OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Kí ni orúkọ Ọlọ́run?
Gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé wa ló ní orúkọ. Àwọn ẹran tí à ń sìn nínú ilé pàápàá ní orúkọ tí à ń pè wọ́n! Ǹjẹ́ kò wá yẹ kí Ọlọ́run náà ní orúkọ? Ọ̀pọ̀ orúkọ oyè bí Ọlọ́run Olódùmarè, Olúwa Ọba Aláṣẹ àti Ẹlẹ́dàá ni wọ́n pe Ọlọ́run nínú Bíbélì, àmọ́ ó ní orúkọ tí ó ń jẹ́ gan-an.—Ka Aísáyà 42:8.
Nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì, orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an fara hàn ní Sáàmù 83:18. Bí àpẹẹrẹ, nínú Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ẹsẹ yẹn sọ pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo orúkọ Ọlọ́run?
Tí a bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ojúlùmọ̀ wa tí a fẹ́ràn sọ̀rọ̀, a máa ń lo orúkọ wọn
Ọlọ́run fẹ́ ká máa lo orúkọ òun. Tí a bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ojúlùmọ̀ wa tí a fẹ́ràn sọ̀rọ̀, a máa ń lo orúkọ wọn. Ọlọ́run náà ńkọ́? Ó fẹ́ ká máa lo orúkọ òun tí a bá ń bá òun sọ̀rọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù Kristi pàápàá rọ̀ wá pé ká máa lo orúkọ Ọlọ́run.—Ka Mátíù 6:9; Jòhánù 17:26.
Àmọ́ ṣá o, tí a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kì í ṣe orúkọ rẹ̀ nìkan ni a máa mọ̀, a tún gbọ́dọ̀ mọ àwọn nǹkan míì nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, irú ẹni wo gan-an ni Ọlọ́run jẹ́? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí wà nínú Bíbélì.