ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 11/15 ojú ìwé 8-12
  • Ìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ỌLỌ́RUN NÍ KÁ JẸ́ MÍMỌ́
  • Ẹ MÁA ṢÈGBỌRÀN KẸ́ Ẹ LÈ JẸ́ MÍMỌ́
  • MÁA ṢÈGBỌRÀN DÉLẸ̀DÉLẸ̀ SÍ ÒFIN ỌLỌ́RUN LÓRÍ Ọ̀RÀN Ẹ̀JẸ̀
  • ÌDÍ TÍ JÈHÓFÀ FI RETÍ PÉ KÁ JẸ́ MÍMỌ́
  • Fi Ojú Pàtàkì Wo Ẹ̀bùn Ìwàláàyè Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀mí
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ẹ̀mí Ni Kí Ìwọ Náà Máa Fi Wò Ó
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Fifi Ẹ̀jẹ̀ Gba Ẹmi Là—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 11/15 ojú ìwé 8-12

Ìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́

“Ẹ . . . jẹ́ mímọ́.”—LÉF. 11:45.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí nìdí tí ìwẹ̀nùmọ́ Áárónì àti ti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi yẹ kó ṣe gbogbo àwa èèyàn Jèhófà lóde òní láǹfààní?

  • Ọ̀nà wo la lè gbà máa ṣègbọràn ká lè jẹ́ mímọ́?

  • Ọwọ́ wo ló yẹ ká máa fi mú òfin Jèhófà lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀?

1. Ọ̀nà wo ni ìwé Léfítíkù lè gbà ràn wá lọ́wọ́?

NÍNÚ Bíbélì, inú ìwé Léfítíkù ni ọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́mímọ́ ti fara hàn jù lọ. Torí pé Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwọn tó ń sin òun tọkàntọkàn jẹ́ mímọ́, ó ṣe pàtàkì ká lóye ohun tó wà nínú ìwé Léfítíkù ká sì mọrírì rẹ̀ ká bàa lè jẹ́ mímọ́.

2. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó wà nínú ìwé Léfítíkù?

2 Ìwé Léfítíkù tí Mósè kọ jẹ́ ọ̀kan lára “gbogbo Ìwé Mímọ́” tó ṣàǹfààní fún kíkọ́ni. (2 Tím. 3:16) Ó tó ìgbà mẹ́wàá tí orúkọ náà, Jèhófà fara hàn nínú orí kọ̀ọ̀kan nínú ìwé Léfítíkù. Tá a bá lóye ohun tó wà nínú ìwé Léfítíkù, ó máa jẹ́ ká lè sá fún ohunkóhun tó lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. (Léf. 22:32) Ó yẹ ká jẹ́ kí gbólóhùn náà, “Èmi ni Jèhófà” tí ìwé Léfítíkù lò léraléra máa rán wa létí pé ká máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, a máa gbádùn àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye nínú ìwé Léfítíkù tó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run táá jẹ́ ká lè máa ṣe ìjọsìn mímọ́.

ỌLỌ́RUN NÍ KÁ JẸ́ MÍMỌ́

3, 4. Kí ni wíwẹ̀ tí wọ́n wẹ Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

3 Ka Léfítíkù 8:5, 6. Jèhófà yan Áárónì láti máa sìn nípò àlùfáà àgbà nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ó sì yan àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà fún orílẹ̀-èdè náà. Áárónì ṣàpẹẹrẹ Jésù Kristi, nígbà tí àwọn ọmọkùnrin Áárónì ṣàpẹẹrẹ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. Torí náà, ṣé a wá lè sọ pé wíwẹ̀ tí wọ́n wẹ Áárónì ṣàpẹẹrẹ ìwẹ̀nùmọ́ Jésù? Rárá o, Jésù jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀ kò sì ní “àbààwọ́n,” torí náà kò nílò ìwẹ̀nùmọ́. (Héb. 7:26; 9:14) Àmọ́, ohun tí wíwẹ̀ tí wọ́n wẹ Áárónì mọ́ ṣàpẹẹrẹ ni jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ ẹni mímọ́ àti olódodo. Kí wá ni wíwẹ̀ tí wọ́n wẹ àwọn ọmọkùnrin Áárónì ṣàpẹẹrẹ?

