ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 2/1 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Yóò Fún Wa Ní Ìjọba Kan Tó Máa Ṣàkóso Gbogbo Ayé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 2/1 ojú ìwé 16

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ǹjẹ́ gbogbo ayé lè wà lábẹ́ ìjọba kan ṣoṣo?

Gbogbo èèyàn kárí ayé máa wà lábẹ́ ìjọba kan ṣoṣo

Báwo ni ìjọba kan tó kárí ayé ṣe máa mú kí gbogbo èèyàn wà ní ìṣọ̀kan? Isaiah 32:1, 17; 54:13

Fojú inú wo bí nǹkan ṣe máa rí tí gbogbo ayé bá wà lábẹ́ ìjọba kan ṣoṣo. Inú ayé tí ìyà ti ń jẹ́ àwọn tálákà, táwọn olówó sì ń gbádùn lọ ràì là ń gbé. Àmọ́ tí gbogbo ayé bá wà lábẹ́ ìjọba kan ṣoṣo tó fẹ́ràn àwọn aráàlú, ńṣe ni gbogbo èèyàn máa ní ohun tí wọ́n ń fẹ́. Ǹjẹ́ o rò pé àwa èèyàn lè pawọ́pọ̀ ṣètò irú ìjọba bẹ́ẹ̀?—Ka Jeremáyà 10:23.

Ká sòótọ́, ìjákulẹ̀ ló ti gbẹ̀yìn gbogbo ìjọba táráyé gbé kalẹ̀. Wọn ò rí tàwọn mẹ̀kúnnù rò rárá, kódà àwọn ìjọba kan tiẹ̀ máa ń dìídì ni àwọn èèyàn lára. (Oníwàásù 4:1; 8:9) Àmọ́, Ọlọ́run Olódùmarè ṣèlérí fún wa pé òun máa fi ìjọba kan rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn. Ó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Ọba tí òun ti yàn máa tọ́jú wa dáadáa.—Ka Aísáyà 11:4; Dáníẹ́lì 2:44.

Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa gbé ṣe?

Jèhófà Ọlọ́run ti yan ẹni tó tóótun láti ṣàkóso ayé yìí, ẹni náà ni Jésù Ọmọ rẹ̀. (Lúùkù 1:31-33) Jésù ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso lóòótọ́ torí pé nígbà tó wà láyé, ó fẹ́ràn àtimáa rán àwọn èèyàn lọ́wọ́. Láìpẹ́, Jésù máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ́ wa, á sì mú kí gbogbo ayé wà ní ìṣọ̀kan.—Ka Sáàmù 72:8, 12-14.

Ṣé gbogbo èèyàn ló ti gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Alákòóso wọn? Rárá o. Àmọ́, Jèhófà ṣì ń mú sùúrù fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. (2 Pétérù 3:9) Ó fẹ́ kí wọ́n tún èrò wọn pa, kí wọ́n sì gba Jésù ni alákòóso tàbí adarí. Torí pé láìpẹ́, Jésù máa pa àwọn èèyàn burúkú run, á sì mú kí àlàáfíà gbilẹ̀ kárí ayé.—Ka Míkà 4:3, 4.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 8 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́