Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
June 15, 2014
© 2014 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
AUGUST 4-10, 2014
AUGUST 11-17, 2014
“Nífẹ̀ẹ́ Aládùúgbò Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ara Rẹ”
AUGUST 18-24, 2014
Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Àìlera Ẹ̀dá Ni Ìwọ Náà Fi Ń Wò Ó?
AUGUST 25-31, 2014
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ “Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run Rẹ”
▪ “Nífẹ̀ẹ́ Aládùúgbò Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ara Rẹ”
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí jíròrò òfin méjì tí Jésù Kristi sọ pé ó tóbi jù lọ nínú àwọn Òfin. A máa kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, ọkàn wa àti èrò inú wa. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa.
▪ Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Àìlera Ẹ̀dá Ni Ìwọ Náà Fi Ń Wò Ó?
▪ Ran Àwọn Mìíràn Lọ́wọ́ Láti Lo Ẹ̀bùn Wọn ní Kíkún
Báwo la ṣe lè ran àwọn tó ń ronú pé àwọn jẹ́ aláìlera lọ́wọ́? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà lára ohun tá a jíròrò nínú àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí. Àwọn àpilẹ̀kọ náà tún ṣàlàyé bá a ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ tàbí àwọn arákùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi lọ́wọ́ kí wọ́n lè lo ẹ̀bùn wọn ní kíkún.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 “Mú Ipa Ọ̀nà Ẹsẹ̀ Rẹ Jọ̀lọ̀” Kó O Lè Tẹ̀ Síwájú
7 Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
8 Báwo La Ṣe Lè Ran Àwọn Kristẹni Tí Ọkọ Tàbí Ìyàwó Wọn Kọ̀ Sílẹ̀ Lọ́wọ́?
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Àwọn ará ń wàásù ìhìn rere fún àwọn apẹja tí wọ́n ń sọ èdè Mbukushu, tí wọ́n ń gbé létí Odò Okavango tó wà ní orílẹ̀-èdè Botswana
BOTSWANA
IYE ÈÈYÀN
2,021,000
IYE AKÉDE
2,096
IYE ÌJỌ
47
ÀWỌN TÓ WÁ SÍBI ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI NÍ ỌDÚN 2013
5,735