4 Wíwẹ̀ tí wọ́n wẹ àwọn ọmọkùnrin Áárónì mọ́ ṣàpẹẹrẹ ìwẹ̀nùmọ́ àwọn tí a yàn láti jẹ́ àlùfáà lókè ọ̀run. Ṣé ìrìbọmi tí àwọn ẹni àmí òróró ṣe ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ọmọkùnrin Áárónì? Rárá, torí pé ìrìbọmi kì í wẹ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ẹnì kan ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run láìbéèrè ohunkóhun pa dà. A wẹ àwọn ẹni àmì òróró mọ́ “nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà,” èyí sì gba pé kí wọ́n máa fi àwọn ẹ̀kọ́ Kristi sílò nígbèésí ayé wọn, kí wọ́n sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn. (Éfé. 5:25-27) A wá tipa bẹ́ẹ̀ sọ wọ́n di mímọ́, a sì wẹ̀ wọ́n mọ́. “Àwọn àgùntàn mìíràn” ńkọ́?—Jòh. 10:16.

5. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé a fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wẹ àwọn àgùntàn mìíràn mọ́?

5 Kì í ṣe “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó jẹ́ ara “àgùntàn mìíràn” ni àwọn ọmọkùnrin Áárónì ṣàpẹẹrẹ. (Ìṣí. 7:9) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé àwọn tó ti ṣèrìbọmi yìí náà ti di mímọ́ àti pé a ti fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wẹ̀ wọ́n mọ́? Bẹ́ẹ̀ ni! Ìdí sì ni pé nígbà tí àwọn tó ní ìrètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé bá ka ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ẹ̀jẹ̀ Jésù tó ta sílẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó àti bó ṣe lágbára tó láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù, wọ́n máa ń ní ìgbàgbọ́ nínú ohun tí Bíbélì sọ, wọ́n sì ń ṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ . . . tọ̀sán-tòru.” (Ìṣí. 7:13-15) Bí àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn ṣe ń ‘tọ́jú ìwà wọn kó lè dára’ fi hàn pé òótọ́ là ń wẹ̀ wọ́n mọ́. (1 Pét. 2:12) Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó bó ṣe ń kíyè sí àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn tí wọ́n wà ní mímọ́ àti níṣọ̀kan, tí wọ́n ń fetí sí ọ̀rọ̀ Jésù tí í ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn wọn tí wọ́n sì ń fòótọ́ tì í lẹ́yìn!

6. Àyẹ̀wò táá ṣe wá láǹfààní wo ló yẹ ka ṣe nípa ara wa?

6 Àṣẹ tí Jèhófà pa fún àwọn àlùfáà nílẹ̀ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n wà ní mímọ́ nípa tara ń ṣe àwa èèyàn Jèhófà lóde òní láǹfààní. Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sábà máa ń kíyè sí i pé àwọn ibi ìjọsìn wa máa ń mọ́ tónítóní àti pé a máa ń wọṣọ tó mọ́ a sì ń múra dáadáa. Síbẹ̀, bí àwọn àlùfáà ṣe máa ń wà ní mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tó bá ń wá síbi ìjọsìn Jèhófà tí a gbé ga gbọ́dọ̀ “mọ́ ní ọkàn-àyà.” (Ka Sáàmù 24:3, 4; Aísá. 2:2, 3.) A gbọ́dọ̀ máa fi ọkàn àti èrò mímọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú ara mímọ́ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run. Èyí gba pé ká máa ṣe àyẹ̀wò ara wa déédéé, téyìí á sì mú káwọn kan ṣe àwọn ìyípadà tó pọn dandan kí wọ́n lè jẹ́ mímọ́. (2 Kọ́r. 13:5) Bí àpẹẹrẹ, bí ẹni tó ti ṣèrìbọmi bá ń mọ̀ọ́mọ̀ wo àwòrán oníhòòhò, ó yẹ kó bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́?’ Lẹ́yìn náà, ó yẹ kó wá ìrànlọ́wọ́ kó lè jáwọ́ nínú ìwà burúkú náà.—Ják. 5:14.

Ẹ MÁA ṢÈGBỌRÀN KẸ́ Ẹ LÈ JẸ́ MÍMỌ́

7. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ tó bá ohun tó wà nínú Léfítíkù 8:22-24 mu?

7 Nígbà tí wọ́n fi àwọn àlùfáà joyè nílẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ àgbò sí etí ọ̀tún Áárónì Àlùfáà Àgbà àti tàwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Wọ́n sì tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. (Ka Léfítíkù 8:22-24.) Lílò tí wọ́n lo ẹ̀jẹ̀ lọ́nà yìí fi hàn pé àwọn àlùfáà náà máa ṣègbọràn bí wọ́n ṣe ń sa gbogbo ipá wọn láti ṣe ojúṣe wọn. Lọ́nà kan náà, Jésù tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn. Lọ́nà wo? Ó máa ń fetí sí àwọn ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Ó ń fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ìfẹ́ Jèhófà, kò sì fìgbà kan yẹsẹ̀ kúrò lójú ọ̀nà mímọ́.—Jòh. 4:31-34.

