Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Málákì
Ó JU àádọ́rin ọdún lọ tí wọ́n ti parí tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń tún kọ́ ní Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ bí àkókò ti ń lọ, àjọṣe àwọn Júù pẹ̀lú Ọlọ́run kò fi bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán mọ́. Kódà àwọn àlùfáà di oníjẹkújẹ. Ta ló máa mú kí wọ́n mọ ipò tí wọ́n wà, táá sì tún ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Ọlọ́run? Wòlíì Málákì ni Jèhófà gbé iṣẹ́ náà lé lọ́wọ́.
Málákì ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nígbà tó ń kọ ìwé tó kẹ́yìn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, èyí tó ní àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí. Tá a bá ń fiyè sáwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ tí Málákì sọ, á jẹ́ ká lè múra sílẹ̀ de “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà,” èyí tí yóò dé nígbà tí ètò àwọn nǹkan búburú yìí bá wá sópin.—Málákì 4:5.
ÀWỌN ÀLÙFÁÀ “TI MÚ Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ KỌSẸ̀”
Jèhófà sọ bí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Mo nífẹ̀ẹ́ yín.” Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà ti tẹ́ńbẹ́lú orúkọ Ọlọ́run. Lọ́nà wo? “Nípa mímú oúnjẹ eléèérí wá sórí pẹpẹ [rẹ̀],” tí wọ́n sì tún ń fi ‘ẹran tí ó yarọ tàbí èyí tó ń ṣàìsàn’ rúbọ.—Málákì 1:2, 6-8.
Àwọn àlùfáà “ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀ nínú òfin.” Àwọn èèyàn ‘ń ṣe àdàkàdekè sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.’ Àwọn kan lára wọn fi àwọn obìnrin tí kì í ṣe Júù ṣaya. Nígbà táwọn míì sì hùwà àdàkàdekè sí “aya ìgbà èwe [wọn].”—Málákì 2:8, 10, 11, 14-16.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
2:2—Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà “gégùn-ún fún ìbùkún” àwọn àlùfáà tí wọn ò pa òfin rẹ̀ mọ́? Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ṣe èyí ni pé ńṣe ni ìbùkún táwọn àlùfáà yìí ń tọrọ yóò máa já sí ègún.
2:3—Kí ló túmọ̀ sí láti “fọ́n imí” sójú àwọn àlùfáà? Ohun tí òfin Mósè sọ ni pé kí àlùfáà kó imí ẹran tó bá fi rúbọ lọ sí òde ibùdó, kó sì fi iná sun ún níbẹ̀. (Léfítíkù 16:27) Ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé òun máa fọ́n imí sójú àwọn àlùfáà ni pé òun ò ní gba ẹbọ tí wọ́n bá rú sí òun àti pé bí imí gan-an làwọn àlùfáà náà rí sóun.
2:13—Omijé àwọn wo ló bo pẹpẹ Jèhófà mọ́lẹ̀? Omijé aya àwọn ọkùnrin Júù tó wá sí àgbàlá tẹ́ńpìlì láti sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn fún Jèhófà ni. Kí ló kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn? Àwọn ọkọ wọn tí wọ́n jẹ́ Júù ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ torí ohun tí kò tó nǹkan, wọ́n sì pa wọn tì, bóyá nítorí àtifẹ́ ọmọge míì láti ilẹ̀ òkèèrè.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:10. Inú Jèhófà ò dùn sáwọn ẹbọ táwọn àlùfáà jẹgúdújẹrá yìí ń rú. Àwọn àlùfáà yìí máa ń gba owó fún iṣẹ́ tó kéré gan-an, bíi kí wọ́n ti ilẹ̀kùn tàbí kí wọ́n ṣáná sí ẹbọ orí pẹpẹ. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kó jẹ́ ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan tá a ní fún Ọlọ́run àti fún àwọn èèyàn ló ń sún wa jọ́sìn Ọlọ́run, tó sì ń mú ká máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, kó má sì ṣe jẹ́ nítorí owó!—Mátíù 22:37-39; 2 Kọ́ríńtì 11:7.
1:14; 2:17. Jèhófà ò gba ìwà àgàbàgebè láyè.
2:7-9. Gbogbo àwọn tó bá láǹfààní láti máa kọ́ni nínú ìjọ gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ohun tó wà níbàámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tí “olóòótọ́ ìríjú náà” ń tẹ̀ jáde, làwọn fi ń kọ́ni.—Lúùkù 12:42; Jákọ́bù 3:11.
2:10, 11. Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwọn olùjọsìn rẹ̀ tòótọ́ fọwọ́ pàtàkì mú ìmọ̀ràn tó sọ pé ká gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 7:39.
2:15, 16. Àwọn olùjọsìn tòótọ́ kò gbọ́dọ̀ yẹ májẹ̀mú tí wọ́n bá aya ìgbà èwe wọn dá.
