Mẹ́talọ́kan—A Ha Fi Kọ́ni Nínú Bibeli Bí?
“Èyí ni Ìgbàgbọ́ Katoliki, pé àwa ń jọ́sìn Ọlọrun kan nínú Mẹ́talọ́kan àti Mẹ́talọ́kan nínú Ìṣọ̀kan. . . . Nítorí náà Bàbá jẹ́ Ọlọrun, Ọmọ jẹ́ Ọlọrun, Ẹ̀mí Mímọ́ sì jẹ́ Ọlọrun. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọn kìí ṣe Ọlọrun Mẹ́ta, ṣùgbọ́n Ọlọrun Kan.”
PẸ̀LÚ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí Ìjẹ́wọ́-Ìgbàgbọ́ Athanasius ṣàpèjúwe ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ ṣíṣe pàtàkì jùlọ ti Kristẹndọm—Mẹ́talọ́kan.a Bí ìwọ bá jẹ́ mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì kan, Katoliki tàbí Protẹstanti, a lè sọ fún ọ pé èyí ni ẹ̀kọ́ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí o níláti ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìwọ ha lè ṣàlàyé ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ náà bí? Díẹ̀ lára àwọn ọlọ́gbọ́nlóye ènìyàn nínú Kristẹndọm ti jẹ́wọ́ àìtóótun wọn láti lóye Mẹ́talọ́kan.
Èéṣe, nígbà náà, tí wọ́n fi gbà á gbọ́? Ó ha jẹ́ nítorí pé Bibeli fi ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ náà kọ́ni ni bí? Bíṣọ́ọ̀bù ìjọ Anglica John Robinson tí ó ti dolóògbé fúnni ní ìdáhùn tí ń ru ìrònú sókè sí ìbéèrè yìí nínú ìwé rẹ̀ tí ó tà dáradára jùlọ nì Honest to God. Ó kọ̀wé pé:
“Níti gidi ìwàásù àti ìkọ́ni tí ó lókìkí gbé ojú-ìwòye Kristi tí ó jẹ́ Ọlọrun kalẹ̀ èyí tí a kò lè fi ẹ̀rí tì lẹ́yìn láti inú Májẹ̀mú Titun. Ó sọ lọ́nà kan pàtó pé Jesu jẹ́ Ọlọrun, ní irú ọ̀nà kan tí àwọn èdè-ìsọ̀rọ̀ náà ‘Kristi’ àti ‘Ọlọrun’ gbà jẹ́ èyí tí ó ṣeé fi rọ́pò ara. Ṣùgbọ́n kò sí ibìkankan tí èyí ti rí bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí Bibeli gbà lò ó. Májẹ̀mú Titun sọ pé Jesu jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ó sọ pé Ọlọrun wà nínú Kristi, ó sọ pé Jesu ni Ọmọkùnrin Ọlọrun; ṣùgbọ́n kò sọ pé Jesu jẹ́ Ọlọrun, lọ́nà kan pàtó bẹ́ẹ̀.”
John Robinson jẹ́ ẹnì tí ó fa àríyànjiyàn nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Anglica. Síbẹ̀, òun ha tọ̀nà nínú sísọ pé “Májẹ̀mú Titun” kò sọ ní ibìkankan pé “Jesu jẹ́ Ọlọrun, lọ́nà kan pàtó bẹ́ẹ̀” bí?
Ohun tí Bibeli Wí Gan-an
Àwọn kan lè dáhùn ìbéèrè yẹn nípa fífa ọ̀rọ̀ ẹsẹ tí ó bẹ̀rẹ̀ Ìhìnrere Johannu yọ pé: “Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọrun, Ọlọrun sì ni Ọ̀rọ̀ náà.” (Johannu 1:1) Ìyẹn kò ha tako ohun tí bíṣọ́ọ̀bù Anglica náà sọ bí? Kìí ṣe bẹ́ẹ̀ níti gidi. Gẹ́gẹ́ bí John Robinson ti mọ̀ láìṣiyèméjì, àwọn atúmọ̀ òde-òní kan kò fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú bí King James Version ṣe tumọ̀ ọ̀rọ̀ ẹsẹ-ìwé yẹn. Èéṣe? Nítorí pé nínú ọ̀rọ̀ náà “Ọlọrun . . . ni Ọ̀rọ̀ náà” ní èdè Griki ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ náà fún “Ọlọrun” kò ní ọ̀rọ̀ atọ́ka pàtó náà “náà.” Nínú gbólóhùn-ọ̀rọ̀ ti ìṣáájú “Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọrun,” ọ̀rọ̀ náà fún “Ọlọrun” ṣe pàtó, ìyẹn ni pé, ó ní ọ̀rọ̀ atọ́ka pàtó. Èyí mú kí ó jẹ́ ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeéṣe pé àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì ní ìjẹ́pàtàkì kan-náà.
