bọ́ lọwọ awọn amupinnuṣẹ ati awọn oṣiṣẹ ni gbogbogboo. Ọpọ ṣekayefi boya wọn yoo tun ri akoko aasiki kan ti o duro deedee mọ́ lae.

2 O ha lodi lati daniyan nipa ire aasiki wa nipa ti ara bi? Rara o, de aaye kan o wulẹ ba iwa-ẹda mu lati ṣe bẹẹ. Ni akoko kan-naa, otitọ ipilẹ kan wà ti a gbọdọ mọ̀ nipa ọlà. Ni opin gbogbo rẹ̀, gbogbo awọn ohun ti ara wá lati ọ̀dọ̀ Ẹlẹdaa naa. Oun ni “Ọlọrun Oluwa, . . . ẹni ti o tẹ́ ayé, ati ohun ti o ti inu rẹ̀ wá; ẹni ti o fi eemi fun awọn eniyan lori rẹ̀, ati ẹmi fun awọn ti ń rìn ninu rẹ̀.”—Isaiah 42:5.

3 Bi o tilẹ jẹ pe Jehofa kò pinnu ẹni ti yoo là ati ẹni ti yoo jẹ talaka tẹlẹ, gbogbo wa ni yoo dáhùn fun ọ̀nà ti a gbà lo ipin eyikeyii ti a ní ninu “aye, ati ohun ti o ti inu rẹ̀ wá.” Bi a ba lo ọlà wa lati fi jẹgàba lé awọn miiran lori, Jehofa yoo mú ki a jíhìn fun un. Ẹnikẹni ti ó bá sì ń sìnrú fun ọrọ̀ kàkà ki ó jẹ fun Jehofa yoo rii pe “ẹni ti o ba gbẹkẹle ọrọ̀ rẹ̀ yoo ṣubu.” (Owe 11:28; Matteu 6:24; 1 Timoteu 6:9) Aasiki nipa ti ara tí ọkan-aya ti ó muratan lati ṣegbọran si Jehofa kò bá pẹlu rẹ̀ jẹ alaiwulo latokedelẹ.—Oniwasu 2:3-11, 18, 19; Luku 16:9.

Aasiki Ti O Ṣepataki Julọ

4. Eeṣe ti aasiki nipa tẹmi fi dara ju ọpọ yanturu nipa ti ara lọ?

4 Ni afikun si aasiki nipa ti ara, Bibeli sọrọ nipa aasiki nipa tẹmi. Eyi ni kedere ni iru eyi ti o dara ju. (Matteu 6:19-21) Aasiki nipa tẹmi wemọ ipo-ibatan titẹnilọrun pẹlu Jehofa ti o lè wà titi ayeraye. (Oniwasu 7:12) Ju bẹẹ lọ, awọn iranṣẹ Ọlọrun ti wọn jẹ́ ọlọ́rọ̀ nipa tẹmi kìí padanu awọn ibukun ohun-ìní ti ara gbigbamuṣe. Ninu ayé titun, ọlà nipa tẹmi ni a o sopọ mọ aasiki nipa ti ara. Awọn oluṣotitọ yoo gbadun aabo nipa ti ara ni iyatọ ifiwera pẹlu eyi ti wọn ń jere nipasẹ idije kikoro tabi fifi ilera ati ayọ rubọ, bi o ti maa ń ri niye ìgbà ninu ọpọlọpọ ọ̀ràn lonii. (Orin Dafidi 72:16; Owe 10:28; Isaiah 25:6-8) Wọn yoo ri i pe ni gbogbo ọ̀nà “ibukun Oluwa níí múniílà, kìí sìí fi làálàá pẹlu rẹ̀.”—Owe 10:22.

