Kọ́ Ọmọ Rẹ
Jótámù Jẹ́ Olóòótọ́ Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Bàbá Rẹ̀ Kò Sin Jèhófà Mọ́
TÍ ÒBÍ ọmọ kan kò bá sin Jèhófà Ọlọ́run mọ́, èyí lè mú kí nǹkan nira fún ọmọ náà. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Jótámù. A máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó ní nílé wọn nígbà tó wà lọ́mọdé.
Ùsáyà ọba Júdà ni bàbá Jótámù. Òun ni ipò rẹ̀ ga jù ní orílẹ̀-èdè náà. Ọ̀pọ̀ ọdún ni Ùsáyà fi jẹ́ ọba dáadáa kí ó tó bí Jótámù. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, Ùsáyà bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, ó sì ṣàìgbọràn sí Òfin Ọlọ́run. Torí náà Ọlọ́run mú kó ní àrùn burúkú kan tí wọ́n ń pè ní ẹ̀tẹ̀, ó sì di adẹ́tẹ̀. Ọmọ kékeré ṣì ni Jótámù ní gbogbo àkókò yìí. Ǹjẹ́ o mọ nǹkan tí Jótámù wá ṣe?—a
Jótámù ń bá a lọ láti máa sin Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé màmá rẹ̀ Jẹ́rúṣà ni ó ràn án lọ́wọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, ó dà bí ẹni pé ó máa ṣòro fún Jótámù láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lẹ́yìn tí wọ́n ti lé Ùsáyà bàbá rẹ̀ jáde kúrò ní ilé Jèhófà.
Tó bá ṣẹlẹ̀ pé bàbá rẹ tàbí màmá rẹ kò sin Jèhófà mọ́ ńkọ́? Ǹjẹ́ ìyẹn kò ní mú kí nǹkan nira fún ọ?— Kò burú rárá tí o bá ronú pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀. Ohun tí Dáfídì kọ sínú Bíbélì fi hàn pé kò burú. Jẹ́ ká wò ó.
Jésè ni orúkọ bàbá Dáfídì. Jésè yìí jẹ́ èèyàn dáadáa. Jèhófà ni ó ń sìn, ó sì dájú pé Dáfídì fẹ́ràn bàbá rẹ̀. Àmọ́ Dáfídì kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Jèhófà, ó sì wá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ju Jésè tó jẹ́ bàbá rẹ̀ lọ. Jẹ́ ká wo bí a ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀.
Jọ̀wọ́ ṣí Bíbélì rẹ sí Sáàmù 27:10. Dáfídì sọ níbẹ̀ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” Rò ó wò ná: Ohun tí Bíbélì ń sọ níbí yìí ni pé tó bá ṣẹlẹ̀ pé Jésè bàbá Dáfídì tàbí màmá rẹ̀ kò sin Jèhófà mọ́, Dáfídì kò ní ṣíwọ́ láti máa sin Jèhófà.
Ìwọ ńkọ́? Ṣé wàá ṣì máa sin Jèhófà kódà bí bàbá rẹ àbí màmá rẹ kò bá sìn ín mọ́?— Ó dára kí o bi ara rẹ ní ìbéèrè yìí. Òfin tó ṣe pàtàkì jù nínú Bíbélì sọ ìdí tó fi yẹ kí o bi ara rẹ ní ìbéèrè yìí. Ó ní: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.”
Ohun tí òfin yìí túmọ̀ sí ni pé a gbọ́dọ̀ máa sin Jèhófà títí lọ, kódà bí kò bá tiẹ̀ rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ta ni o rò pé ó máa fẹ́ ká fi Jèhófà sílẹ̀ ká má sìn ín mọ́?— Sátánì Èṣù ni. Ó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run. Jésù pè é ní “olùṣàkóso ayé yìí.” Bíbélì tún sọ pé òun ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” Àmọ́ o, ṣé ó dára ká máa bẹ̀rù Sátánì?—
Rárá o. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà lágbára ju Sátánì lọ. Jèhófà máa dáàbò bò wá tí a bá gbẹ́kẹ̀ lé e. Kà nípa bí Jèhófà ṣe gba Dáfídì lọ́wọ́ Gòláyátì tó jẹ́ òmìrán tó ń báni lẹ́rù gan-an, nínú Bíbélì rẹ. Jèhófà máa dáàbò bò ọ́ tí o bá ń bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́ sí i.
Kà á nínú Bíbélì rẹ
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Kà á nínú Bíbélì rẹ
a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.