Fún ìdí èyí, àwọn ìtumọ̀ kan mú apá-ìhà ànímọ́ náà jáde nínú ìtumọ̀ wọn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan túmọ̀ gbólóhùn-ọ̀rọ̀ náà sí “Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ àtọ̀runwá.” (An American Translation, Schonfield) Moffatt túmọ̀ rẹ̀ sí “Logos [Ọ̀rọ̀] náà jẹ́ àtọ̀runwá.” Bí ó ti wù kí ó rí, ní fífihàn pé “àtọ̀runwá” kì yóò jẹ́ ìtumọ̀ tí ó yẹ jùlọ níhìn-ín, John Robinson àti ọmọ ilẹ̀ Britain náà Sir Frederick Kenyon tí ó jẹ́ olùṣelámèyítọ́ ọ̀rọ̀-ẹsẹ-ìwé náà ṣàlàyé pé tí ìyẹn bá jẹ́ ohun tí Johannu fẹ́ láti tẹnumọ́, òun ìbá ti lo ọ̀rọ̀ Griki náà fún “àtọ̀runwá,” theiʹos. Ìtumọ̀ New World Translation, ní wíwo ọ̀rọ̀ náà “Ọlọrun” lọ́nà títọ́ gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò ṣe pàtó, àti mímú apá-ìhà ànímọ́ tí ìgbékalẹ̀ èdè Griki tọ́ka sí jáde, lo ọ̀rọ̀ aláìtọ́ka pàtó èdè Gẹ̀ẹ́sì, báyìí: “Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọrun kan.”
Ọ̀jọ̀gbọ́n C. H. Dodd, olùdarí ìwéwèé-dáwọ́lé New English Bible, sọ̀rọ̀ lóri ọ̀nà ìgbàṣe yìí pé: “Ìtumọ̀ tí ó ṣeéṣe . . . yóò jẹ́, ‘Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ọlọrun kan’. Gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀-kan fún ọ̀rọ̀-kan kò sí ohun tí ó burú pẹ̀lú rẹ̀.” Bí ó ti wù kí ó rí, The New English Bible kò túmọ̀ ẹsẹ náà ní ọ̀nà yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Johannu 1:1 nínú ẹ̀dà ìtumọ̀ yẹn kà pé: “Nígbà tí gbogbo nǹkan bẹ̀rẹ̀, Ọ̀rọ̀ náà ti wà ṣáájú. Ọ̀rọ̀ náà gbé pẹ̀lú Ọlọrun, ohun tí Ọlọrun sì jẹ́, ni Ọ̀rọ̀ náà jẹ́.” Èéṣe tí ìgbìmọ̀ ìtumọ̀ náà kò fi yan ìṣètumọ̀ tí ó rọrùn jù náà? Ọ̀jọ̀gbọ́n Dodd dáhùn pé: “Ìdí tí kò fi ṣètẹ́wọ́gbà ni pé ó lòdì sí èrò òde-ìwòyí nípa Johannu, àti nítòótọ́ nípa èrò Kristian lódindi.”—Technical Papers for the Bible Translator, Ìdìpọ̀ 28, January 1977.
Ìtumọ̀ Aláìlábùlà ti Ìwé Mímọ́
Àwa yóò ha sọ pé èrò náà pé Jesu jẹ́ ọlọrun kan àti pé kò bá Ọlọrun Ẹlẹ́dàá dọ́gba yóò ha lòdì sí èrò Johannu (ìyẹn ni, aposteli Johannu), àti pẹ̀lú èrò ti Kristian lódindi bí? Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀-ẹsẹ-ìwé Bibeli díẹ̀ tí ó tọ́ka sí Jesu àti sí Ọlọrun, àwa yóò sì rí ohun tí àwọn alálàyé kan tí wọ́n ti gbé ṣáájú kí á tó hùmọ̀ Ìjẹ́wọ́-Ìgbàgbọ́ Athanasius ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀-ẹsẹ-ìwé wọ̀nnì.
“Ọ̀kan ni èmi àti Bàbá mi jásí.”—Johannu 10:30.