5. Ileri wo ni Jesu funni nipa awọn ohun-ìní ti ara?

5 Àni lonii paapaa awọn wọnni ti wọn mọyì awọn ohun tẹmi ń nimọlara iru ìtòròparọ́rọ́ kan bi o bá kan awọn ohun-ìní ti ara. Loootọ, wọn ń ṣiṣẹ lati san awọn iwe gbèsè wọn ti wọn si ń founjẹ bọ́ idile wọn. Tabi awọn kan tilẹ lè padanu iṣẹ́ wọn ni akoko ìfẹ́ri ọrọ̀-ajé. Ṣugbọn iru awọn idaniyan bẹẹ kò bò wọn mọlẹ. Kaka bẹẹ, wọn gbagbọ ninu ileri Jesu ti o sọ pe: “Ẹ maṣe ṣe aniyan, wi pe, Ki ni a o jẹ? tabi, Ki ni a o mu? tabi, aṣọ wo ni a o fi wọ̀ wá? . . . Nitori Baba yin ti ń bẹ ni ọrun mọ̀ pe, ẹyin kò lè ṣe alaini gbogbo nǹkan wọnyi. Ṣugbọn ẹ tètè maa wa ijọba Ọlọrun ná, ati ododo rẹ̀; gbogbo nǹkan wọnyi ni a o sì fi kun un fun yin”.—Matteu 6:31-33.

Ọlà Tẹmi Lonii

6, 7. (a) Ṣapejuwe apá diẹ ninu aasiki nipa tẹmi ti awọn eniyan Ọlọrun. (b) Asọtẹlẹ wo ni o ń ni imuṣẹ lonii, awọn ibeere wo ni eyi si gbe dide?

6 Nipa bayii, awọn eniyan Jehofa ti yàn lati fi Ijọba naa si ipo akọkọ ninu igbesi-aye wọn, ẹ sì wo bi a ti bukun fun wọn tó! Wọn gbadun aṣeyọrisirere dídọ́ṣọ̀ ninu iṣẹ́ wọn ti sisọ awọn eniyan di ọmọ-ẹhin. (Isaiah 60:22) Jehofa ń kọ́ wọn, wọn ń gbadun ìtúyààjáde awọn ohun rere nipa tẹmi laidawọduro ti a ń pese lati ọwọ “ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa.” (Matteu 24:45-47, NW; Isaiah 54:13) Siwaju sii, ẹmi Jehofa wà lori wọn, ó ń mọ wọn sinu ẹgbẹ́-ará kari-aye gbigbadunmọni kan.—Orin Dafidi 133:1; Marku 10:29, 30.

7 Eyi nitootọ jẹ aasiki nipa tẹmi, ohun kan ti owo kò lè rà. O jẹ imuṣẹ apàfiyèsí kan nipa ileri Jehofa naa: “Ẹ mu gbogbo idamẹwaa wa si ile iṣura, ki ounjẹ baa lè wà ni ile mi, ẹ sì fi eyi dán mi wò nisinsinyi, bi emi ki yoo bá ṣi awọn ferese ọrun fun yin, kí ń si tú ibukun jade fun yin, tobẹẹ ti kì yoo sí àyè tó lati gbà á.” (Malaki 3:10) Awa lonii ti ri imuṣẹ ileri yii. Bi o ti wu ki o ri, eeṣe ti Jehofa, Orisun gbogbo ọlà, ṣe beere pe ki awọn iranṣẹ rẹ̀ mu ipin kan ninu mẹwaa, tabi idamẹwaa wá? Awọn wo ni wọn ń janfaani lati inu idamẹwaa naa? Lati dahun awọn ibeere wọnyi, ẹ gbe idi ti Jehofa fi sọ awọn ọ̀rọ̀ wọnyi lati ẹnu Malaki ni ọrundun karun-un B.C.E. yẹwo.

Awọn Idamẹwaa ati Irubọ

8. Ni ibamu pẹlu majẹmu Ofin, lori ki ni aasiki awọn ọmọ Israeli nipa ti ara sinmile?

8 Ni akoko Malaki awọn eniyan Ọlọrun kò laasiki. Eeṣe ti o fi ri bẹẹ? Ni apa kan o nii ṣe pẹlu awọn irubọ ati awọn idamẹwaa. Nigba naa lọhun-un, Israeli wà labẹ majẹmu Ofin Mose. Nigba ti Jehofa ṣe majẹmu yẹn, o ṣeleri pe bi Israeli bá pa apa tiwọn ninu rẹ̀ mọ́, oun yoo bukun wọn nipa tẹmi ati nipa ti ara. Niti gasikia, aasiki Israeli sinmi lori iṣotitọ wọn.—Deuteronomi 28:1-19.