8. Kí ni gbogbo àwọn tó ń sin Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣe?

8 Àwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn mìíràn Jésù gbọ́dọ̀ máa rìn ní ọ̀nà ìwàtítọ́ bí Àlùfáà Àgbà wọn ti ṣe. Gbogbo àwọn tó ń sin Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn, kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nípa bẹ́ẹ̀ wọn ò ní máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́. (Éfé. 4:30) Wọ́n gbọ́dọ̀ máa ‘ṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ wọn.’—Héb. 12:13.

9. Kí ni àwọn arákùnrin mẹ́ta kan tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ? Báwo ni ohun tí wọ́n sọ ṣe lè jẹ́ kó o máa jẹ́ mímọ́ nìṣó?

9 Ronú nípa ọ̀rọ̀ àtọkànwá tí àwọn arákùnrin mẹ́ta kan sọ. Àwọn arákùnrin yìí ní ìrètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ọ̀kan lára wọ́n sọ pé: “Ká sòótọ́, àǹfààní iṣẹ́ ìsìn àrà ọ̀tọ̀ lèyí jẹ́, àmọ́ bí mo ṣe máa ń wà pẹ̀lú wọn ti jẹ́ kí n rí i lọ́pọ̀ ìgbà pé bí àwọn arákùnrin yìí tilẹ̀ jẹ́ ẹni àmì òróró, aláìpé ṣì ni wọ́n. Síbẹ̀, ọ̀kan lára ohun tí mo ti pinnu láti àwọn ọdún yìí wá ni pé màá máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú.” Arákùnrin kejì sọ pé: “Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi 2 Kọ́ríńtì 10:5 tó sọ pé ká ‘ṣègbọràn sí Kristi,’ ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa ṣègbọràn kí n sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń múpò iwájú. Torí náà, mo máa ń ṣègbọràn látọkàn wá.” Arákùnrin kẹta sọ pé: “Ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé à ń ṣègbọràn sí ètò Ọlọ́run àti sí àwọn tó ń lò láti máa polongo ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé ni pé ká máa nífẹ̀ẹ́ ohun tí Jèhófà bá nífẹ̀ẹ́, ká máa kórìíra ohun tó bá kórìíra, ká máa wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀ nígbà gbogbo, ká sì máa ṣe ohun tó wù ú.” Arákùnrin yìí gbọ́ pé Arákùnrin Nathan Knorr tó di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí tẹ́wọ́ gba àwọn àlàyé kan tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ 1925 lédè Gẹ̀ẹ́sì, tó sọ̀rọ̀ nípa ìbí orílẹ̀-èdè náà, ìyẹn “Birth of the Nation,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan rò pé àwọn àlàyé náà kò tọ̀nà. Bí Arákùnrin Knorr ṣe ṣègbọràn yìí wú arákùnrin náà lórí gan-an. Bí ìwọ náà bá ń ronú lórí ohun táwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ yìí sọ, wàá lè máa ṣègbọràn kó o lè máa jẹ́ mímọ́.

MÁA ṢÈGBỌRÀN DÉLẸ̀DÉLẸ̀ SÍ ÒFIN ỌLỌ́RUN LÓRÍ Ọ̀RÀN Ẹ̀JẸ̀

10. Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé ká ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀?

10 Ka Léfítíkù 17:10. Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe jẹ “ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí.” Ọlọ́run ní kí àwa Kristẹni náà ta kété sí ẹ̀jẹ̀, ì báà jẹ́ ti èèyàn tàbí ti ẹranko. (Ìṣe 15:28, 29) Kò sẹ́ni tẹ́rù ò ní bà tó bá mọ̀ pé Ọlọ́run máa ‘dojú kọ òun’ kó sì ké òun kúrò láàárín ìjọ àwọn èèyàn rẹ̀. A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì fẹ́ láti máa ṣègbọràn sí i. Bó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé a dojú kọ ohun tó lè ṣekú pa wá, tí àwọn tí kò mọ Jèhófà tí wọn ò sì fẹ́ ṣègbọràn sí i ń rọ̀ wá láti ṣohun tí kò tọ́, a ti pinnu pé a ò ní juwọ́ sílẹ̀. Kódà, bí wọ́n bá fẹ́ mú wa lọ́ranyàn, a ò ní gbà. Ó dájú pé àwọn èèyàn máa fi wá ṣẹ̀sín tá a bá ta kété sí ẹ̀jẹ̀, àmọ́ a ti pinnu láti ṣègbọràn sí ohun tí Ọlọ́run sọ. (Júúdà 17, 18) Tó bá dọ̀ràn ẹ̀jẹ̀, kí ló máa mú ká ‘pinnu lọ́nà tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in’ pé a kò ní jẹ ẹ̀jẹ̀ tàbí pé a ò ní gbà kí wọ́n fà á sí wa lára?—Diu. 12:23.

11. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Ọjọ́ Ètùtù tó máa ń wáyé lọ́dọọdún kì í ṣe ààtò ẹ̀sìn tí kò ṣe pàtàkì?

11 Bí àlùfáà àgbà ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣe máa ń lo ẹ̀jẹ̀ ẹran ní Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún jẹ́ ká lóye ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀jẹ̀. Ó ní nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ kí àlùfáà náà máa lò ó fún. Ó fẹ́ kó máa fi ẹ̀jẹ̀ ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó ń wá ìdáríjì lọ́dọ̀ Jèhófà. Kó máa wọ́n ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ síhà ìbòrí àpótí májẹ̀mú náà àti níwájú rẹ̀. (Léf. 16:14, 15, 19) Èyí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún Jèhófà láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jì wọ́n. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà pàṣẹ pé bí ọkùnrin kan bá fẹ́ pa ẹran jẹ, kí ó da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde kí ó sì fi erùpẹ̀ bò ó, “nítorí ọkàn gbogbo onírúurú ẹran ara ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.” (Léf. 17:11-14) Ṣé ààtò ẹ̀sìn tí kò ṣe pàtàkì ni gbogbo èyí jẹ́? Rárá o. Bí wọ́n ṣe ń lo ẹ̀jẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù àti àṣẹ tí Jèhófà pa fún wọn pé kí wọ́n máa da ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, bá àṣẹ tó kọ́kọ́ pa mu, èyí tó pa fún Nóà àtàwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ nípa ẹ̀jẹ̀. (Jẹ́n. 9:3-6) Jèhófà Ọlọ́run ti sọ pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ lo ẹ̀jẹ̀ láti fi gba ẹ̀mí là. Báwo lèyí ṣe kan àwa Kristẹni?

12. Báwo ni lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ṣe fi hàn pé ẹ̀jẹ̀ ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìdáríjì?

12 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni nípa agbára ìwẹ̀nùmọ́ tí ẹ̀jẹ̀ ní, ó ṣàlàyé pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀ mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú Òfin, bí kò sì ṣe pé a tú ẹ̀jẹ̀ jáde, ìdáríjì kankan kì í wáyé.” (Héb. 9:22) Pọ́ọ̀lù tún ṣàlàyé pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹbọ tí wọ́n ń fi ẹran rú níye lórí dé ìwọ̀n kan, ńṣe ló ń rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àti pé wọ́n nílò ohun tó ju ẹran lọ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò pátápátá. Ó ṣe kedere pé Òfin jẹ́ “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe kókó inú àwọn ohun náà gan-an.” (Héb. 10:1-4) Báwo wá ni ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ṣe máa ṣeé ṣe?

13. Báwo ló ṣe rí lára rẹ pé Jésù fún Jèhófà ní ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀?

13 Ka Éfésù 1:7. Ikú ìrúbọ Jésù Kristi tó fínnú-fíndọ̀ ‘fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún wa’ ṣe gbogbo àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀ àti Baba rẹ̀ láǹfààní gan-an. (Gál. 2:20) Síbẹ̀, ohun tí Jésù ṣe lẹ́yìn ikú àti àjíǹde rẹ̀ ló dá wa sílẹ̀, tó sì mú ká rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù bó sè wà nínú Òfin Mósè ṣàpẹẹrẹ ohun tí Jésù wá mú ṣẹ. Ní ọjọ́ yẹn, àlùfáà àgbà mú díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ ẹran ìrúbọ náà lọ sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú àgọ́ ìjọsìn ó sì fi í fún Ọlọ́run, bíi pé ó wà níwájú rẹ̀. Ohun kan náà ni wọ́n ṣe nínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì nígbà tó yá. (Léf. 16:11-15) Lọ́nà kan náà, Jésù wọ ọ̀run lọ pẹ̀lú ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó fi rúbọ nígbà tó wà láyé, ó sì fi í fún Jèhófà. (Héb. 9:6, 7, 11-14, 24-28) A mà dúpẹ́ gan-an o pé Ọlọ́run ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá ó sì tún ń sọ ẹ̀rí ọkàn wa di mímọ́ torí pé à ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù!

14, 15. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká lóye òfin Jèhófà lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ ká sì tún máa ṣègbọràn sí òfin náà?

