ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 12/1 ojú ìwé 14-15
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Rántí​—Jésù Kristi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Rántí​—Jésù Kristi?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Èyí Ni Ọmọ Mi”
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Wọ́n Bí Jésù Sí Ibùso Ẹran
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ó Dé ‘Ìparí Èrò Nínú Ọkàn Rẹ̀’
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Àwọn Áńgẹ́lì Kéde Pé Wọ́n Ti Bí Jésù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 12/1 ojú ìwé 14-15
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

KỌ́ ỌMỌ RẸ

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Rántí—Jésù Kristi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ní gbogbo oṣù December, kárí ayé ni àwọn èèyàn máa ń rí àwòrán Jésù tí wọ́n yà bí ọmọ jòjòló tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran, ìyẹn àpótí kan tí wọ́n máa ń kó oúnjẹ àwọn ẹran sí. Àmọ́ ṣé ọmọ jòjòló ṣì ni Jésù?—a Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tó dára jù láti máa rántí Jésù. Lóru ọjọ́ kan, ohun kan ṣẹlẹ̀ sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà ní pápá nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Jẹ́ ká wo ohun tí a lè rí kọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ó ṣẹlẹ̀ pé áńgẹ́lì kan ṣàdédé yọ si àwọn olùṣọ́ àgùntàn yẹn. Ó sọ fún wọn pé: “A bí Olùgbàlà kan fún yín lónìí, ẹni tí í ṣe Kristi Olúwa.” Ó ṣàlàyé fún wọn pé wọ́n máa rí Jésù “tí a fi àwọn ọ̀já wé, ó sì wà ní ìdùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì fara hàn, wọ́n sì ń “yin Ọlọ́run.”

Ǹjẹ́ inú rẹ ò ní dùn tó o bá gbọ́ bí àwọn áńgẹ́lì ṣe ń yin Ọlọ́run?— Inú àwọn olùṣọ́ àgùntàn yẹn dùn gan an ni! Wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a rí i dájú pé a lọ ní tààràtà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, kí a sì rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yìí.” Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n “rí Màríà àti Jósẹ́fù, àti ọmọdé jòjòló tí ó wà ní ìdùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.”

Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn wá sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù níbi tí Màríà àti Jósẹ́fù wà. Nígbà tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹnu ya gbogbo wọn. Ǹjẹ́ inú rẹ dùn láti mọ àwọn ohun rere yìí nípa Jésù?— Inú gbogbo àwa tá a fẹ́ràn Ọlọ́run dùn láti mọ̀ ọ́n. Ó yá, jẹ́ ká wo ìdí tí inú àwọn èèyàn fi dùn tó bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bí Jésù. Ká tó lè mọ̀ ọ́n, a ní láti kọ́kọ́ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ kí Màríà tó ṣègbéyàwó.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Lọ́jọ́ kan, áńgẹ́lì kan tó ń jẹ́ Gébúrẹ́lì wá sọ́dọ̀ Màríà. Ó ṣèlérí fún Màríà pé ó máa bí ọmọ kan, tí “yóò jẹ́ ẹni ńlá, a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ . . . yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba . . . , kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.”

Màríà fẹ́ mọ bí ohun tí áńgẹ́lì yẹn sọ ṣe máa ṣẹlẹ̀, torí pé kò tíì bá ọkùnrin kankan sùn rí. Gébúrẹ́lì wá ṣàlàyé fún un pé: “Agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́” àti pé, “ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.” Iṣẹ́ ìyanu ńlá ni Ọlọ́run ṣe nígbà tó fi ìwàláàyè Jésù sínú ikùn Màríà láti ọ̀run, kó lè bíi sáyé bí ọmọ jòjòló!

Ǹjẹ́ o ti rí àwọn àwòrán tàbí àwọn eré kan nípa ìgbà tí wọ́n bí Jésù, tí àwọn “amòye mẹ́ta” àti àwọn olùṣọ́ àgùntàn lọ kí Jésù nígbà tó ṣì wà lọ́mọ jòjòló?— Irú àwọn àwòrán àti àwọn eré bẹ́ẹ̀ máa ń wọ́pọ̀ lásìkò Kérésì. Àmọ́ àwọn ìtàn yẹn kì í ṣe òtítọ́. Awòràwọ̀ ni wọ́n, ìyẹn àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run kórìíra. Jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí wọ́n sì wọ ilé náà, wọ́n rí ọmọ kékeré náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀.” Torí náà, Jésù kì í ṣe ọmọ jòjòló tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran mọ́, ó ti di ọmọ kékeré tó ń gbé nínú ilé pẹ̀lú Jósẹ́fù àti Màríà.

Báwo ni àwọn awòràwọ̀ yẹn ṣe mọ ibi tí Jésù wà?— “Ìràwọ̀” kan ló ṣamọ̀nà wọn. Dípò kó darí wọn gba Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ọ̀dọ̀ Hẹ́rọ́dù Ọba ní Jerúsálẹ́mù ni ìràwọ̀ náà kọ́kọ́ darí wọn lọ. Bíbélì sọ pé Hẹ́rọ́dù fẹ́ mọ ibi tí Jésù wa, kó lè pa á. Ronú nípa èyí ná. Ta lo rò pé ó rán ohun tó dà bíi “ìràwọ̀” yẹn láti darí àwọn awòràwọ̀ náà lọ sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù?— Sátánì Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ ló rán ìràwọ̀ yẹn!

Lónìí, Sátánì ń fẹ́ kí àwọn èèyàn máa wo Jésù bíi ọmọ jòjòló tí kò mọ nǹkan kan rárá. Àmọ́, áńgẹ́lì náà Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà pé: “Yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba . . . , kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” Ní báyìí, Jésù ti ń ṣàkóso bíi Ọba ní ọ̀run, láìpẹ́ ó máa pa gbogbo àwọn ọ̀tá Ọlọ́run run pátápátá. Ohun tó yẹ ká máa rántí nípa Jésù nìyẹn, ó sì yẹ kí a sọ ọ́ fún àwọn èèyàn.

Kà á nínú Bíbélì rẹ

  • Lúùkù 1:26-35; 2:8-18

  • Mátíù 2:7-12; 1 Pétérù 5:8

  • Ìṣípayá 19:19-21; 1 Jòhánù 2:17

a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́