9. Ni ọjọ awọn ọmọ Israeli igbaani, eeṣe ti Jehofa fi beere pe ki Israeli san idamẹwaa ki wọn si mu awọn irubọ wa?

9 Apakan iṣẹ́ aigbọdọmaṣe Israeli labẹ Ofin ni lati mu irubọ wa sinu tẹmpili ki wọn sì san idamẹwaa. Lara awọn irubọ naa ni a ń sun lodidi lori pẹpẹ Jehofa, nigba ti a ń pin awọn yooku laaarin awọn alufaa ati awọn ti wọn ń mu ẹbọ naa wa, pẹlu awọn apá akanṣe kan ti a firubọ si Jehofa. (Lefitiku 1:3-9; 7:1-15) Niti idamẹwaa, Mose sọ fun awọn ọmọ Israeli pe: “Gbogbo idamẹwaa ilẹ naa ibaa ṣe ti irugbin ilẹ naa, tabi ti eso igi, ti OLUWA ni: mímọ́ ni fun OLUWA.” (Lefitiku 27:30) Idamẹwaa naa ni a fifun awọn ọmọ Lefi ti wọn jẹ oṣiṣẹ ninu agọ-isin ati lẹhin naa ni tẹmpili. Ni tiwọn, awọn ọmọ Lefi ti kìí ṣe alufaa yoo fi idamẹwaa ohun ti wọn ti gba fun awọn alufaa ti ẹ̀yà Aaroni. (Numeri 18:21-29) Eeṣe ti Jehofa fi beere lọwọ Israeli lati san idamẹwaa? Lakọọkọ, ki wọn baa lè fi imọriri wọn fun iwarere-iṣeun Jehofa hàn lọna ti ó jọjú. Ati ekeji, ki wọn baa lè ṣe iranlọwọ fun itilẹhin awọn ọmọ Lefi, ti wọn yoo tipa bẹẹ pọkanpọ sori iṣẹ́ aigbọdọmaṣe wọn, ti o ni ninu kikọni ni Ofin. (2 Kronika 17:7-9) Ni ọ̀nà yii ijọsin mimọgaara ni a tun ń ṣetilẹhin fun, gbogbo eniyan ni o sì janfaani.

10. Ki ni o ṣẹlẹ nigba ti Israeli kuna lati mú awọn idamẹwaa ati awọn irubọ wa?

10 Bi o tilẹ jẹ pe awọn idamẹwaa ati irubọ naa ni awọn ọmọ Lefi ń lo lẹhin-ọ-rẹhin, niti gidi wọn jẹ́ ẹbun fun Jehofa ati nipa bẹẹ wọn gbọdọ jẹ́ ojulowo daradara, ti wọn yẹ fun un. (Lefitiku 22:21-25) Ki ni ń ṣẹlẹ nigba ti awọn ọmọ Israeli bá kunan lati mú idamẹwaa wọn wa tabi ti wọn bá mu awọn irubọ ti kìí ṣe ojulowo wá? Ijiya kankan ni a kò lana rẹ̀ silẹ ninu Ofin, ṣugbọn awọn abajade maa ń wà. Jehofa fa ọwọ́ ibukun rẹ̀ sẹhin, awọn ọmọ Lefi, ti a si fi itilẹhin nipa ti ara dù, fi ila-iṣẹ wọn ni tẹmpili silẹ lati lọ ṣetilẹhin fun araawọn. Nipa bayii, gbogbo Israeli jiya.

