Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
February 15, 2013
© 2013 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
APRIL 1-7, 2013
APRIL 8-14, 2013
APRIL 15-21, 2013
APRIL 22-28, 2013
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Èyí Ni Ogún Tẹ̀mí Wa
▪ Ǹjẹ́ O Mọyì Ogún Tẹ̀mí Wa?
Nínú àwọn àpilẹ̀kọ́ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àkànṣe ogún tí Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀. Àwọn àpilẹ̀kọ náà tún máa jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe pa Bíbélì mọ́, bí kò ṣe jẹ́ kí orúkọ Rẹ̀ di ìgbàgbé àti bó ṣe jẹ́ ká mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́.
▪ Dúró sí Ibi Ààbò Jèhófà
Ìwé Sekaráyà 14:4 sọ̀rọ̀ nípa àfonífojì ńlá kan. Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ohun tí àfonífojì tó jẹ́ ibi ààbò yìí túmọ̀ sí àti ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ dúró síbẹ̀. Bákan náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ohun tí Sekaráyà 14:8 pè ní omi ààyè àti àǹfààní tó máa jẹ́ tiwa tá a bá mu nínú omi náà.
▪ Sá fún Àwọn Nǹkan Tí Kò Ní Jẹ́ Kí Ọlọ́run Dá Ẹ Lọ́lá
Jèhófà máa ń dá àwa èèyàn lọ́lá. Àpilẹ̀kọ yìí sọ ohun tó lè mú kó dá wa lọ́lá. Ó jẹ́ ká mọ ohun tó lè mú kí Ọlọ́run má ṣe dá wa lọ́lá. Ó sì sọ bí ìfaradà wa ṣe lè mú kí Ọlọ́run dá àwọn míì lọ́lá.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
13 Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Olú Ọba Gbọ́ Ìhìn Rere
22 Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọkàn Rẹ Tàn Ẹ́ Jẹ
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ní àríwá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàmíbíà, akéde kan ń wàásù fún obìnrin Himba kan. Màlúù ni àwọn ẹ̀yà Himba tó wà ní orílẹ̀-èdè yìí máa ń dà. Àwọn obìnrin wọn máa ń lọ òkúta pupa tí wọ́n gé láti ara àpáta, wọ́n á wá fi ṣe èròjà tí wọ́n fi ń pa ara àti irun wọn
NÀMÍBÍÀ
IYE ÈÈYÀN
2,373,000
IYE AKÉDE
2,040
ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
4,192