Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
September 15, 2014
© 2014 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
OCTOBER 27, 2014–NOVEMBER 2, 2014
Ǹjẹ́ Ó Dá Ẹ Lójú Pé O Wà Nínú Òtítọ́? Kí Nìdí?
NOVEMBER 3-9, 2014
Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀ Láìka “Ọ̀pọ̀ Ìpọ́njú” Sí
OJÚ ÌWÉ 12 • ORIN: 135, 133
NOVEMBER 10-16, 2014
Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín
NOVEMBER 17-23, 2014
Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun Asán
OJÚ ÌWÉ 23 • ORIN: 111, 109
NOVEMBER 24-30, 2014
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Ǹjẹ́ Ó Dá Ẹ Lójú Pé O Wà Nínú Òtítọ́? Kí Nìdí?
Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò ohun tó mú kí ọ̀pọ̀ gbà pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní òtítọ́. Bákan náà, a máa ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó mú kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé a wà nínú òtítọ́.
▪ Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀ Láìka “Ọ̀pọ̀ Ìpọ́njú” Sí
Ìpọ́njú jẹ́ àmì pé à ń gbé nínú ayé Sátánì. Àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ kan lè wá lọ́nà tó ṣe tààràtà, àwọn míì sì lè wá lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí Sátánì ń lò àti bá a ṣe lè múra sílẹ̀ dè wọ́n.
▪ Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín
Ojúṣe àwọn òbí ni láti tọ́ àwọn ọmọ wọn “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò ọ̀nà mẹ́ta tí wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀, tí wọ́n á fi lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa ń dàábò bo agbo àgùntàn rẹ̀.
▪ Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun Asán
Báwo ni ikú ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í pa èèyàn? Báwo ni ‘ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ṣe máa di asán’? (1 Kọ́r. 15:26) Wo bí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí ṣe jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe lo ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n rẹ̀ àti ní pàtàkì ìfẹ́.
▪ Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún
Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti máa ń ní àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n ń fi àkókò kíkún sìn ín láìka àwọn ìṣòro tó wà nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ní ayé ìsinsìnyí sí. Kí la lè ṣe tá a fi máa rántí “iṣẹ́ ìṣòtítọ́” àti “òpò onífẹ̀ẹ́” wọn?—1 Tẹs. 1:3.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Àwọn arákùnrin méjì ń wàásù fún apẹja kan nílùú Negombo tó wà ní etíkun ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Sri Lanka
SRI LANKA
IYE ÈÈYÀN
20,860,000
IYE AKÉDE
5,600
IYE AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ DÉÉDÉÉ
641