Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
July 15, 2013
© 2013 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
SEPTEMBER 2-8, 2013
Sọ fún Wa, Ìgbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yóò Ṣẹlẹ̀?
SEPTEMBER 9-15, 2013
“Wò ó! Mo Wà Pẹ̀lú Yín ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”
SEPTEMBER 16-22, 2013
Jésù Ń Tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn
SEPTEMBER 23-29, 2013
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Sọ fún Wa, Ìgbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yóò Ṣẹlẹ̀?
▪ “Wò ó! Mo Wà Pẹ̀lú Yín ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”
Àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí jíròrò díẹ̀ lára àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tó wà nínú ìwé Mátíù orí 24 àti 25. Wọ́n jẹ́ ká mọ àwọn òye tuntun tá a ní nípa ìgbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn àti àkàwé nípa àlìkámà àti èpò máa ṣẹ. Wọ́n tún jẹ́ ká mọ bí òye tuntun tá a ní yìí ṣe lè ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láǹfààní.
▪ Jésù Ń Tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn
▪ “Ní Ti Tòótọ́, Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?”
Yálà Jésù ń pèsè oúnjẹ fún ogunlọ́gọ̀ ni o, tàbí ó ń fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ọ̀nà kan náà ló máa ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ni pé, ó máa ń tipasẹ̀ àwọn kéréje bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn. Àkọ́kọ́ nínú àpilẹ̀kọ méjì yìí máa jẹ́ ká mọ àwọn kéréje tó lò láti bọ́ àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn ní ọ̀rúndún kìíní. Èkejì dáhùn ìbéèrè pàtàkì yìí: Àwọn kéréje wo ni Kristi ń lò láti bọ́ wa lónìí?
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
26 Ẹnì Kan Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Arákùnrin yìí ń wàásù láti ilé dé ilé ní Bukimba, Runda, lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà
RÙWÁŃDÀ
Ìdá mẹ́rin àwọn ará tó wà lórílẹ̀-èdè yìí ló ń kópa nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kan tàbí òmíràn. Àwọn ará yòókù sì ń lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà. Ní ìpíndọ́gba, wọ́n ń lo ogun [20] wákàtí lóṣooṣù
IYE ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ
22,734
ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
52,123
ÀWỌN TÓ WÁ SÍBI ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI LỌ́DÚN 2012
69,582