Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
February 15, 2014
© 2014 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
APRIL 7-13, 2014
APRIL 14-20, 2014
Ẹ Yọ̀ Nítorí Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn!
OJÚ ÌWÉ 8 • ORIN: 109, 100
APRIL 21-27, 2014
APRIL 28, 2014–MAY 4, 2014
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Ẹ Yin Kristi, Ọba Ògo!
▪ Ẹ Yọ̀ Nítorí Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn!
Mèsáyà Ọba náà, Jésù Kristi sán idà rẹ̀ mọ́dìí, ó sì ń gẹṣin lọ kó lè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. Lẹ́yìn tó ti pa gbogbo wọn run pátápátá, ó gbé arẹwà kan níyàwó, àwọn wúńdíá tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ arẹwà náà sì tẹ̀ lé e. Ìwé Sáàmù 45 ló ṣàlàyé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá yìí. Yẹ̀ ẹ́ wò, kó o lè rí ọ̀nà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà gbà kàn ẹ́.
▪ Jèhófà—Olùpèsè àti Aláàbò Wa
▪ Jèhófà—Ọ̀rẹ́ Wa Tímọ́tímọ́
Kí ló lè jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì Jèhófà tó jẹ́ Baba wa ọ̀run? Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà tó jẹ́ Olùpèsè, Aláàbò wa àti Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́. Wọ́n tún máa sún wa láti ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bọlá fún un.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
13 Ọlọ́run San Opó Sáréfátì Lẹ́san Torí Ìgbàgbọ́ Rẹ̀
ÀWÒRÁN ÌWÁJÚ ÌWÉ: Gbàgede (Michaelerplatz) térò ti ń lọ ti ń bọ̀ ní ìlú Vienna yìí jẹ́ ibi tó dára téèyàn ti lè máa wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Arábìnrin wa kan rèé tó ń fi èdè Chinese wàásù tó sì ń fún ẹnì kan ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
AUSTRIA
IYE AKÉDE
20,923
AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ
2,201
ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
10,987
Èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ni wọ́n fi ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní ìlú Vienna