Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
April 15, 2014
© 2014 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
JUNE 2-8, 2014
JUNE 9-15, 2014
Ǹjẹ́ Ò Ń Rí “Ẹni Tí A Kò Lè Rí”?
JUNE 16-22, 2014
JUNE 23-29, 2014
Jẹ́ Onígboyà —Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Rẹ!
JUNE 30, 2014–JULY 6, 2014
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Mósè
▪ Ǹjẹ́ Ò Ń Rí “Ẹni Tí A Kò Lè Rí”?
Ìgbàgbọ́ tí Mósè ní mú kó máa rí ohun tó kọjá èyí tó lè fi ojú lásán rí. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè lo ìgbàgbọ́ bíi ti Mósè ká sì máa bá a lọ ní “fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.”—Héb. 11:27.
▪ Kò Sí Ẹni Tó Lè Sin Ọ̀gá Méjì
▪ Jẹ́ Onígboyà—Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Rẹ!
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé ti yàn láti fi ìlú ìbílẹ̀ wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè wá iṣẹ́ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì fi ìyàwó àtàwọn ọmọ sílẹ̀ nílé. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fẹ́ ká máa fi wo ojúṣe wa nínú ìdílé, ó sì tún máa jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe náà.
▪ Ǹjẹ́ O Mọyì Bí Jèhófà Ṣe Ń Fìfẹ́ Ṣọ́ Wa?
Nígbà tá a bá kà á nínú Bíbélì pé “ojú Jèhófà ń bẹ ní ibi gbogbo,” àwọn kan lára wa lè máa rò pé ohun tó jẹ Ọlọ́run lógún ni bó ṣe máa rí sí i pé à ń pa àwọn òfin òun mọ́. Ìyẹn sì lè mú ká máa ní ìbẹ̀rù tí kò tọ́. (Òwe 15:3) Àmọ́, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí ọ̀nà márùn-ún tá a lè gbà jàǹfààní látinú bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ bójú tó wa.
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Ní ìlú Istanbul arákùnrin kan ń wàásù lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà fún ẹni tó máa ń gẹrun fún un, ó ń fún un ní ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
TỌ́KÌ
IYE ÈÈYÀN
75,627,384
IYE AKÉDE
2,312
ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
1,632
ÌPÍNDỌ́GBA
Akéde 1 máa wàásù fún èèyàn 32,711
Láti ọdún 2004 iye tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé tó wà ní orílẹ̀-èdè Tọ́kì fi pọ̀ sí i jẹ́ 165%