ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 8/15 ojú ìwé 31-32
  • Àwòkẹ́kọ̀ọ́ “Eureka” Mú Kí Ọ̀pọ̀ Rí Ẹ̀kọ́ Òtítọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwòkẹ́kọ̀ọ́ “Eureka” Mú Kí Ọ̀pọ̀ Rí Ẹ̀kọ́ Òtítọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • WỌ́N MÚ KÍ ÒTÍTỌ́ JINLẸ̀ LỌ́KÀN ÀWỌN ÈÈYÀN
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 8/15 ojú ìwé 31-32

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

Àwòkẹ́kọ̀ọ́ “Eureka” Mú Kí Ọ̀pọ̀ Rí Ẹ̀kọ́ Òtítọ́

“EUREKA!” túmọ̀ sí “Mo rí i!” Ní nǹkan bí igba [200] ọdún sẹ́yìn ní ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èèyàn lè gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́nu awakùsà kan nígbà tó bá kan góòlù nínú ilẹ̀. Àmọ́, Arákùnrin Charles Taze Russell àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti rí ohun kan tó ṣeyebíye ju góòlù lọ, ohun náà ni ẹ̀kọ́ òtítọ́. Wọ́n sì fẹ́ láti sọ nípa rẹ̀ fún àwọn èèyàn.

Nígbà tó fi máa di ìgbà ẹ̀rùn ọdún 1914, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn láti àwọn ìlú ńláńlá ló ń rọ́ wá wo sinimá “Photo-Drama of Creation,” ìyẹn àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá. Àwọn International Bible Students Association (I.B.S.A.) ló gbé sinimá oníwákàtí mẹ́jọ tó ń fi fọ́tò ṣàlàyé ìtàn ìṣẹ̀dá jáde. Sinimá tó wọni lọ́kàn náà gbé ohùn jáde, àwọn fọ́tò aláwọ̀ mèremère rẹ̀ ṣe ketekete, àlàyé asọ̀tàn kún rẹ́rẹ́, àwọn orin tó sì wà nínú rẹ̀ bá a mu gan-an ni. Sinimá tó dá lórí Bíbélì yìí sọ ìtàn láti ìgbà ìṣẹ̀dá èèyàn títí lọ dé òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù Kristi.—Ìṣí. 20:4.a

Àmọ́, báwo ni sinimá yìí ṣe máa dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń gbé ní àwọn ìlú kéékèèké àti àwọn abúlé? Torí kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí lè dé ọ̀dọ̀ àwọn tí òǹgbẹ òtítọ́ ń gbẹ, àjọ I.B.S.A. gbé àwòkẹ́kọ̀ọ́ kan tí kò gùn tó “Photo-Drama” jáde ní August 1914, wọ́n pè é ní “Eureka Drama,” wọ́n yọ apá tó jẹ́ sinimá kúrò nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí. Oríṣi mẹ́ta ni àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì wà làwọn èdè mélòó kan. Ọ̀kan ni “Eureka X,” gbogbo àlàyé asọ̀tàn àti orin ló wà nínú rẹ̀. Èkejì ni “Eureka Y,” gbogbo ohùn tá a gbà sílẹ̀ àti àwọn fọ́tò aláwọ̀ mèremère ló wà nínú rẹ̀. Ẹ̀kẹta ni “Eureka Family Drama,” tá a dìídì ṣe fún àwọn ìdílé, ó ní àṣàyàn àlàyé asọ̀tàn àti ohùn orin. A tún máa ń ta giramafóònù àti ohun èlò tí wọ́n fi ń wo sinimá lówó pọ́ọ́kú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ohun èlò tí wọ́n fi ń gbé àwòrán aláwọ̀ mèremère jáde ni wọ́n fi wo sinimá náà

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò nílò kí wọ́n gbé ohun èlò tá a fi ń wo sinimá dání tàbí ẹ̀rọ agbáwòrányọ fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kí wọ́n tó lè fi àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí han àwọn èèyàn. Èyí jẹ́ kí wọ́n lè gbé àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fi ń han àwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́ yìí lọ sáwọn ìgbèríko, kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Ìjọba náà lè dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tí kò gbọ́ nípa rẹ̀ rí. Ìgbàkigbà ni èèyàn lè tẹ́tí sí “Eureka X” tó jẹ́ ohùn nìkan. Tí wọ́n bá fẹ́ wo “Eureka Y,” wọ́n lè lo ohun èlò tó ń lo kábáàdì láti fi gbé àwòrán jáde láìlo iná mànàmáná. Ìròyìn kan nínú Ilé Ìṣọ́ èdè Finnish sọ pé, “A lè fi àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí han àwọn èèyàn níbikíbi.” Bọ̀rọ̀ sì ṣe rí gan-an nìyẹn!

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó mọ owó ṣọ́ ná yìí máa ń wá àwọn ibi tí wọ́n lè lò lọ́fẹ̀ẹ́, irú bíi kíláàsì, àwọn gbọ̀ngàn ilé ẹjọ́, àwọn ibùdó ọkọ̀ ojú irin, kódà wọ́n ń lo pálọ̀ àwọn tí ilé wọn tóbi dípò tí wọ́n á fi lọ fi owó háyà àwọn gbọ̀ngàn ńlá. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìta gbangba ni wọ́n ti ń fi àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí han àwọn èèyàn, wọ́n máa ń ta aṣọ funfun tó fẹ̀ dáadáa mọ́ ara ògiri abà tí wọ́n ń kó àwọn nǹkan oko sí láti fi gbé àwòrán náà jáde. Arákùnrin Anthony Hambuch sọ pé: “Àwọn àgbẹ̀ máa ń fún wa ní àlàfo kékeré kan lóko wọn níbi táwọn èèyàn ti lè jókòó sórí àwọn igi tó ti wó lulẹ̀, kí wọ́n sì gbádùn àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà.” Àwọn tó ń fi àwòkẹ́kọ̀ọ́ “Eureka” han àwọn èèyàn ní àpótí ńlá kan, wọ́n pè é ní “Drama wagon,” inú àpótí yìí ni wọ́n máa ń kó ohun èlò, ẹrù wọn àtàwọn nǹkan tí wọ́n fi ń pàgọ́ àti èyí tí wọ́n fi ń dáná sí.

