Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
January 15, 2013
© 2013 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania..
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
FEBRUARY 25, 2013–MARCH 3, 2013
Jẹ́ Onígboyà, Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ!
MARCH 4-10, 2013
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Ẹ Jìnnà sí Jèhófà
MARCH 11-17, 2013
MARCH 18-24, 2013
O Lè Sin Jèhófà Kó O Má sì Kábàámọ̀
MARCH 25-31, 2013
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Jẹ́ Onígboyà, Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ!
Bíbélì sọ fún wa nípa ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà. Ìrírí wọn máa fún ìgbàgbọ́ wa lókun, ó sì máa jẹ́ kí àwa náà máa fi ìgboyà sin Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí la ti máa jíròrò ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2013.
▪ Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Ẹ Jìnnà sí Jèhófà
▪ Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà láyé yìí tí a kò lè fi ọwọ́ ara wa yàn. Lára wọn ni àwọn òbí wa, ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò wa àti ibi tí wọ́n máa bí wa sí. Ṣùgbọ́n a lè yàn bóyá a máa sún mọ́ Ọlọ́run tàbí a máa jìnnà sí i. Nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun méje tí a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó mú wa jìnnà sí Jèhófà.
▪ O Lè Sin Jèhófà Kó O Má sì Kábàámọ̀
Gbogbo wa la ti kábàámọ̀ rí, tó sì ṣe wá bíi pé ká ṣàtúnṣe àwọn ohun kan tá a ti ṣe kọjá. Àmọ́, tá a bá ń ṣàníyàn jù nípa àwọn àṣìṣe wa, kò ní ṣeé ṣe fún wa láti fi iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti sin Jèhófà ká má sì kábàámọ̀.
▪ Àwọn Alàgbà Jẹ́ ‘Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún Ìdùnnú Wa’
Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà kejì tó kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé òun àtàwọn táwọn jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ jẹ́ ‘alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú wọn.’ (2 Kọ́r. 1:24) Kí làwọn alàgbà lè rí kọ́ látinú gbólóhùn yìí? Báwo la sì ṣe lè máa ran ara wa lọ́wọ́ ká lè máa bá a nìṣó láti fayọ̀ sin Ọlọ́run? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Norway
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Tọkọtaya kan tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní iwájú ilé kan ní Àgọ́ Perrin. Bíi ti tọkọtaya yìí, àwọn ọmọ ìlú Haiti kan tí wọ́n ń gbé lókè òkun ti ń pa dà sí orílẹ̀-èdè wọn kí wọ́n lè lọ máa wàásù níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i
HAITI
IYE ÈÈYÀN TÍ AKÉDE KAN Á WÀÁSÙ FÚN NÍ HAITI
1:557
IYE AKÉDE
17,954
ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
35,735