“Ẹ Kiyesi Ọ̀nà Yin”

11, 12. (a) Ki ni ó maa ń yọrisi nigba ti Israeli bá ṣainaani pipa Ofin mọ́? (b) Iṣẹ́-àṣẹ wo ni Jehofa fun Israeli nigba ti ó mú wọn pada wá lati Babiloni?

11 Laaarin akoko ọ̀rọ̀ ìtàn awọn ọmọ Israeli, awọn kan jẹ awofiṣapẹẹrẹ ninu igbiyanju lati pa Ofin mọ́, titikan sisan idamẹwaa. (2 Kronika 31:2-16) Bi o ti wu ki o ri, ni gbogbogboo, orilẹ-ede naa jẹ́ alainaani. Leralera ni wọn da majẹmu pẹlu Jehofa, titi ti o fi yọnda nikẹhin ki a ṣẹgun wọn ati, ni 607 B.C.E., ki a kò wọn lọ si Babiloni.—2 Kronika 36:15-21.

12 Iyẹn jẹ ibawi ti o nira, ṣugbọn lẹhin 70 ọdun Jehofa mú awọn eniyan rẹ̀ padabọsipo si ilẹ ibilẹ wọn. Ọpọ lara awọn asọtẹlẹ nipa Paradise ninu Isaiah yoo ni imuṣẹ wọn akọkọ lẹhin ipadabọ yẹn. (Isaiah 35:1, 2; 52:1-9; 65:17-19) Sibẹ, idi pataki tí Jehofa fi mú awọn eniyan rẹ̀ pada kìí ṣe lati kọ́ paradise ori ilẹ̀-ayé kan, ṣugbọn lati ṣe atunkọ tẹmpili ki wọn si mú ijọsin tootọ padabọsipo. (Esra 1:2, 3) Bi Israeli bá ṣegbọran si Jehofa, awọn anfaani nipa ti ara yoo tẹle e, ibukun Jehofa yoo sì mú wọn lọ́rọ̀ nipa tẹmi ati nipa ti ara. Ni ibamu pẹlu eyi, ni 537 B.C.E., ni kete lẹhin ti wọn de si ilẹ ibilẹ wọn, awọn Ju kọ́ pẹpẹ kan ni Jerusalemu wọn si bẹrẹsii ṣiṣẹ lori tẹmpili naa. Bi o ti wu ki o ri, wọn ṣalabaapade àtakò lilekoko wọn si duro. (Esra 4:1-4, 23) Gẹgẹ bi abajade eyi, Israeli ko gbadun ibukun Jehofa.

13, 14. (a) Ki ni o tẹle e nigba ti Israeli kuna lati ṣatunkọ tẹmpili? (b) Bawo ni a ṣe ṣatunkọ tẹmpili naa nigbẹhin-gbẹhin, ṣugbọn awọn ifasẹhin siwaju sii wo niha ọ̀dọ̀ Israeli ni a rohin?

13 Ni ọdun 520 B.C.E., Jehofa gbe wolii Haggai ati Sekariah dide lati rọ Israeli lati pada sẹnu iṣẹ́ kíkọ́ tẹmpili. Haggai fihàn pe orilẹ-ede naa ń jiya inira ohun-ìní ti ara ó sì so eyi pọ̀ mọ́ aini ìtara wọn fun ile Jehofa. O sọ pe: “Bayii ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Ẹ kiyesi ọ̀nà yin. Ẹyin ti fọ́n irugbin pupọ, ẹ sì mú diẹ wa ile; ẹyin ń jẹ, ṣugbọn ẹyin kò yó: ẹyin ń mu, ṣugbọn kò tẹ yin lọrun; ẹyin ń bora, ṣugbọn kò si ẹni ti o gbóná; ẹni ti o sì ń gbowo ọ̀yà ń gba á sinu ajádìí àpò. Bayii ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wí: Ẹ kiyesi ọ̀nà yin. Ẹ gun ori oke-nla lọ, ẹ si mú igi wá, ki ẹ si kọ́ ile naa; inu mi yoo si dun si i, a o si yin mi logo.”—Haggai 1:5-8.