Novatian (nǹkan bíi 200 sí 258 C.E.) sọ pé: “Níwọ̀n ìgbà tí Ó ti sọ pé ohun ‘kan,’[b] jẹ́ kí ó yé àwọn aládàámọ̀ pé Òun kò sọ pé ẹni ‘kan.’ Nítorí ọ̀kan tí a fi sí ipò kòṣakọ-kòṣabo, dọ́gbọ́n túmọ̀sí ìfohùnṣọ̀kan alájọṣepọ̀, kìí ṣe ìṣọ̀kan ti ara-ẹni. . . . Jù bẹ́ẹ̀ lọ, pé Òun sọ pé ọ̀kan, ní ìtọ́ka sí ìfohùnṣọ̀kan, àti sí ìṣọ̀kan ìdájọ́, àti sí ìbákẹ́gbẹ́ onífẹ̀ẹ́ fúnraarẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti bọ́gbọ́nmu pé Bàbá àti Ọmọkùnrin wà ní ìfohùnṣọ̀kan, nínú ìfẹ́, àti nínú ìfẹ́ni.”—Treatise Concerning the Trinity, orí 27.
“Bàbá mi tóbi jù mí lọ.”—Johannu 14:28.
Irenaeus (nǹkan bíi 130 sí 200 C.E.): “A lè kẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ Rẹ̀ [Kristi] pé Bàbá ga ju ohun gbogbo lọ. Nítorí pé ‘Bàbá,’ ni Òun [Kristi] sọ, ‘tóbi jù mí lọ.’ Nítorí náà, Bàbá, ni Oluwa wa ti polongo pé ó tayọ níti ìmọ̀.”—Against Heresies, Ìwe Keji, orí 28.8.
“Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ̀ ọ́, ìwọ nìkan Ọlọrun òtítọ́, àti Jesu Kristi, ẹni tí ìwọ rán.”—Johannu 17:3.
Clement ará Alexandria (nǹkan bíi 150 sí 215 C.E.): “Láti mọ Ọlọrun ayérayé, olùfúnni ní ohun tí ó jẹ́ ayérayé, àti nípa ìmọ̀ àti ìlóye láti ní Ọlọrun, ẹni tí ó jẹ́ àkọ́kọ́, tí ó sì ga jùlọ, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan, àti ẹni rere. . . . Ẹni náà tí yóò gbé ìgbésí-ayé òtítọ́ ni a pàṣẹ fún nígbà náà láti mọ̀ Ọ́n ‘ẹni tí kò sí ẹni tí ó mọ̀ ọ́n, àyàfi pé Ọmọkùnrin fi (Í) hàn.’ (Matt. 11:27) Èyí tí ó kàn láti mọ̀ ni ìtóbilọ́lá Olùgbàlà náà lẹ́yìn Rẹ̀.”—Who Is the Rich Man That Shall Be Saved? Ìkeje, Ìkẹjọ.
“Ọlọrun kan àti Bàbá gbogbo, ẹni tí ó wà lórí gbogbo àti nípa gbogbo àti nínú yín gbogbo.”—Efesu 4:6.
Irenaeus: “Àti nípa báyìí Ọlọrun kan Bàbá ni a polongo, ẹni tí ó wà lórí ohun gbogbo, àti la ohun gbogbo já, àti nínú ohun gbogbo. Bàbá ni ó wà lórí ohun gbogbo nítòótọ́, Òun sì ni Orí Kristi.”—Against Heresies, Ìwé Karùn-ún, orí 18.2.
Àwọn ònkọ̀wé ìjímìjí wọ̀nyí lóye àwọn ẹsẹ wọ̀nyí ní kedere pé ó ṣàpèjúwe Bàbá gẹ́gẹ́ bí onípò-àjùlọ, tí ó wà lórí ohun gbogbo àti ẹni gbogbo títí kan Jesu Kristi. Àwọn ọ̀rọ̀ wọn kò tanilólobó pé wọ́n gbàgbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan.
Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣí Gbogbo Òtítọ́ Payá
Jesu ṣèlérí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé lẹ́yìn ikú àti àjíǹde òun, a ó fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ kan. Ó ṣèlérí pé: “Nígbà tí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ nì bá dé, yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo; . . . yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín.”—Johannu 14:16, 17; 15:26; 16:13.
Lẹ́yìn ikú Jesu, ìlérí yẹn ni a múṣẹ. Bibeli ṣàkọsílẹ̀ bí a ṣe ṣí àwọn ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ titun payá tàbí mú un ṣe kedere síi fún ìjọ Kristian nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́. Àwọn ẹ̀kọ́ titun wọ̀nyí ni a kọsílẹ̀ nínú àwọn ìwé tí ó wá di apá kejì Bibeli, Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki, tàbí “Májẹ̀mú Titun.” Nínú ìlàlóye titun púpọ̀ jaburata yìí, ìṣípayá èyíkéyìí nípa wíwà Mẹ́talọ́kan kan ha wà láé bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Ẹ̀mí mímọ́ ṣí ohun kan tí ó yàtọ̀ gan-an payá nípa Ọlọrun àti Jesu.
