KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÌJỌBA ỌLỌ́RUN—ÀǸFÀÀNÍ WO LÓ MÁA ṢE Ẹ́?
Ìjọba Ọlọ́run—Àǹfààní Tó Máa Ṣe Ẹ́
Ó dájú pé ohun tó o kà nínú àwọn àkòrí méjì àkọ́kọ́ ti jẹ́ kó o mọ ìdí tí Ìjọba Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣé ìwọ náà ń fojú sọ́nà fún àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, àbí ara ń fu ẹ́ pé àwọn ìlérí yẹn lè máà jóòótọ́?
Ọlọ́gbọ́n máa ń ní ìfura lóòótọ́, nítorí kì í ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ ló yẹ ká gbà gbọ́. (Òwe 14:15) Torí náà, tí ìwọ náà bá ń wádìí àwọn ohun tó o gbọ́ dáadáa, ńṣe lò ń fara wé àwọn ará Bèróà ìgbàanì.a Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere nípa Ìjọba náà, wọ́n gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀, àmọ́ wọ́n tún yiri ọ̀rọ̀ náà wò. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé wọ́n fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ “ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.” (Ìṣe 17:11) Lédè míì, ńṣe ni àwọn ará Bèróà fi ìhìn rere tí wọ́n gbọ́ wé ohun tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Nígbẹ̀yìn, ó wá dá wọn lójú pé àtinú Bíbélì ni ìhìn rere tí àwọn gbọ́ ti wá.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rọ̀ ẹ́ pé kí ìwọ náà ṣe bí àwọn ará Bèróà. A ṣe tán láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, o sì tún lè fi àwọn ohun tá a bá kọ́ ẹ nípa Ìjọba Ọlọ́run wé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ní ti gidi.
Ní àfikún sí ohun tó o bá kọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, Bíbélì tún lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì bí:
Ibo gan-an la ti wá?
Kí la wá ṣe láyé?
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà?
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú?
Ṣé ayé yìí máa pa rẹ́ lóòótọ́?
Kí ló lè mú kí ìdílé láyọ̀?
Àmọ́ ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì á jẹ́ kó o “sún mọ́ Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:8) Àti pé, bó o ṣe ń sún mọ́ Ọlọ́run sí i, wàá túbọ̀ mọyì àwọn ohun rere tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún ẹ nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. Ohun tí Jésù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó gbàdúrà sí Baba rẹ̀ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
a Bèróà jẹ́ ìlú kan ni Makedóníà àtijọ́.