Látinú Àpamọ́ Wa
Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Dé Ilẹ̀ Japan
A fi ìwé ìkésini yìí pe gbogbo èèyàn sí àsọyé ní ìlú Tokyo a sì tún fi ọkọ̀ òfuurufú fọ́n ọn káàkiri ìlú Osaka
NÍ September 6, ọdún 1926, ọmọ ilẹ̀ Japan kan tó jẹ́ arìnrìn-àjò-ìsìn (alábòójútó arìnrìn-àjò) lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pa dà sí ilẹ̀ Japan láti lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Ẹni tó ń dúró dè é láti kí i káàbọ̀ ni ẹnì kan ṣoṣo tí wọ́n máa ń fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì ránṣẹ́ sí déédéé, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwùjọ kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílùú Kobe. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe àpéjọ wọn àkọ́kọ́ nílùú yẹn ní January 2, ọdún 1927. Àwọn mẹ́rìndínlógójì [36] ló pésẹ̀ síbẹ̀, àwọn mẹ́jọ sì ṣèrìbọmi. Ohun tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ yìí dára gan-an ni, àmọ́ báwo ni àwùjọ kékeré yìí ṣe máa dé ọ̀dọ̀ ọgọ́ta mílíọ̀nù [60,000,000] èèyàn tó ń gbé ilẹ̀ Japan tó sì yẹ kí wọ́n rí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Bíbélì?
Ní oṣù May ọdún 1927, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n nítara ṣe ìpolongo láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa ọ̀wọ́ àsọyé Bíbélì tó máa wáyé. Káwọn èèyàn lè mọ̀ nípa àsọyé àkọ́kọ́ tó máa wáyé nílùú Osaka, àwọn ará gbé àwọn àmì sí ojú ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì káàkiri ìlú náà, wọ́n sì gbé àwọn pátákó gàdàgbà síbi táwọn èèyàn ti lè rí i, wọ́n wá fi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ìwé ìpè ránṣẹ́ sí àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn. Wọ́n tún pín ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ [150,000] ìwé ìkésíni, wọ́n sì polongo àsọyé náà nínú àwọn ìwé ìròyìn tó gbajúmọ̀ nílùú Osaka àti nínú ogún ọ̀kẹ́ [400,000] tíkẹ́ẹ̀tì ọkọ̀ ojú irin. Lọ́jọ́ tí wọ́n fẹ́ sọ àsọyé náà, ọkọ̀ òfuurufú méjì fò lórí ìlú náà, wọ́n sì fọ́n ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] ìwé ìkésíni káàkiri. Àwọn èèyàn tí wọ́n kún inú Gbọ̀ngàn Osaka Asahi tó nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún lé lẹ́gbàá [2,300], wọ́n wá gbọ́ àsọyé tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ “Ìjọba Ọlọ́run Kù sí Dẹ̀dẹ̀.” Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan èèyàn la ní láti dá pa dà torí pé wọ́n ò ráyè wọlé. Lẹ́yìn àsọyé náà, ó jú ẹgbẹ̀ta [600] lára àwọn tó wá tí wọ́n dúró láti gbọ́ apá tó jẹ́ ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní àwọn oṣù tó tẹ̀ lé e, wọ́n sọ àwọn àsọyé Bíbélì nílùú Kyoto àtàwọn ìlú míì ní ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Japan.
Ní oṣù October ọdún 1927, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣètò àwọn àsọyé ní ìlú Tokyo. Wọ́n tún pín ìwé ìpè fún àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn, títí kan olórí ìjọba, àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, àwọn olórí ẹ̀sìn àtàwọn lọ́gàálọ́gàá nínú iṣẹ́ ológun. Wọ́n lo àwọn ìwé tí wọ́n lẹ̀ káàkiri, ìwé ìròyìn àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́wàá [710,000] ìwé ìkésíni. Ẹgbẹ̀rìnlélógún [4,800] èèyàn ló wá gbọ́ àsọyé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní olú ìlú Japan yìí.
