ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 3/1 ojú ìwé 13-15
  • Àwọn Ẹ̀bùn Tó Tọ́ Sí Ọba

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ẹ̀bùn Tó Tọ́ Sí Ọba
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • LÍLA AṢÁLẸ̀ ARÉBÍÀ KỌJÁ
  • “ÒWÒ TÍ WỌ́N TÍÌ BÒ LÁṢÌÍRÍ JÙ LỌ”
  • Bí Wọ́n Ṣe Ń Lo Ohun Ìṣaralóge Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Básámù Gílíádì Òróró Ìkunra Tó ń Woni Sàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 3/1 ojú ìwé 13-15
Oríṣiríṣi èròjà atasánsán

Àwọn Ẹ̀bùn Tó Tọ́ Sí Ọba

“Àwọn awòràwọ̀ láti àwọn apá ìlà-oòrùn . . . ṣí àwọn ìṣúra wọn pẹ̀lú, wọ́n sì fún un ní àwọn ẹ̀bùn, wúrà àti oje igi tùràrí àti òjíá.”—Mátíù 2:1, 11.

IRÚ ẹ̀bùn wo lo máa fún ẹnì kan tó ṣe pàtàkì láwùjọ? Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, bí wúrà ṣe níye lórí ni àwọn èròjà atasánsán níye lórí débi pé ọba ni irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ tọ́ sí.a Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé èròjà atasánsán ni méjì lára àwọn ẹ̀bùn táwọn awòràwọ̀ náà fún “ọba àwọn Júù.”—Mátíù 2:1, 2, 11.

Òróró Básámù

Òróró Básámù

Bíbélì tún sọ pé nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà bẹ Sólómọ́nì wò, “ó fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ńtì wúrà, àti òróró básámù ní ìwọ̀n púpọ̀ gan-an, àti àwọn òkúta iyebíye; kò sì tíì wá sí òróró básámù tí ó dà bí èyí tí ọbabìnrin Ṣébà fún Sólómọ́nì Ọba.”b (2 Kíróníkà 9:9) Àwọn ọba míì tún fi òróró básámù ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn.—2 Kíróníkà 9:23, 24.

Kí nìdí tí àwọn èròjà atasánsán yìí fi wọ́n tó bẹ́ẹ̀ láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ń lò ó fún, irú bíi ṣíṣe ara lóge, ààtò ìsìn àti ìsìnkú. (Wo àpótí náà “Ohun Tí Wọ́n Ń Lo Àwọn Èròjà Atasánsán fún Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì.”) Ohun míì tó jẹ́ kó wọ́n ni pé, ọjà yìí ń tà wàràwàrà, owó kékeré kọ́ ni wọ́n sì ń ná láti kó o wọ̀lú.

LÍLA AṢÁLẸ̀ ARÉBÍÀ KỌJÁ

Kaṣíà

Kaṣíà

Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn igi olóòórùn dídùn tí wọ́n máa ń rí èròjà atasánsán lára rẹ̀ máa ń hù ní Àfonífojì Jọ́dánì. Àmọ́, wọ́n máa ń kó àwọn míì wá láti òkè òkun. Bíbélì mẹ́nu kan oríṣiríṣi àwọn èròjà atasánsán yìí. Èyí táwọn èèyàn mọ̀ jù ni sáfúrónì, álóè, básámù, sínámónì, oje igi tùràrí àti òjíá. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún mẹ́nu kan onírúurú èròjà amóúnjẹ ta sánsán bíi kúmínì, efinrin àti dílì.

Ibo ni wọ́n ti ń rí àwọn èròjà atasánsán tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí? Àwọn ibi tá a wá mọ̀ sí Ṣáínà, Íńdíà àti Sri Lanka lóde òní ni wọ́n ti ń rí álóè, kaṣíà àti sínámónì. Ara àwọn igi àti igbó tó wà ní aṣálẹ̀ gúúsù Arébíà títí lọ dé Sòmálíà nílẹ̀ Áfíríkà ni wọ́n ti ń rí òjíá àti oje igi tùràrí. Àwọn ará Íńdíà ló ń ṣe èròjà náádì tàbí sípíkénádì, agbègbè Himalayas ni wọ́n sì ti ń rí i.

Sáfúrónì

Sáfúrónì

Ilẹ̀ Arébíà ni àwọn oníṣòwò máa ń gbà kó àwọn èròjà atasánsán dé ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ìwé The Book of Spices wá sọ pé èyí wà lára ohun tó mú kí ilẹ̀ Arébíà di “ojú ọ̀nà kan ṣoṣo tí àwọn oníṣòwò máa ń gbà kó ọjà láti apá Ìlà Oòrùn lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn” ní ẹgbẹ̀rún ọdún kìíní àti ìkejì Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Wọ́n tiẹ̀ ṣàwárí àwọn ìlú àtijọ́, ilé olódi àtàwọn abà táwọn oníṣòwò ti máa ń sinmi ní Négébù tó wà ní gúúsù Ísírẹ́lì, èyí sì jẹ́ kí wọ́n mọ ojú ọ̀nà táwọn oníṣòwò tó ń ta èròjà atasánsán ń gbà kọjá. Ẹ̀ka tó ń rí sí Àwọn Ibi Àgbàyanu Yíká Ayé lábẹ́ àjọ UNESCO sọ pé àwọn ibùdó tí wọ́n ṣàwárí yìí fi hàn pé “òwò ńlá tó ń mérè gọbọi wá . . . ni wọ́n ń ṣe láti gúúsù Arébíà títí lọ dé Mẹditaréníà.”

