Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
November 15, 2013
© 2013 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
DECEMBER 30, 2013–JANUARY 5, 2014
‘Ẹ Wà Lójúfò Kí Ẹ Lè Máa Gbàdúrà’
JANUARY 6-12, 2014
Báwo La Ṣe Lè Máa Ní “Ẹ̀mí Ìdúródeni”?
JANUARY 13-19, 2014
Olùṣọ́ Àgùntàn Méje àti Mọ́gàjí Mẹ́jọ Ti Òde Òní
JANUARY 20-26, 2014
Ṣègbọràn sí Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Tí Jèhófà Yàn
JANUARY 27, 2014–FEBRUARY 2, 2014
Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá Náà
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ ‘Ẹ Wà Lójúfò Kí Ẹ Lè Máa Gbàdúrà’
Bí òpin ètò Sátánì yìí ti ń sún mọ́lé, ó ṣe pàtàkì pé ká máa jọ́sìn Ọlọ́run, ká má ṣe sùn lọ nípa tẹ̀mí. Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé bí wíwà lójúfò ká lè máa gbàdúrà kò ṣe ní jẹ́ ká sùn lọ nípa tẹ̀mí.
▪ Báwo La Ṣe Lè Máa Ní “Ẹ̀mí Ìdúródeni”?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, wo ohun tá a lè rí kọ́ látinú sùúrù wòlíì Míkà. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò tá a fi ń dúró pé kí Jèhófà pa ètò nǹkan búburú yìí run ti parí. Tún kíyè sí bá a ṣe lè máa fi hàn pé a mọrírì sùúrù Ọlọ́run.
▪ Olùṣọ́ Àgùntàn Méje àti Mọ́gàjí Mẹ́jọ Ti Òde Òní
Àwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò fún wa lóde òní wà nínú ìtàn nípa bí Senakéríbù ṣe gbógun ti Jerúsálẹ́mù nígbà ayé Hesekáyà. Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí ṣe pàtàkì gan-an fún àwọn tó ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ.
▪ Ṣègbọràn sí Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Tí Jèhófà Yàn
▪ Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá Náà
Èyí àkọ́kọ́ lára àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí dá lórí bí Jèhófà àti Jésù ṣe ń ṣe olùṣọ́ àwọn àgùntàn wọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé àti bó ṣe yẹ kí àwọn àgùntàn náà tẹ́wọ́ gba ìtọ́jú tí wọ́n ń pèsè. Àpilẹ̀kọ kejì ṣàlàyé irú èrò tó yẹ kí àwọn alàgbà sapá láti ní bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ Ọlọ́run.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
8 Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Èèyàn
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ìjẹ́rìí òpópónà ní ibùdókọ̀ ojú irin kan ní ìlú Tokyo. Àwọn èèyàn tó ń rìnrìn àjò lọ sí ìlú Tokyo lójoojúmọ́ lé ní mílíọ̀nù méjì àti ogójì ọ̀kẹ́ [2,800,000]. Àwọn ará wa ń sapá láti wàásù fún àwọn tí kò sí nílé nígbà tí wọ́n ń wàásù láti ilé dé ilé
JAPAN
IYE ÈÈYÀN:
126,536,000
IYE AKÉDE:
216,692
AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ DÉÉDÉÉ:
65,245