Fún àpẹẹrẹ, ní Pentekosti 33 C.E., lẹ́yìn ìgbà tí ẹ̀mí mímọ́ sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí wọ́n kórajọ ní Jerusalemu, aposteli Peteru jẹ́rìí fún àwọn ogunlọ́gọ̀ tí wọ́n wà lẹ́yìn-òde nípa Jesu. Òun ha sọ̀rọ̀ nípa Mẹ́talọ́kan bí? Gbé díẹ̀ lára àwọn gbólóhùn rẹ̀ yẹ̀wò, kí o sì ṣèdájọ́ fúnraàrẹ: “Jesu . . . , ọkùnrin tí a fihàn fún yín [láti] ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, nípa iṣẹ́ agbára àti ti ìyanu, àti ti àmì tí Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàárín yín.” “Jesu náà yìí ni Ọlọrun ti jí dìde, ẹlẹ́rìí èyí tí gbogbo wa í ṣe.” “Ọlọrun ti fi Jesu náà, tí ẹ̀yín kàn mọ́ [igi, NW], jẹ Oluwa àti Kristi.” (Iṣe 2:22, 32, 36) Yàtọ̀ gédégédé sí kíkọ́ni ní Mẹ́talọ́kan, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti ẹnu Peteru tí ó kún fún ẹ̀mí mímọ́ tẹnumọ́ ipò jíjẹ́ ọmọ-abẹ́ tí Jesu wà sí Bàbá rẹ̀, pé òun jẹ́ ohun-èèlò kan fún ìmúṣẹ ìfẹ́-inú Ọlọrun.
Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, Kristian olùṣòtítọ́ mìíràn sọ̀rọ̀ nípa Jesu. Stefanu Kristian kan tí ó sì jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, ni a mú wá síwájú Àjọ-Ìgbìmọ̀ láti dáhùn àwọn ẹ̀sùn. Dípò bẹ́ẹ̀, Stefanu yí ipò-ọ̀ràn náà pò, ní fífẹ̀sùn kàn pé àwọn olùfẹ̀sùnkanni òun dàbí àwọn bàbáńlá wọn ọlọ̀tẹ̀. Níkẹyìn, àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Òun kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó tẹjúmọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọrun, àti Jesu ń dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Ó sì wí pé, Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, àti Ọmọ-ènìyàn ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.” (Iṣe 7:55, 56) Èéṣe tí ẹ̀mí mímọ́ fi Jesu hàn láti wulẹ̀ jẹ́ “Ọmọ-ènìyàn” tí ń dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun tí kìí sìí ṣe apákan Ọlọrun ẹlẹ́ni mẹ́ta tí ó dọ́gba pẹ̀lú Bàbá rẹ̀? Ní kedere, Stefanu kò mọ ohun tí ń jẹ́ Mẹ́talọ́kan.
Nígbà tí Peteru gbé ìhìnrere nípa Jesu tọ Korneliu lọ, àǹfààní síwájú síi láti ṣí ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan payá wà. Kí ní ó ṣẹlẹ̀? Peteru ṣàlàyé pé Jesu ni “Oluwa ohun gbogbo.” Ṣùgbọ́n ó ń báa lọ láti ṣàlàyé pé ipò jíjẹ́ Oluwa yìí wá láti orísun giga jù kan. Jesu ni “a ti ọwọ́ Ọlọrun yàn ṣe Onídàájọ́ ààyè òun òkú.” Lẹ́yìn àjíǹde Jesu, Bàbá rẹ̀ ‘gbà á láàyè [fún un ní ìyọ̀ọ̀da] láti di híhàn gbangba’ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ẹ̀mí mímọ́ sì ńkọ́? Ó farahàn nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ yìí ṣùgbọ́n kìí ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹnìkẹta nínú Mẹ́talọ́kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ‘Ọlọrun fi ẹ̀mi mímọ́ àti agbára yan Jesu.’ Nípa báyìí, ẹ̀mí mímọ́, yàtọ̀ gédégédé sí jíjẹ́ ẹnìkan, ni a fihàn láti jẹ́ ohun kan tí kìí ṣe ènìyàn, bí “agbára” tí a tún mẹ́nukàn nínú ẹsẹ yẹn. (Iṣe 10:36, 38, 40, 42) Ṣàyẹ̀wò Bibeli dáradára, ìwọ yóò sì rí ẹ̀rí síwájú síi pé ẹ̀mí mímọ́ kìí ṣe ẹnìkan bíkòṣe ipá agbékánkánṣiṣẹ́ tí ènìyàn lè kún fún, sún ènìyàn ṣiṣẹ́, mú kí wọ́n tànyòò, kí ó sì di èyí tí a tú sí wọn lórí.