“Ọjà tó lówó lórí ni àwọn èròjà atasánsán torí pé ọjà díẹ̀, èrè gọbọi ni, ó sì ń tà wàràwàrà.” —Ìwé náà, The Book of Spices

Àwọn oníṣòwò tó ń ta àwọn èròjà yìí sábà máa ń rìnrìn àjò tí ó tó ẹgbẹ̀sán [1,800] kìlómítà la ilẹ̀ Arébíà kọjá. (Jóòbù 6:19) Bíbélì sọ nípa àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì oníṣòwò tó ń kó àwọn èròjà atasánsán bíi “gọ́ọ̀mù lábídánúmù àti básámù àti èèpo-igi olóje” láti Gílíádì lọ sí Íjíbítì. (Jẹ́nẹ́sísì 37:25) Àwọn oníṣòwò yìí ni àwọn ọmọ Jékọ́bù ta Jósẹ́fù àbúrò wọn fún gẹ́gẹ́ bí ẹrú.

“ÒWÒ TÍ WỌ́N TÍÌ BÒ LÁṢÌÍRÍ JÙ LỌ”

Dílì

Dílì

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn oníṣòwò Arébíà nìkan ló ń ta ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èròjà atasánsán yìí fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún. Torí náà, àwọn nìkan ni wọ́n máa ń kó àwọn èròjà bíi kaṣíà àti sínámónì wá láti Éṣíà. Kí àwọn oníṣòwò Mẹditaréníà má baà gbégbá òwò yìí, ńṣe làwọn oníṣòwò Arébíà bẹ̀rẹ̀ sí í hùmọ̀ àwọn ìtàn àròsọ nípa ewu téèyàn máa là kọjá kó tó rí àwọn èròjà yẹn. Ìwé The Book of Spices sọ pé orísun àwọn èròjà atasánsán ni “òwò tí wọ́n tíì bò láṣìírí jù lọ.”

Kúmínì

Kúmínì

Àwọn ìtàn wo ni àwọn ará Arébíà tàn kálẹ̀? Herodotus tó jẹ́ òpìtàn ilẹ̀ Gíríìsì ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún Ṣáájú Sànmánì Kristẹni sọ nípa àwọn ẹyẹ abàmì tó fi èèpo igi sínámónì kọ́ ìtẹ́ wọn sórí àwọn òkè ńlá tí kò ṣe é gùn. Kí wọ́n lè rí èèpo igi yìí, wọ́n máa kó ẹran ńláńlá sí ẹsẹ̀ òkè ńlá náà. Àwọn ẹyẹ yìí máa wá fi ìwọra kó ẹran tó pọ̀ lọ sínú ìtẹ́ wọn, èyí á sì mú kí ìtẹ́ náà jábọ́ sílẹ̀. Tó bá ti jábọ́, wọ́n á tètè ṣa àwọn èèpo igi sínámónì tó wà níbẹ̀, wọ́n á sì tà á fáwọn oníṣòwò. Irú àwọn ìtàn yìí gbòde gan-an nígbà yẹn. Ìwé The Book of Spices sọ pé torí “ewu tí wọ́n sọ pé ó wà nínú rírí sínámónì, owó gọbọi ni wọ́n ń tà á.”

Efinrin

Efinrin

Níkẹyìn, àṣírí àwọn oníṣòwò Arébíà yìí tú, ọ̀pọ̀ àwọn míì sì gbégbá òwò yìí. Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìlú Alẹkisáńdíríà nílẹ̀ Íjíbítì wá di ibùdó ọkọ̀ òkun ńlá, àwọn èròjà atasánsán sì ń tà níbẹ̀ wàràwàrà. Àwọn atukọ̀ okùn kíyè sí ìgbà tí afẹ́fẹ́ Òkun Íńdíà máa ń dẹrùn, bí àwọn ọkọ̀ òkun Róòmù ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn èròjà atasánsán láti Íjíbítì lọ sí ilẹ̀ Íńdíà nìyẹn. Bí wọ́n ṣe ń kó àwọn èròjà yìí wọ̀lú lọ́pọ̀ yanturu mú kí owó rẹ̀ wálẹ̀ dáadáa.

Lónìí, a ò lè fi iye tí wọ́n ń ta àwọn èròjà atasánsán wé ti wúrà, a ò sì kà á sí ẹ̀bùn tó tọ́ sí ọba mọ́. Síbẹ̀, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ṣì ń lò wọ́n gẹ́gẹ́ bíi lọ́fíńdà àti oògùn, wọ́n sì ń fi àwọn míì sínú oúnjẹ kó lè máa ta sánsán. Kò sí àní-àní pé òórùn dídùn táwọn èròjà yìí ní mú kí wọ́n gbajúmọ̀ lónìí gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe gbajúmọ̀ ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn.