14 Bi a ti fun wọn niṣiiri lati ẹnu Haggai ati Sekariah, awọn ọmọ Israeli kiyesi ọ̀nà wọn, tẹmpili naa ni wọn sì kọ́. Bi o ti wu ki o ri, ni nǹkan bii 60 ọdun lẹhin naa, Nehemiah ṣebẹwo si Jerusalemu o si ri i pe Israeli tun ti di alainaani awọn Ofin Jehofa. O ṣatunṣe eyi. Ṣugbọn lakooko ibẹwo ẹẹkeji, o ri i pe awọn nǹkan tun ti jagọ̀ lẹẹkan sii. O rohin pe: “Mo si mọ̀ pe, a kò ti fi ipin awọn ọmọ Lefi fun wọn; awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin, ti ń ṣe iṣẹ́, sì ti salọ olukuluku si oko rẹ̀.” (Nehemiah 13:10) Iṣoro yii ni a mú padabọsipo, ‘gbogbo Juda sì mú idamẹwaa ọkà ati ọti-waini titun ati ororo wa si ile iṣura.’—Nehemiah 13:12.

Jíja Jehofa Lólè

15, 16. Fun awọn ikuna wo ni Jehofa, nipasẹ Malaki, tọ́ awọn ọmọ Israeli sọna?

15 O ṣeeṣe ki o jẹ pe, asọtẹlẹ Malaki jẹ ni saa akoko gbogbogboo kan-naa yii, wolii naa si sọ pupọ sii fun wa nipa aiṣotitọ Israeli. O ṣakọsilẹ awọn ọ̀rọ̀ Jehofa si Israeli pe: “Bi emi ba ṣe baba, ọlá mi ha da? bi emi ba si ṣe oluwa, ẹ̀rù mi ha da? ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi fun yin: Ẹyin alufaa, ti ń gan orukọ mi.” Ki ni o ṣaitọ? Jehofa ṣalaye pe: “Bi ẹyin ba sì fi eyi ti oju rẹ̀ fọ́ rubọ [ẹyin wi pe], ibi kọ eyiini? bi ẹyin ba si fi amukun-un ati olokunrun rubọ [ẹyin wi pe], ibi kọ eyiini”—Malaki 1:6-8.

16 Ni ọ̀nà alapejuwe yii, Malaki fihàn pe nigba ti awọn ọmọ Israeli ń mu irubọ wọn wọle, awọn tí ijojulowo wọn kò dara wọnyi fi ailọwọ biburu lekenka hàn. Malaki tun kọwe pe: “Lati ọjọ awọn baba yin wá ni ẹyin tilẹ ti yapa kuro ni ilana mi, ti ẹ kò si pa wọn mọ. Ẹ yipada si ọdọ mi, Emi o si yipada si ọdọ yin, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.” Awọn ọmọ Israeli ṣe kayefi nipa ohun ti wọn nilati ṣe ní pato, nitori naa wọn beere pe: “Nipa bawo ni awa o yipada?” Jehofa dahun pe: “Eniyan yoo ha ja Ọlọrun ni olè? ṣugbọn ẹyin sa ti jà mi ni olè.” Bawo ni Israeli ṣe lè ja Jehofa, Orisun gbogbo ọlà ni olè? Jehofa dahun pe: “Nipa idamẹwaa ati ọrẹ.” (Malaki 3:7, 8) Bẹẹni, nipa kikuna lati mu awọn idamẹwaa ati awọn irubọ wọn wa, Israeli ń ja Jehofa ni ole!

17. Ète wo ni idamẹwaa ati irubọ ṣiṣẹ fun ni Israeli, ileri wo si ni Jehofa ṣe nipa idamẹwaa?