Níbòmíì àwọn tó wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà lè máà tó nǹkan, wọ́n sì máa ń pọ̀ gan-an láwọn ibòmíì. Ní abúlé kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn tó ń gbé níbẹ̀ kò ju àádọ́jọ [150] lọ, àmọ́ irínwó [400] èèyàn Ió wá wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ tá a fi han àwọn èèyàn níléèwé kan. Níbòmíì, àwọn kan rin ìrìn kìlómítà mẹ́jọ ní àlọ àti kìlómítà mẹ́jọ ní àbọ̀ kí wọ́n lè wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ní orílẹ̀-èdè Sweden, àwọn aládùúgbò arábìnrin kan tó ń jẹ́ Charlotte Ahlberg kóra jọ sí ilé rẹ̀ kékeré láti gbọ́ àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ti ohùn nìkan, ohun tí wọ́n gbọ́ yìí “wọ wọ́n lọ́kàn gan-an.” Lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, àwọn ẹgbẹ̀rún kan àtààbọ̀ [1,500] ló wá wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà ní ibi àdádó ní ìlú kan tí wọ́n ti ń wa kùsà. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ [Gẹ̀ẹ́sì] sọ pé láwọn iléèwé gíga àtàwọn ilé ìwé girama, “àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n àtàwọn ọmọ iléèwé fẹ́ràn àwọn fọ́tò àti ohùn tó ń jáde nínú giramafóònù wa.” Àwọn èèyàn mọ Àwòkẹ́kọ̀ọ́ “Eureka” bí ẹní mọ owó kódà láwọn gbọ̀ngàn tí wọ́n ti máa ń wo fíìmù.

WỌ́N MÚ KÍ ÒTÍTỌ́ JINLẸ̀ LỌ́KÀN ÀWỌN ÈÈYÀN

Àwùjọ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí ìjọ máa ń rán àwọn ará lọ sáwọn àgbègbè táwọn èèyàn ti gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n lè sọ àsọyé fún wọn kí wọ́n sì fi àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà hàn wọ́n. A ò lè sọ ní pàtó iye gbogbo àwọn tó wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà. Àwọn èèyàn wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà dáadáa. Lọ́dún 1915, nínú àwùjọ mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86] tó ń fi àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà han àwọn èèyàn, àwùjọ mẹ́rìnlá péré ló ń ròyìn déédéé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwùjọ tí kò ròyìn déédéé pọ̀ gan-an, síbẹ̀ ìròyìn òpin ọdún sọ pé ó lé ní mílíọ̀nù kan àwọn èèyàn tó ti wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] ló sì sọ pé àwọn fẹ́ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́.

Ó fẹ́ kọ́kọ́ dà bíi pé kò sẹ́ni tó máa rántí àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà mọ́ nínú ìtàn, àmọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí láti Ọsirélíà dé Argentina, láti South Africa lọ dé Àwọn Erékùṣù Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Íńdíà àti agbègbè Caribbean. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì rí ohun kan tó ṣeyebíye ju góòlù lọ, ìyẹn ẹ̀kọ́ òtítọ́. Èyí ló mú kí wọ́n fi ìtara sọ pé “Eureka!” tó túmọ̀ sí “Mo rí i!”

a Wo “Látinú Àpamọ́ Wa—Sinimá Tó Dá Lórí Ìṣẹ̀dá Ti Pé Ọgọ́rùn-ún Ọdún Báyìí!” nínú Ilé Ìṣọ́, February 15, 2014, ojú ìwé 30 sí 32.

“Bíbélì Máa Dà Bí Ìwé Tuntun Kan Sí Ẹ”

A ṣe sinimá “Photo-Drama of Creation,” ìyẹn àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá àti sinimá tí wọ́n pè ní “Eureka Drama” kó lè mú káwọn èèyàn ní ìgbàgbọ́ nínú Bíbélì, tó jẹ́ orísun tó ga jù lọ tá a ti lè mọ òtítọ́ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ibi tá a ti lè gba ìsọfúnni tó wúlò jù lọ nígbèésí ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wá wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà la fún ní ìwé Scenario of the Photo-Drama of Creation, ìyẹn ìwé tó fi ọ̀rọ̀ àti àwòrán ṣàlàyé àwọn ìtàn Bíbélì. Torí pé, àwọn àwòrán àti àwọn ọ̀rọ̀ àsọyé nípa àwòkẹ́kọ̀ọ́ ló wà nínú ìwé náà, ó mú kí Bíbélì “dà bí ìwé tuntun kan.” A fún ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn ní ìwé Scenario lọ́fẹ̀ẹ́. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan sọ pé ní àfikún sí àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, ó jọ pé ìwé Scenario ni “ìwé tó bá a mu jù lọ láti fi la ojú àwọn èèyàn” sí ẹ̀kọ́ òtítọ́.

Bákan náà, ìwé Scenario di ìwé aláwòrán tí ìdílé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá nífẹ̀ẹ́ sí gan-an. Ọmọdé kan tó ń jẹ́ Alice Hoffmann àti àbúrò rẹ̀ fẹ́ràn ìwé Scenario gan-an. Ó sọ pé: “Inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá ń wo ìwé yìí, ó ń mú wa rántí àwọn àwòrán mèremère tá a wò nínú sinimá náà!”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́