Níkẹyìn, aposteli Paulu ní àǹfààní rere láti ṣàlàyé Mẹ́talọ́kan—bí ó bá ti jẹ́ ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ tòótọ́—nígbà tí ó ń wàásù fún àwọn ará Ateni. Nínú ọ̀rọ̀-àsọyé rẹ̀, ó tọ́ka sí pẹpẹ wọn “FÚN ỌLỌRUN ÀÌMỌ̀” ó sì sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹni tí ẹ̀yín ń sìn ní àìmọ̀ òun náà ni èmi ń sọ fún yín.” Òun ha kéde Mẹ́talọ́kan bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Ó ṣàpèjúwe “Ọlọrun náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tíí ṣe Oluwa ọ̀run òun ayé.” Ṣùgbọ́n Jesu ńkọ́? “[Ọlọrun] ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo, nípasẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn.” (Iṣe 17:23, 24, 31) Kò sí olobó kan nípa Mẹ́talọ́kan níbẹ̀!
Níti tòótọ́ Paulu ṣàlàyé ohun kan nípa ète Ọlọrun tí ó mú kí ó má ṣeéṣe pé kí Jesu àti Bàbá rẹ̀ jẹ́ apá ọgbọọgba ti Mẹ́talọ́kan. Ó kọ̀wé pé: “[Ọlọrun] ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ [Jesu]. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wí pé ohun gbogbo ni a fi sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó dájú pé, òun nìkanṣoṣo ni ó kù, tí ó fi ohun gbogbo sí i lábẹ́. Nígbà tí a bá sì fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni a ó fi Ọmọ tìkáraarẹ̀ pẹ̀lú sábẹ́ ẹni tí ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọrun kí ó lè jásí ohun gbogbo ní ohun gbogbo.” (1 Korinti 15:27, 28) Nípa báyìí, Ọlọrun yóò wà lórí ohun gbogbo síbẹ̀, títí kan Jesu.
Nígbà náà, a ha fi Mẹ́talọ́kan kọ́ni nínú Bibeli bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. John Robinson tọ̀nà. Kò sí nínú Bibeli, bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe apákan “èrò Kristian.” Ìwọ ha ka èyí sí pàtàkì fún ìjọsìn rẹ̀ bí? O níláti ṣe bẹ́ẹ̀. Jesu sọ pé: “Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ̀ ọ́, ìwọ nìkan Ọlọrun òtítọ́, àti Jesu Kristi ẹni tí ìwọ rán.” (Johannu 17:3) Bí a bá fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn wa sí Ọlọrun, ó ṣe kókó pé kí a mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí òun tí rí níti gidi, gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣí araarẹ̀ payá fún wa. Kìkì nígbà náà ni a tó lè sọ tòótọ́-tòótọ́ pé a wà lára “olùsìn tòótọ́” tí ń “sin Bàbá ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”—Johannu 4:23.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní ìbámu pẹ̀lu The Catholic Encyclopedia, ìtẹ̀jáde ti 1907, ìdìpọ̀ 2, ojú-ìwé 33.
b Novatian ń tọ́ka sí òtítọ́ náà pé ọ̀rọ̀ náà fún “ọ̀kan” nínú ẹsẹ yìí wà ní ẹ̀yà kòṣakọ-kòṣabo. Fún ìdí èyí, ìtumọ̀ ipilẹṣẹ̀ rẹ̀ ni “ohun kan.” Fiwé Johannu 17:21, níbi tí a ti lo ọ̀rọ̀ Griki fún “ọ̀kan” ní ọ̀nà bíbáramu rẹ́gí. Ó fanilọ́kànmọ́ra pé, New Catholic Encyclopedia (ìtẹ̀jáde 1967) tẹ́wọ́gba De Trinitate tí Novatian, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fihàn pé nínú rẹ̀ “Ẹ̀mí Mímọ́ ni a kò kà sí Ẹni àtọ̀runwá kan.”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]
Ìtumọ̀ ṣíṣe kedere ti Ìwé Mímọ́ fihàn ní kedere pé Jesu àti Bàbá rẹ̀ kìí ṣe Ọlọrun kan
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
Èèṣe tí ẹ̀mí mímọ́ kò fi ṣípayá pé Jesu ni Ọlọrun lẹ́yìn Pentekosti 33 C.E.?