KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN
Ǹjẹ́ O Mọ Orúkọ Ọlọ́run, Ṣé O Máa Ń Lò Ó?
Ǹjẹ́ ẹnì kankan wà nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí o kò mọ orúkọ rẹ̀? Bóyá ni. Obìnrin kan ní Bulgaria tó ń jẹ́ Irina sọ pé, “Kò ṣeé ṣe láti sún mọ́ Ọlọ́run tó ò bá mọ orúkọ rẹ̀.” Ṣé o rántí pé ohun tá a sọ nínú àkòrí tó ṣáájú nìyẹn. Inú wa sì dùn pé Ọlọ́run fẹ́ ká sún mọ́ òun, ó tiẹ̀ sọ orúkọ ara rẹ̀ fún wa nínú Bíbélì, ó ní: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.”—Aísáyà 42:8.
Ọlọ́run fẹ́ ká sún mọ́ òun, ó tiẹ̀ sọ orúkọ rẹ̀ fún wa nínú Bíbélì ó ní: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.”—Aísáyà 42:8
Ǹjẹ́ Jèhófà fẹ́ kó o máa lo orúkọ òun? Rò ó wò ná: Lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà. Kò sí orúkọ míì tó fara hàn tó bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì. Àmì nìyẹn jẹ́ pé Jèhófà fẹ́ kó o mọ orúkọ òun, kó o sì máa lò ó.a
Táwọn méjì bá fẹ́ di ọ̀rẹ́, orúkọ ara wọn ni wọ́n máa ń kọ́kọ́ béèrè. Ǹjẹ́ o mọ orúkọ Ọlọ́run?
Ṣùgbọ́n ohun táwọn kan rò ni pé torí Ọlọ́run jẹ́ ẹni mímọ́, òun sì ni olódùmarè, ìwà àrífín ni kéèyàn máa la orúkọ mọ́ ọn. Ká sòótọ́, ìwà àrífín ni téèyàn bá lo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí kò tọ́, ó ṣe tán, àwa náà ò jẹ́ fi orúkọ ọ̀rẹ́ wa wọ́lẹ̀. Àmọ́, Jèhófà fẹ́ kí àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀ máa gbé orúkọ rẹ̀ ga kí wọ́n sì máa pòkìkí rẹ̀ fún aráyé gbọ́. (Sáàmù 69:30, 31; 96:2, 8) Ṣé o rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? Ó ní kí wọ́n máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” Bí ìwọ náà bá ń sọ orúkọ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, ńṣe lò ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, wàá sì tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ Ọlọ́run sí i.—Mátíù 6:9.
Bíbélì tiẹ̀ fi hàn pé Ọlọ́run máa ń dìídì fiyè sí “àwọn tó ń ronú lórí [tàbí “mọyì”] orúkọ rẹ̀.” (Málákì 3:16) Jèhófà ṣèlérí fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé: ‘Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi. Òun yóò ké pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn. Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nígbà wàhálà.’ (Sáàmù 91:14, 15) Ẹ ò rí i báyìí pé tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, ó ṣe pàtàkì ká mọ orúkọ Ọlọ́run ká sì máa lò ó.
a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ yẹn fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù, èyí táwọn kan ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé, ó yani lẹ́nu pé àwọn kan dìídì yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì. Wọ́n wá fi àwọn orúkọ oyè bí “Olúwa” tàbí “Ọlọ́run” rọ́pò rẹ̀. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tá a sọ yìí, wo ojú ìwé 195 sí 197 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.