OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà?
Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ ká máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún un ní fàlàlà àti nígbà gbogbo. (Lúùkù 18:1-7) Ó máa ń gbọ́ àdúrà wa nítorí ó nífẹ̀ẹ́ wa. Nígbà tó jẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ní ká máa bá òun sọ̀rọ̀, kí wá ló dé tá ò fi ní gbàdúrà sí i?—Ka Fílípì 4:6.
Kì í ṣe pé a fẹ́ béèrè fún ìrànlọ́wọ́ nìkan la ṣe ń gbàdúrà sí i, àmọ́, àdúrà máa ń jẹ́ ká sún mọ́ Ọlọ́run. (Sáàmù 8:3, 4) Tá a bá ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún Ọlọ́run nígbà gbogbo, ìyẹn á mú ká túbọ̀ di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.—Ka Jákọ́bù 4:8.
Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà?
Tá a bá ń gbàdúrà, Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa fọ̀rọ̀ dárà tàbí ká máa gba àdúrà àkọ́sórí. Kò sì pọn dandan pé a gbọ́dọ̀ jókòó tàbí ká tẹrí ba, ká kúnlẹ̀ tàbí ká dúró ká tó lè gbàdúrà sí Ọlọ́run. Jèhófà ń fẹ́ ká sọ ohun tó wà lọ́kàn wa. (Mátíù 6:7) Bí àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, Hánà gbàdúrà sí Jèhófà nípa ìṣòro tó ń bá a fínra nínú ìdílé rẹ̀. Kò pẹ́ tí ìbànújẹ́ rẹ̀ fi dayọ̀ tó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run látọkànwá nínú àdúrà rẹ̀.—Ka 1 Sámúẹ́lì 1:10, 12, 13, 26, 27; 2:1.
Ẹ ò rí i pé, àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ la ní láti sọ ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wa fún Ẹlẹ́dàá! A tún lè yìn ín, bẹ́ẹ̀ ni a lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àwọn ohun tó ti ṣe fún wa. Ó dájú pé àwa gan-an mọyì irú àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀.—Ka Sáàmù 145:14-16.