Àdìpọ̀ igi sínámónì

Sínámónì

a Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “èròjà atasánsán” máa ń tọ́ka sí àwọn ewéko tó ń ta sánsán tàbí lọ́fíńdà, kì í ṣe àwọn èròjà amóúnjẹdùn.

b “Òróró básámù” jẹ́ òróró atasánsán tàbí òjé igi tí wọ́n rí lára igi àtàwọn igbó ṣúúrú.

Ohun Tí Wọ́n Ń Lo Àwọn Èròjà Atasánsán fún Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì

Òróró àfiyanni àti tùràrí mímọ́. Jèhófà sọ bí Mósè ṣe máa ṣe òróró àfiyanni tàbí òróró ìkunra àti tùràrí mímọ́. Èròjà atasánsán mẹ́rin ni wọ́n pò pọ̀ láti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí. (Ẹ́kísódù 30:22-25, 34-38) Àwọn àlùfáà kan ni wọ́n yanṣẹ́ ṣíṣe òróró àfiyanni fún, wọ́n sì tún gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó.—Númérì 4:16; 1 Kíróníkà 9:30.

Lọ́fíńdà àti òróró ìkunra. Àwọn tó lówó máa ń ra àtíkè olóòórùn dídùn láti mú ilé wọn ta sánsán, wọ́n máa ń fín in sára aṣọ, ibùsùn àti sí ara. (Ẹ́sítérì 2:12; Òwe 7:17; Orin Sólómọ́nì 3:6, 7; 4:13, 14) Màríà tó jẹ́ arábìnrin Lásárù da “òróró onílọ́fínńdà, ojúlówó náádì,” tó wọ́n gan-an sí irun àti ẹsẹ̀ Jésù. Iye tí wọ́n ń ta ìṣà kékeré “ojúlówó náádì” tó owó iṣẹ́ ọdún kan.—Máàkù 14:3-5; Jòhánù 12:3-5.

Mímúra òkú sílẹ̀ fún ìsìnkú. Nikodémù mú “àdìpọ̀ òjíá àti àwọn álóè” wá fún mímúra òkú Jésù sílẹ̀ fún ìsìnkú. (Jòhánù 19:39, 40) Àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà mú “èròjà atasánsán àti àwọn òróró onílọ́fínńdà” wá sí ibojì Jésù.—Lúùkù 23:56–24:1.

Amóúnjẹdùn. Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa lo àwọn èròjà yìí láti mú ẹja àti ẹran tí wọ́n bá sè ta sánsán. Wọ́n sì máa ń fi àwọn èròjà atasánsán míì sínú wáìnì.—Orin Sólómọ́nì 8:2.

Àwọn Èròjà Atasánsán Méjì Tí Wọ́n Fún Jésù

Oje igi tó máa ń jáde lára èèpo ẹ̀yìn igi kéékèèké àti igbó ṣúúrú tí wọ́n bá là ni wọ́n fí ń ṣe oje igi tùràrí àti òjíá.

Igi olóje máa ń hù ní àwọn etíkun tó wà lápá gúúsù ilẹ̀ Arébíà, igi òjíá sì pọ̀ ní àwọn aṣálẹ̀ orílẹ̀-èdè Sòmálíà àti Yemen. Àwọn èèyàn ka àwọn èròjà atasánsán méjì yìí sí pàtàkì gan-an nítorí òórùn dídùn wọn. Jèhófà pàápàá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láṣẹ pé kí wọ́n máa lò ó nínú ìjọsìn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, òjíá wà lára ohun tí wọ́n fi ń ṣe òróró mímọ́ àfiyanni, oje igi tùràrí sì wà lára ohun tí wọ́n fi ń ṣe tùràrí mímọ́. (Ẹ́kísódù 30:23-25, 34-37) Àmọ́ ìlò àwọn méjèèjì yàtọ̀ síra.

Tùràrí ni wọ́n sábà máa ń fi oje igi tùràrí ṣe, ó sì dìgbà tí wọ́n bá sun ún kí òórùn rẹ̀ tó jáde. Àmọ́ oje tó jáde lára igi òjíá máa ń mú òórùn jáde ní gbàrà tí wọ́n bá ti yọ ọ́. Ẹ̀ẹ̀mẹta ni Bíbélì mẹ́nu kan òjíá nínú ọ̀ràn Jésù: àkọ́kọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn tí wọ́n fún un ní kékeré (Mátíù 2:11), ìkejì, g̣ẹ́gẹ́ bí oògùn apàrora pa pọ̀ pẹ̀lú wáìnì nígbà tó wà lórí òpó igi oró (Máàkù 15:23), àti ìkẹta, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn èròjà atasánsán tí wọ́n fi múra òkú rẹ̀ sílẹ̀ fún ìsìnkú (Jòhánù 19:39).

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́