Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
August 15, 2013
© 2013 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
SEPTEMBER 30, 2013–OCTOBER 6, 2013
OCTOBER 7-13, 2013
Má Ṣe “Kún fún Ìhónú sí Jèhófà”
OCTOBER 14-20, 2013
Ẹ Máa Gba Ti Ara Yín Rò Kẹ́ Ẹ sì Máa fún Ara Yín Ní Ìṣírí
OCTOBER 21-27, 2013
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ A Ti Sọ Yín Di Mímọ́
A ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, torí náà, Ọlọ́run sọ wá di mímọ́ tàbí pé ó yà wá sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò orí kẹtàlá ìwé Nehemáyà. A máa jíròrò kókó mẹ́rin tó lè mú ká máa jẹ́ mímọ́ nìṣó.
▪ Má Ṣe “Kún fún Ìhónú sí Jèhófà”
Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò nǹkan márùn-ún tó lè mú kí Kristẹni kan tó jẹ́ olóòótọ́ “kún fún ìhónú sí Jèhófà.” (Òwe 19:3) Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ àwọn ọ̀nà márùn-ún tá a lè gbà yẹra fún dídá Jèhófà lẹ́bi pé òun ló fa ìṣòro wa.
▪ Ẹ Máa Gba Ti Ara Yín Rò Kẹ́ Ẹ sì Máa fún Ara Yín Ní Ìṣírí
▪ Máa Ronú Nípa Irú Ẹni Tó Yẹ Kó O Jẹ́
Àkọ́kọ́ nínú àpilẹ̀kọ méjì yìí jíròrò bá a ṣe lè ran ara wa lọ́wọ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ láìka àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra sí. Àpilẹ̀kọ kejì sọ bá a ṣe lè borí àwọn ìdẹwò tí Sátánì ń lò láti fi ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
8 Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
9 Jèhófà ‘Ń Bá Mi Gbé Ẹrù Mi Lójoojúmọ́’
15 Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Ọmọ Yín Láti Kékeré
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ń wàásù láti ilé dé ilé ní abúlé Erap. Abúlé yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn abúlé tó wà káàkiri lórí òkè òun pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní agbègbè Morobe, lórílẹ̀-èdè Papua New Guinea
PAPUA NEW GUINEA
Iye Èèyàn: 7,013,829
Ìpíndọ́gba Akéde: 3,770
Iye Aṣáájú-ọ̀nà Déédéé: 367
Ìpíndọ́gba Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: 5,091
Àwọn Tó Wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2012: 28,909
Iye Èdè Tá À Ń Tú Ìwé Wa Sí: 14
Ní ìpíndọ́gba, ẹni mẹ́fà ni akéde kọ̀ọ̀kan pè wá síbi Ìrántí Ikú Kristi