17 Isọfunni ipilẹ ọlọrọ ìtàn yii fi ijẹpataki awọn idamẹwaa ati awọn irubọ ni Israeli hàn. Wọn jẹ ìfihàn imọriri niha ọ̀dọ̀ ẹni ti o ń fi funni. Wọn sì ṣeranwọ lati ṣetilẹhin fun ijọsin tootọ ni ọ̀nà ohun-ìní ti ara. Nipa bayii, Jehofa ń baa lọ lati fun Israeli niṣiiri pe: “Ẹ mu gbogbo idamẹwaa wa si ile iṣura.” Ni fifi ohun ti yoo tẹle e bi wọn ba ṣe bẹẹ hàn, Jehofa ṣeleri pe: “Ki n sì tú ibukun jade fun yin, tobẹẹ ti kì yoo sí ààyè tó lati gbà á.” (Malaki 3:10) Ibukun Jehofa yoo mú wọn là.

A Ṣedajọ Wọn Lati Ọwọ ‘Oluwa Tootọ Naa’

18. (a) Dídé ta ni Jehofa kilọ nipa rẹ̀? (b) Nigba wo ni dídé si tẹmpili naa ṣẹlẹ, ta ni o ni ninu, ki sì ni iyọrisi rẹ̀ fun Israeli?

18 Jehofa nipasẹ Malaki tun kilọ pe oun yoo wá lati ṣedajọ awọn eniyan rẹ̀. “Kiyesi i, Emi o ran onṣẹ mi, yoo si tun ọ̀nà ṣe niwaju mi: ati Oluwa, ti ẹyin ń wá, yoo de ni ojiji si tẹmpili rẹ̀, àní onṣẹ majẹmu naa, ti inu yin dùn si; kiyesi i, o ń bọ wá, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.” (Malaki 3:1) Nigba wo ni dide ti a ṣeleri sinu tẹmpili naa wáyé? Ni Matteu 11:10, Jesu fa asọtẹlẹ Malaki nipa onṣẹ ti yoo tun ọ̀nà ṣe yọ o si fihàn bi o ti nii ṣe pẹlu Johannu Arinibọmi. (Malaki 4:5; Matteu 11:14) Nitori naa ni 29 C.E., akoko naa fun idajọ ti de! Ta ni onṣẹ keji naa, onṣẹ majẹmu naa ti yoo bá Jehofa ‘Oluwa tootọ naa’ rìn wá sinu tẹmpili? Jesu funraarẹ ni, ati ni akoko iṣẹlẹ meji ó wá sinu tẹmpili ni Jerusalemu ati lọna amunijigiri o wẹ̀ ẹ́ mọ́, ni lílé awọn alabosi onipaṣipaarọ owó sita. (Marku 11:15-17; Johannu 2:14-17) Nipa akoko idajọ ti ọrundun kìn-ín-ní yii, Jehofa beere lọna alasọtẹlẹ pe: “Ta ni ó lè gba ọjọ wiwa rẹ̀? ta ni yoo si duro nigba ti o bá fi ara hàn?” (Malaki 3:2) Niti tootọ, Israeli kò duro. A bẹ wọn wò, wọn kò si kúnjú iwọn, ati ni 33 C.E., a ta wọn nù bii orilẹ-ede ayanfẹ Jehofa.—Matteu 23:37-39.