‘OLÚWA TÒÓTỌ́ YÓÒ WÁ SÍ TẸ́ŃPÌLÌ RẸ̀’
“Olúwa tòótọ́ [Jèhófà Ọlọ́run] yóò sì wá sí tẹ́ńpìlì Rẹ̀ lójijì” òun pẹ̀lú “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà [Jésù Kristi].” Ọlọ́run ‘yóò sún mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ fún ìdájọ́,’ yóò sì di ẹlẹ́rìí yíyára kánkán lòdì sí gbogbo ẹni tó bá ń hùwà búburú. Láfikún sí i, “ìwé ìrántí kan” yóò wà tí orúkọ àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà máa wà nínú rẹ̀.—Málákì 3:1, 3, 5, 16.
Ọjọ́ “tí ń jó bí ìléru” máa dé, ó sì máa run gbogbo àwọn ẹni ibi. Kí ọjọ́ yẹn tó dé, Jèhófà máa rán wòlíì kan wá, wòlíì yìí máa “yí ọkàn-àyà àwọn baba padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ, àti ọkàn-àyà àwọn ọmọ padà sọ́dọ̀ àwọn baba.”—Málákì 4:1, 5, 6.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
3:1-3—Ìgbà wo ni “Olúwa tòótọ́ náà” àti “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà” wá sínú tẹ́ńpìlì, ta sì lẹni tá a rán ṣáájú wọn? Ẹnì kan ló wá ṣojú fún Jèhófà láti fọ tẹ́ńpìlì rẹ̀ mọ́ ní Nísàn 10, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ìyẹn jẹ́ nígbà tí Jésù wá sínú tẹ́ńpìlì, tó lé àwọn tí wọ́n ń rà tí wọ́n sì ń tà síta. (Máàkù 11:15) Ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ lẹ́yìn tí Jèhófà yan Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba lọ́la lèyí ṣẹlẹ̀. Lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú, ó jọ pé ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ lẹ́yìn tí Jésù di Ọba ní ọ̀run, ó bá Jèhófà lọ sínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, ó sì rí i pé àwọn èèyàn Ọlọ́run nílò ìfọ̀mọ́. Ní ọ̀rúndún kìíní, Jèhófà rán Jòhánù Olùbatisí lọ ṣáájú láti múra àwọn Júù de ìgbà tí Jésù Kristi máa dé. Lóde òní, ońṣẹ́ kan kọ́kọ́ jáde láti múra àwọn èèyàn sílẹ̀ de ìgbà tí Jèhófà máa wá sínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Láti àwọn ọdún 1880, àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ èèyàn láwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì nínú Bíbélì.
3:10—Ṣé tá a bá ṣáà ti ń san “gbogbo ìdá mẹ́wàá” wa, ó túmọ̀ sí pé gbogbo ohun tá a lè fún Jèhófà la ti fún un yẹn? Ikú Jésù ti fòpin sí Òfin Mósè, torí náà kò pọn dandan ká máa san ìdámẹ́wàá lónìí. Síbẹ̀, ìdámẹ́wàá ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan. (Éfésù 2:15) Kò túmọ̀ sí gbogbo ohun tó yẹ ká fún Jèhófà. Nígbà tó jẹ́ pé ọdọọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń san ìdá mẹ́wàá, ńṣe làwa fún Jèhófà ní gbogbo ohun tó jẹ́ tiwa nígbà tá a ṣèyàsímímọ́, tá a sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Látìgbà yẹn lọ, gbogbo ohun tá a ní di ti Jèhófà. Síbẹ̀, ó ṣì gbà wá láyè láti yan ìwọ̀n tá a máa lò lára ohun tá a ní yìí fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ìyẹn sì ni ìdámẹ́wàá ń ṣàpẹẹrẹ. Tó túmọ̀ sí pé ká máa ṣe gbogbo ohun tí ipò wa bá yọ̀ǹda fún wa láti ṣe àtèyí tí ọkàn wa sún wa ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Lára àwọn ohun tá a fi ń rúbọ sí Jèhófà ni àkókò wa, agbára wa àtàwọn ohun ìní wa tá à ń lò nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Ó sì tún kan lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aláìsàn àtàwọn àgbàlagbà tá a jọ ń sin Jèhófà, àti fífowó ṣètìlẹyìn fún ìjọsìn tòótọ́.
4:3—Ọ̀nà wo làwọn olùjọsìn Jèhófà máa gbà “tẹ àwọn ẹni burúkú mọ́lẹ̀”? Kì í ṣe pé àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé máa fi ẹsẹ̀ wọn “tẹ àwọn ẹni burúkú mọ́lẹ̀,” ìyẹn ni pé káwọn àti Ọlọ́run jọ pa àwọn ẹni burúkú run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà lórí ilẹ̀ ayé máa fi tọkàntọkàn kópa nínú ayẹyẹ ìṣẹ́gun tó máa wáyé lẹ́yìn tí ayé Sátánì bá ti pa run.—Sáàmù 145:20; Ìṣípayá 20:1-3.
