ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 11/1 ojú ìwé 5
  • Wọ́n Parọ́ Pé Àdììtú Ni Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Parọ́ Pé Àdììtú Ni Ọlọ́run
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bawo Ni Wọn Ṣe Ṣàlàyé Mẹtalọkan?
    Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?
  • Apa Kì-ín-ní—Jesu ati Awọn Ọmọ-ẹhin Rẹ̀ Ha Fi Ẹkọ Mẹtalọkan Kọni Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Mẹ́talọ́kan—A Ha Fi Kọ́ni Nínú Bibeli Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Iwọ Ha Nilati Gbà Á Gbọ́ Bí?
    Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 11/1 ojú ìwé 5
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | ÀWỌN IRỌ́ TÍ KÒ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN

Wọ́n Parọ́ Pé Àdììtú ni Ọlọ́run

OHUN TÍ Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN GBÀ GBỌ́

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n pín ẹ̀sìn Kristẹni sí, ìyẹn ẹ̀sìn Kátólíìkì, ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ìlà Oòrùn àti ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì gbà pé Mẹ́talọ́kan ni Ọlọ́run. Wọ́n ní Ọlọ́run Baba, Ọlọ́run Ọmọ àti Ọlọ́run Ẹ̀mí Mímọ́ ló wà. Nínú ẹ̀kọ́ ìsìn àwọn Kristẹni, wọ́n gbà pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kì í ṣe ọlọ́run ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ńṣe ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ Ọlọ́run kan ṣoṣo.”

ÒTÍTỌ́ TÍ BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ̀

Ọmọ ni Jésù jẹ́ sí Ọlọ́run, kò sì sọ ọ́ rí pé òun bá Bàbá òun dọ́gba tàbí pé àwọn méjèèjì jẹ́ ọ̀kan-náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Mo ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí pé Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28) Ó tún sọ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run yín.”—Jòhánù 20:17.

Ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe Ọlọ́run. Àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni “kún fún ẹ̀mí mímọ́,” Jèhófà tiẹ̀ sọ pé: “Èmi yóò sì tú lára ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara.” (Ìṣe 2:1-4, 17) Torí náà, ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe Ọlọ́run. Agbára Ọlọ́run ni.

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ FI ṢE PÀTÀKÌ

Ọ̀gbẹ́ni Karl Rahner àti ọ̀gbẹ́ni Herbert Vorgrimler, tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé nípa ẹ̀sìn Kátólíìkì ṣàlàyé pé: “Láìsí ìṣípayá a ò lè mọ Mẹ́talọ́kan, kódà lẹ́yìn ìṣípayá a ò lè lóye rẹ̀ ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́.” Ǹjẹ́ o lè nífẹ̀ẹ́ ẹni tí kò ṣe é mọ̀ tàbí ẹni tó ṣòro lóye? Bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, ó dà bí ohun ìdènà tí kò lè jẹ́ kéèyàn mọ Ọlọ́run tàbí kéèyàn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Marco, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ pé: “Mo rò pé Ọlọ́run ń fara pamọ́ fún mi, ìyẹn ló túbọ̀ jẹ́ kó jìnnà sí mi, ó sì wá dà bí àdììtú àti ẹni tí mi ò lè sún mọ́ rárá.” Àmọ́, “Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu.” (1 Kọ́ríńtì 14:33) Kò fi ara rẹ̀ pamọ́ fún wa. Ó fẹ́ kí a mọ òun. Jésù sọ pé: “Àwa ń jọ́sìn ohun tí àwa mọ̀.”—Jòhánù 4:22.

Marco tún sọ pé: “Ìgbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kì í ṣe Mẹ́talọ́kan ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá di ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Dípò ká máa wo Ọlọ́run bí àdììtú, á dáa ká máa wò ó bí Ẹnì tá a lè mọ̀, èyí á mú kó rọrùn fún wa láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 Jòhánù 4:8.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́