Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
March 15, 2014
© 2014 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
MAY 5-11, 2014
Máa Fi Hàn Pé O Ní Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ
MAY 12-18, 2014
Bó O Ṣe Lè Máa Fi Ojú Tó Tọ́ Wo Nǹkan
MAY 19-25, 2014
Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Yín
MAY 26, 2014–JUNE 1, 2014
Bá A Ṣe Lè Máa Tọ́jú Àwọn Àgbàlagbà
OJÚ ÌWÉ 25 • ORIN: 134, 29
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Máa Fi Hàn Pé O Ní Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ
Ọ̀tá ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ kan wà tó máa ń mú kó ṣòro fún wa láti máa fi hàn pé a ní irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí Jésù ní. Àpilẹ̀kọ yìí máa sọ ọ̀tá náà, ó sì máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè lo Bíbélì láti kojú rẹ̀.
▪ Bó O Ṣe Lè Máa Fi Ojú Tó Tọ́ Wo Nǹkan
Tá a bá ń fi ojú tó tọ́ wo nǹkan, àá lè máa bá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà nìṣó láìbọ́hùn. Kí nìdí tí èrò òdì fi máa ń wá sọ́kàn àwọn kan ṣáá? Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí bá a ṣe lè lo Bíbélì ká lè máa fi ojú tó tọ́ wo ara wa.
▪ Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Yín
▪ Bá A Ṣe Lè Máa Tọ́jú Àwọn Àgbàlagbà
Nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí, a jíròrò ojúṣe Kristẹni kọ̀ọ̀kan àti ojúṣe ìjọ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bójú tó àwọn ará àti àwọn ìbátan tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà. A tún máa jíròrò àwọn àbá mélòó kan tó ṣeé mú lò tó máa jẹ́ ká lè kẹ́sẹ járí.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Bá A Ṣe Lè Mú Kí Àwọn Ìbátan Wa Tí Kì í Ṣe Ẹlẹ́rìí Nífẹ̀ẹ́ Òtítọ́
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ní Ọsirélíà máa ń rin ìrìn tó jìn kí wọ́n lè mú ìhìn rere dé àrọko lọ́dọ̀ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọgbà tí wọ́n ti ń sin màlúù tí wọ́n sì tún ń gbé níbẹ̀
ỌSIRÉLÍÀ
IYE ÈÈYÀN
23,192,500
IYE AKÉDE
66,967