Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
April 15, 2013
© 2013 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
JUNE 3-9, 2013
Jàǹfààní Kíkún Látinú Kíka Bíbélì Déédéé
JUNE 10-16, 2013
Fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ran Ara Rẹ àti Àwọn Míì Lọ́wọ́
JUNE 17-23, 2013
Ẹ Máa Wádìí Dájú Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù
JUNE 24-30, 2013
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Jàǹfààní Kíkún Látinú Kíka Bíbélì Déédéé
▪ Fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ran Ara Rẹ àti Àwọn Míì Lọ́wọ́
Pọ́ọ̀lù sọ pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Héb. 4:12) Àmọ́, ká tó lè jàǹfààní látinú agbára yẹn, àfi ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì máa fi àwọn nǹkan tá a bá ń kọ́ sílò. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tá a lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì tún ṣàlàyé bá a ṣe lè máa lo ọgbọ́n Ọlọ́run lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa àti nínú ìgbé ayé wa.
▪ Ẹ Máa Wádìí Dájú Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù
▪ Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Àárẹ̀ Mú Yín
Àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ fún wa pé a wà lára ètò àgbàyanu Ọlọ́run tó ní apá ti ọ̀run àti ti ayé. Àmọ́, báwo la ṣe lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò náà lóde òní? Kí la lè ṣe tí a ó fi máa jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú ètò Jèhófà tí a kò sì ní rẹ̀wẹ̀sì? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Mẹ́síkò
17 A Fi Àádọ́ta Ọdún Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Ní Ilẹ̀ Olótùútù
32 Ǹjẹ́ O Mọ̀?
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Aago méje ààbọ̀ òwúrọ̀ ni ìjọ tó pọ̀ jù lọ máa ń pàdé láti jáde òde ẹ̀rí. Ó sì máa ń yá wọn jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà míì. Wọ́n máa ń wàásù fún àwọn tí wọ́n bá rí ní òpópónà
NEPAL
IYE ÈÈYÀN
26,620,809
IYE AKÉDE
1,667
ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
3,265