ÀWỌN ONÍTARA APÍNWÈÉ-ÌSÌN-KIRI
Katsuo àti Hagino Miura
Àwọn apínwèé-ìsìn-kiri (ìyẹn àwọn aṣáájú-ọ̀nà) kó ipa pàtàkì nínú mímú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn nílé wọn. Tá a bá dá orílẹ̀-èdè náà sí ọ̀nà mẹ́rin, Matsue Ishii tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn apínwèé-ìsìn-kiri àkọ́kọ́ nílẹ̀ Japan pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ Jizo, wàásù ní mẹ́ta nínú ìdá mẹ́rin náà, ìyẹn láti Sapporo lápá ibi jíjìn ní àríwá títí dé àwọn ìlú Sendai, Tokyo, Yokohama, Nagoya, Osaka, Kyoto, Okayama àti Tokushima. Arábìnrin Ishii àti arábìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Sakiko Tanaka, máa ń wọ kimono, ìyẹn aṣọ ìmúròde àwọn ará Japan lọ sọ́dọ̀ àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba. Ọ̀kan lára wọn béèrè ọgọ́rùn-ún mẹ́ta lára àwọn ìwé Duru Ọlọrun lédè Gẹ̀ẹ́sì àti ìwé Deliverance, [Ìdáǹdè], ó fẹ́ kó wọn sílé ìkàwé nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Tọkọtaya Katsuo àti Hagino Miura gba àwọn ìwé lọ́dọ̀ Arábìnrin Ishii, gbàrà tí wọ́n ka àwọn ìwé náà ni wọ́n sì ti rí i pé òtítọ́ ló wà níbẹ̀. Wọ́n ṣèrìbọmi lọ́dún 1931 wọ́n sì di apínwèé-ìsìn-kiri. Tọkọtaya Haruichi àti Tane Yamada pẹ̀lú ọ̀pọ̀ lára ìdílé wọn tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní àkókò kan ṣáájú ọdún 1930. Tọkọtaya yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri, Yukiko ọmọbìnrin wọn sì lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì nílùú Tokyo.
“JÉHÙ” ŃLÁ ÀTI KÉKERÉ
“Jéhù” Ńlá gba aṣáájú-ọ̀nà mẹ́fà
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún owó ńlá ni wọ́n fi ń ra ọkọ, ojú ọ̀nà ò sì dáa. Nítorí náà, Kazumi Minoura àtàwọn apínwèé-ìsìn-kiri míì tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ máa ń lo àwọn ọkọ̀ àfiṣelé tí kò ní ẹ́ńjìnnì. Wọ́n pe àwọn ọkọ̀ àfiṣelé náà ni Jéhù torí pé Jéhù máa ń fagbára gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin, tó sì wá di ọ̀kan lára àwọn ọba Ísírẹ́lì. (2 Ọba 10:15, 16) Wọ́n ní “Jéhù” Ńlá mẹ́ta tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lè gba àwọn aṣáájú-ọ̀nà mẹ́fà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gùn tó 2.2 mítà (ẹsẹ̀ bàtà 7.2), ó fẹ̀ tó 1.9 mítà (ẹsẹ̀ bàtà 6.2), ó sì ga tó 1.9 mítà (ẹsẹ̀ bàtà 6.2). Yàtọ̀ síyẹn, ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa ní Japan wọ́n ṣe “Jéhù” Kékeré mọ́kànlá tí wọ́n ń fi kẹ̀kẹ́ fà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lè gba èèyàn méjì. Ẹni tó máa ń bá wọ́n ṣe àwọn “Jéhù” náà ni Kiichi Iwasaki, ó sọ pé, “Jéhù kọ̀ọ̀kan máa ń ní ibi àfiṣelé tó dà bí àgọ́ àti bátìrì ọkọ̀ tí wọ́n ń lò fún títan àwọn iná.” Àwọn apínwèé-ìsìn-kiri máa ń tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ káàkiri ilẹ̀ Japan bí wọ́n ti ń ti àwọn “Jéhù” náà kiri tí wọ́n sì ń fà wọ́n gun àwọn òkè tí wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀, wọ́n máa ń gbé wọn gba àwọn àfonífojì kọjá láti Hokkaido ní àríwá títí dé Kyushu ní gúúsù.
“Jéhù” Kékeré gba èèyàn méjì
Apínwèé-ìsìn-kiri tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ikumatsu Ota sọ pé: “Tá a bá dé sí ìlú kan, àá gbé “Jéhù” wa sétí odò tàbí sí pápá gbalasa. A kọ́kọ́ máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn lóókọlóókọ láàárín ìlú, irú bí olórí ìlú, lẹ́yìn náà, àá lọ sílé àwọn èèyàn láti fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn wọn. Lẹ́yìn tá a bá ti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù náà, àá gbéra lọ sí ìlú tó kàn.”
“Ọjọ́ àwọn ohun kékeré” ni ọjọ́ yẹn lọ́hùn-ún nígbà táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́rìndínlógójì [36] nílùú Kobe ṣe àpéjọ wọn àkọ́kọ́. (Sek. 4:10) Ọdún márùn-ún péré lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 1932, àwọn apínwèé-ìsìn-kiri àtàwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run nílẹ̀ Japan tí wọ́n jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́rùn-ún [103] ròyìn iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, wọ́n fún àwọn èèyàn ní ìwé tó ju ẹgbàá méje [14,000] lọ. Lóde òní, à ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù tá a ṣètò rẹ̀ dáadáa ní àwọn ibi tí èrò pọ̀ sí nílẹ̀ Japan, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mọ́kànlá [220,000] akéde Ìjọba Ọlọ́run ló sì ń tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ káàkiri ilẹ̀ Japan.—Látinú àpamọ́ wa ní Japan.
Sketches by Kiichi Iwasaki, who built the Jehus at Japan Bethel
Katsuo àti Hagino Miura