14 Ní báyìí, ṣé o ti wá lóye ìdí tí Jèhófà fi pàṣẹ fún wa pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ “ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí”? (Léf. 17:10) Ṣé o sì ti lóye ìdí tí Ọlọ́run fi ka ẹ̀jẹ̀ sí mímọ́? Ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀mí gan-an ló fi ń wo ẹ̀jẹ̀. (Jẹ́n. 9:4) Ǹjẹ́ o gba pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀jẹ̀ ló yẹ káwa náà máa fi wò ó, ká sì máa ṣègbọràn sí àṣẹ tó fún wa pé ká ta kété sí ẹ̀jẹ̀? Ọ̀nà kan ṣoṣo tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fi lè ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run ni pé ká ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù ká sì mọ̀ pé ọwọ́ pàtàkì ni Ẹlẹ́dàá wa fi mú ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀.—Kól. 1:19, 20.

15 Ẹnikẹ́ni nínú wa lè ṣàdédé dojú kọ ìṣòro tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀. Ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ kan sì lè dé bá aráalé wa tàbí ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n kan tó máa gba pé kí wọ́n fa ẹ̀jẹ́ sí i lára, tó sì ní láti pinnu bóyá òun máa gbẹ̀jẹ̀ tàbí òun kò ní gbà á. Bí irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ bá wáyé, ó tún lè gba pé kéèyàn pinnu bóyá òun máa gbà kí wọ́n fi àwọn èròjà kéékèèké inú ẹ̀jẹ̀ tọ́jú òun tàbí ó máa gba irú àwọn ìtọ́jú kan. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká ṣe ìwádìí ká sì múra sílẹ̀ de ipò pàjáwìrì tó ṣeé ṣe kó wáyé. Tá a bá ń gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà, irú ìmúrasílẹ̀ bẹ́ẹ̀ á mú ká lè dúró gbọn-in, a ò sì ní ṣe ohun tó lòdì lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀. Dájúdájú, a ò ní fẹ́ ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́, torí náà, a ò ní tẹ́wọ́ gba ohun tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé kò dára. Ọ̀pọ̀ dókítà àtàwọn míì tó ń gbé ìfàjẹ̀sínilára lárugẹ máa ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ láti fi gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là. Àmọ́, àwọn èèyàn mímọ́ tó ń sin Jèhófà gbà pé Ẹlẹ́dàá ní ẹ̀tọ́ láti sọ ọ̀nà tó yẹ ká gbà lo ẹ̀jẹ̀. Lójú Ẹlẹ́dàá, “ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí” jẹ́ mímọ́. Ńṣe ló yẹ ká dúró lórí ìpinnu wa pé a ó máa ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀. Tá a bá ń hùwà mímọ́, à ń fi han Ọlọ́run pé a mọyì agbára tí ẹ̀jẹ̀ Jésù ní láti gbani là, ìyẹn ẹ̀jẹ̀ kan ṣoṣo tó ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìyè àìnípẹ̀kun gbà.—Jòh. 3:16.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ṣé o ti pinnu pé wàá máa ṣègbọràn sí òfin Jèhófà lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀? (Wo ìpínrọ̀ 14, 15)

ÌDÍ TÍ JÈHÓFÀ FI RETÍ PÉ KÁ JẸ́ MÍMỌ́

16. Kí nìdí tí àwọn èèyàn Jèhófà fi gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́?

16 Nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lóko ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì, ó sọ fún wọn pé: “Èmi ni Jèhófà tí ó mú yín gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti fi ara mi hàn ní Ọlọ́run fún yín; kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí pé mo jẹ́ mímọ́.” (Léf. 11:45) Jèhófà retí pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ mímọ́ torí pé òun fúnra rẹ̀ jẹ́ mímọ́. Torí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́. Ìwé Léfítíkù jẹ́ kó ṣe kedere pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́.

17. Kí wá lèrò rẹ nípa ìwé Léfítíkù báyìí?

17 Ó dájú pé a ti jàǹfààní nínú àwọn apá tá a gbé yẹ̀ wò nínú ìwé Léfítíkù. Kò sí àní-àní pé ohun tá a ti jíròrò yìí mú kó o túbọ̀ mọyì ìwé Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí yìí. Ó dájú pé àṣàrò tó o ti ṣe lórí àwọn kan lára ìsọfúnni tó ṣeyebíye tó wà nínú ìwé Léfítíkù ti mú kó o túbọ̀ lóye àwọn ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́. Àmọ́, àwọn ìṣúra tẹ̀mí míì wo ló ń dúró dè wá nínú ìwé Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí yìí? Kí la tún máa rí kọ́ nínú rẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Jèhófà? A máa jíròrò àwọn kókó yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́