Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
May 15, 2013
© 2013 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
JULY 1-7, 2013
Máa Ṣe Ojúṣe Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ajíhìnrere
JULY 8-14, 2013
Ǹjẹ́ O Ní Ìtara fún “Iṣẹ́ Àtàtà”?
JULY 15-21, 2013
Ẹ Máa Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀ Kẹ́ Ẹ Lè Túbọ̀ Ṣera Yín Lọ́kan
JULY 22-28, 2013
Ẹ̀yin Òbí Àtẹ̀yin Ọmọ, Ẹ Máa Fìfẹ́ Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀
JULY 29, 2013–AUGUST 4, 2013
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Máa Ṣe Ojúṣe Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ajíhìnrere
Ta ni ajíhìnrere? Kí nìdí tó fi yẹ káwọn èèyàn gbọ́ ìhìn rere? A máa rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè méjèèjì nínú àpilẹ̀kọ yìí. A tún máa mọ bá a ṣe lè máa ṣe ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere.
▪ Ǹjẹ́ O Ní Ìtara fún “Iṣẹ́ Àtàtà”?
Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò méjì lára àwọn “iṣẹ́ àtàtà” tá à ń fìtara ṣe, tó ń mú káwọn èèyàn wá jọ́sìn Ọlọ́run. (Títù 2:14) Àkọ́kọ́, iṣẹ́ ìwàásù wa. Èkejì sì ni ìwà wa.
▪ Ẹ Máa Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀ Kẹ́ Ẹ Lè Túbọ̀ Ṣera Yín Lọ́kan
▪ Ẹ̀yin Òbí Àtẹ̀yin Ọmọ, Ẹ Máa Fìfẹ́ Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀
Ó ṣe pàtàkì pé kí tọkọtaya máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè ṣera wọn lọ́kan, kí ìgbéyàwó wọn sì lè ládùn. Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ jíròrò àwọn ànímọ́ táá jẹ́ kí wọ́n lè máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà. Àpilẹ̀kọ kejì jẹ́ ká mọ ohun táwọn òbí àtàwọn ọmọ lè ṣe tí wọ́n fi lè máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà.
▪ Máa Ṣe Ìpinnu Tó Dára Kó O Má Bàa Pàdánù Ogún Tẹ̀mí Rẹ
Ogún tẹ̀mí wo làwa Kristẹni ní? Kí la rí kọ́ lára Ísọ̀? Àwọn nǹkan wo la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání? A máa rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí..
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
13 Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
24 Ohun Tó Mú Kí Ìgbésí Ayé Wa Nítumọ̀
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Àwọn arábìnrin wa ń fi ìwé tó wà lédè Gujarati lọ ọkùnrin oníṣòwò kan nílùú London
LONDON, ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