19. Ni ọ̀nà wo ni aṣẹku kan fi pada sọdọ Jehofa ni ọrundun kìn-ín-ní, ibukun wo ni wọn sì rí gbà?

19 Bi o ti wu ki o ri, Malaki pẹlu tun kọwe pe: “[Jehofa] gbọdọ jokoo gẹgẹ bi olùyọ́mọ́ ati olùwẹ̀mọ́ fadaka kan oun sì gbọdọ yọ́ awọn ọmọ Lefi mọ́; oun sì gbọdọ mu wọn ṣe kedere bii wura ati bii fadaka, dajudaju wọn yoo si jẹ awọn eniyan ti ń mu ọrẹ-ẹbọ ẹbun kan wa ninu ododo si Jehofa.” (Malaki 3:3, NW) Ni ibaramu pẹlu eyi, nigba ti a ta pupọ awọn wọnni ti wọn ń jẹwọ pe awọn ń ṣiṣẹsin Jehofa ni ọrundun kìn-ín-ní nù, awọn kan ni a wẹ̀mọ́ ti wọn wa sọdọ Jehofa, ti wọn ń ru awọn ẹbọ ti o ṣe itẹwọgba. Awọn wo? Awọn ti wọn ti dahunpada si Jesu, onṣẹ majẹmu naa ni. Ni Pentekosti 33 C.E., 120 ninu awọn ti wọn dahunpada wọnyi korajọpọ ni iyara oke kan ni Jerusalemu. Bi ẹmi mimọ ti fun wọn lokun, wọn bẹrẹsii pese ọrẹ-ẹbọ ẹbun ninu ododo, ati ni kiamọsa iye wọn ròkè. Laipẹ, wọn tankalẹ jakejado gbogbo Ilẹ-ọba Romu. (Iṣe 2:41; 4:4; 5:14) Nipa bayii, aṣẹku kan yipada sọdọ Jehofa.—Malaki 3:7.

20. Nigba ti a pa Jerusalemu ati tẹmpili run, ki ni o ṣẹlẹ si Israeli titun ti Ọlọrun?

20 Aṣẹku Israeli yii, ti o wá lati ni awọn Keferi ti a mú wọle ninu, gẹgẹ bi a ti le sọ ọ́, sinu gbòǹgbò-ìdí Israeli, jẹ “Israeli Ọlọrun” titun kan, orilẹ-ede kan tí awọn Kristian ẹni-ami-ororo ti a fi ẹmi bi parapọ jẹ́. (Galatia 6:16; Romu 11:17) Ni 70 C.E., “ọjọ . . . ti . . . [ń] jo bi ina ileru” kan de sori Israeli nipa ti ara nigba ti a pa Jerusalemu ati tẹmpili rẹ̀ run lati ọwọ́ awọn ọmọ ogun Romu. (Malaki 4:1; Luku 19:41-44) Ki ni o ṣẹlẹ si Israeli tẹmi ti Ọlọrun naa? Jehofa fi ‘ìyọ́nú hàn fun wọn, gẹgẹ bi ọkunrin kan ti ń fi ìyọ́nú hàn fun ọmọkunrin rẹ̀ ti o ń ṣiṣẹsin in.’ (Malaki 3:17) Ijọ Kristian ẹni-ami-ororo naa fiyesi ikilọ alasọtẹlẹ Jesu. (Matteu 24:15, 16) Wọn laaja, ibukun Jehofa si ń baa lọ lati mu wọn lọ́rọ̀ nipa tẹmi.

21. Awọn ibeere wo ni o ṣẹku nipa Malaki 3:1 ati 10?

21 Ẹ wo idalare fun Jehofa ti eyi jẹ! Bi o ti wu ki o ri, bawo ni Malaki 3:1 ṣe ń ni imuṣẹ lonii? Bawo ni o ṣe yẹ ki Kristian kan dahunpada si iṣiri tí Malaki 3:10 pese lati mu gbogbo idamẹwaa wa sinu ile iṣura? Eyi ni a o jiroro ninu ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wa ti o tẹle e.

Iwọ Ha Le Ṣalaye Bi?

◻ Ni paripari rẹ̀, ta ni Orisun gbogbo ọlà?

◻ Eeṣe ti aasiki nipa tẹmi fi dara ju ọlà nipa ti ara lọ?

◻ Ète wo ni idamẹwaa ati àwọn irubọ ṣiṣẹ fun ni Israeli?

◻ Nigba wo ni Jehofa, ‘Oluwa tootọ naa,’ wa si tẹmpili lati ṣedajọ Israeli, pẹlu iyọrisi wo si ni?

◻ Ta ni o pada sọdọ Jehofa lẹhin ti o ti de sinu tẹmpili rẹ̀ ni ọrundun kìn-ín-ní C.E.?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Onṣẹ majẹmu naa, Jesu, ni ṣiṣoju fun Jehofa, wa si tẹmpili fun idajọ ni ọrundun kìn-ín-ní C.E.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́