4:4—Kí nìdí tó fi yẹ ká “rántí òfin Mósè”? Àwọn Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin yẹn, síbẹ̀ ó jẹ́ “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀.” (Hébérù 10:1) Nítorí náà, tá a bá fiyè sí Òfin Mósè a ó lè rí bí àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ṣe ń nímùúṣẹ. (Lúùkù 24:44, 45) Bákan náà, “àwọn àwòrán ìṣàpẹẹrẹ àwọn ohun ti ọ̀run” wà nínú Òfin náà. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tá a bá fẹ́ lóye àwọn ẹ̀kọ́ àti ìwà Kristẹni.—Hébérù 9:23.
4:5, 6—Ta ni “Èlíjà wòlíì” dúró fún? Àsọtẹ́lẹ̀ Málákì sọ pé “Èlíjà” máa ṣe iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò kan, ìyẹn ni pé ó máa múra àwọn èèyàn sílẹ̀. Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, Jésù Kristi pe Jòhánù Olùbatisí ni “Èlíjà.” (Mátíù 11:12-14; Máàkù 9:11-13) Lóde òní, ẹni tó dà bí Èlíjà yẹn ni Ọlọ́run rán wá “ṣáájú dídé ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà.” Kò sí ẹlòmíì lóde òní tí Èlíjà yẹn dúró fún ju ‘ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà.’ (Mátíù 24:45) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yìí ti ń sa gbogbo ipá wọn láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
3:10. A ò lè rí ìbùkún Jèhófà gbà tá ò bá ṣe gbogbo ohun tó yẹ ká ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.
3:14, 15. Nítorí àpẹẹrẹ burúkú táwọn àlùfáà fi lélẹ̀, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í wo iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run bí nǹkan tí ò ṣe pàtàkì. Àwọn tí wọ́n ń mú ipò iwájú nínú ìjọ Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ rere.—1 Pétérù 5:1-3.
3:16. Jèhófà ní àkọsílẹ̀ gbogbo àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ tí wọ́n sì tún jẹ́ olóòótọ́ sí i. Kò gbàgbé wọn, ó sì máa dá wọn sí nígbà tó bá máa pa ayé búburú Sátánì run. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun mú wa yẹ ìpinnu tá a ti ṣe pé a ó máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láìyẹsẹ̀.—Jóòbù 27:5.
4:1. Nígbà tí Jèhófà bá máa ṣèdájọ́, ìdájọ́ kan náà tí “gbòǹgbò” bá gbà náà ni “ẹ̀tun” máa gbà, ìyẹn ni pé ìdájọ́ táwọn òbí bá gbà náà làwọn ọmọ wọn kéékèèké máa gbà. Ẹ ò rí i pé àwọn òbí níṣẹ́ láti ṣe kí wọ́n má bàa kó bá àwọn ọmọ wọn kéékèèké! Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ sapá gidigidi kí wọ́n lè rí ojú rere Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 7:14.
“Bẹ̀rù Ọlọ́run Tòótọ́”
Ta ló máa yè bọ́ ní “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà”? (Málákì 4:5) Jèhófà sọ pé: “Oòrùn òdodo yóò sì ràn dájúdájú fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, pẹ̀lú ìmúniláradá ní ìyẹ́ apá rẹ̀; ẹ ó sì jáde lọ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì fi àtẹ́sẹ̀ talẹ̀ bí àwọn ọmọ màlúù àbọ́sanra.”—Málákì 4:2.
Jésù Kristi tó jẹ́ “oòrùn òdodo,” yóò ràn sórí àwọn tí wọ́n bẹ̀rù orúkọ Ọlọ́run látọkànwá, èyí á sì mú kí wọ́n rí ojú rere Jèhófà. (Jòhánù 8:12) “Ìmúniláradá [wà] ni ìyẹ́ apá rẹ̀” fáwọn tí wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run, ìyẹn ni pé àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run máa dára sí i nísinsìnyí, àti pé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run máa mú wá, wọ́n á dẹni tá a mú lára dá pátápátá, ẹ̀dùn ọkàn wọn á sì fò lọ. (Ìṣípayá 22:1, 2) Ìdùnnú wọn tó ṣubú layọ̀ mú kí wọ́n máa ṣe “bí àwọn ọmọ màlúù àbọ́sanra.” Bá a ṣe rí i pé ọ̀pọ̀ ìbùkún bẹ́ẹ̀ ló ń dúró dè wá, ẹ jẹ́ ká fi ìmọ̀ràn Sólómọ́nì Ọba sọ́kàn, ó sọ pé: “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”—Oníwàásù 12:13.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Wòlíì Málákì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó nítara tó sì tún fara jin iṣẹ́ Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ohun tó bá Bíbélì mu la gbọ́dọ̀ máa fi kọ́ni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kì í yẹ májẹ̀mú ìgbéyàwó tí wọ́n bá ọkọ tàbí aya wọn dá