Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
March 15, 2015
© 2015 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
MAY 4-10, 2015
“Èyí Ni “Ọ̀nà Tí Ìwọ Tẹ́wọ́ Gbà”
MAY 11-17, 2015
Ṣé Wàá “Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”?
OJÚ ÌWÉ 12 • ORIN: 108, 24
MAY 18-24, 2015
Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpèjúwe Nípa Àwọn Tálẹ́ńtì Náà
OJÚ ÌWÉ 19 • ORIN: 101, 116
MAY 25-31, 2015
Máa Fi Ìdúróṣinṣin Ti Àwọn Arákùnrin Kristi Lẹ́yìn
OJÚ ÌWÉ 25 • ORIN: 107, 63
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Èyí Ni “Ọ̀nà Tí Ìwọ Tẹ́wọ́ Gbà”
▪ Ṣé Wàá “Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”?
Nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe ń fi ẹ̀kọ́ tó ṣe kedere tó sì rọrùn láti lóye tọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ́nà. Àpilẹ̀kọ kejì máa dá lórí àkàwé tí Jésù ṣe nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà àti bó ṣe lè jẹ́ ká wà lójúfò nípa tẹ̀mí lóde òní.
▪ Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpèjúwe Nípa Àwọn Tálẹ́ńtì Náà
▪ Máa Fi Ìdúróṣinṣin Ti Àwọn Arákùnrin Kristi Lẹ́yìn
Nígbà tí Jésù ń sọ àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀, ó sọ àpèjúwe méjì tá a máa gbé yẹ̀ wò. Ọ̀kan dá lórí àwọn ẹrú tí ọ̀gá wọn fún ní àwọn tálẹ́ńtì, èkejì sì dá lórí yíya àwọn ẹni bí àgùntàn sọ́tọ̀ lọ́dọ̀ àwọn ẹni bí ewúrẹ́. Àpilẹ̀kọ wọ̀nyí máa jẹ́ ká mọ ìdí tí Jésù fi sọ àwọn àpèjúwe yìí àti bó ṣe kàn wá.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 A Rí Ohun Míì Tó Sàn Jù Tá A Fi Ìgbésí Ayé Wa Ṣe
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìn-àjò máa ń wá sí ìlú Copán kí wọ́n lè wo bí àwókù ìlú náà ṣe rí kó tó di pé Christopher Columbus ṣèbẹ̀wò síbẹ̀, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa retí ọjọ́ iwájú
HONDURAS
IYE ÈÈYÀN
8,111,000
IYE AKÉDE
22,098
IYE ÀWỌN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ DÉÉDÉÉ
3,471
Sípáníìṣì ni èdè àjùmọ̀lò ní orílẹ̀-èdè Honduras. Àmọ́ ìjọ méjìlá tó ní akéde ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti márùndínláàádọ́rin [365] ló ń fi èdè Garifuna ṣe ìpàdé. Bákan náà, ìjọ mọ́kànlá àti àwùjọ mẹ́ta kan tún wà tó ń lo Ède Adití Lọ́nà Ti Honduras