Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
July 15, 2015
© 2015 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
AUGUST 31, 2015–SEPTEMBER 6, 2015
Bá A Ṣe Lè Fi Kún Ẹwà Párádísè Tẹ̀mí
OJÚ ÌWÉ 7
SEPTEMBER 7-13, 2015
OJÚ ÌWÉ 14
SEPTEMBER 14-20, 2015
Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Ìjọba Ọlọ́run
OJÚ ÌWÉ 22
SEPTEMBER 21-27, 2015
OJÚ ÌWÉ 27
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Bá A Ṣe Lè Fi Kún Ẹwà Párádísè Tẹ̀mí
Àwọn èèyàn Jèhófà ń gbé ní àyíká kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa tẹ̀mí nínú apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè fi ìmọrírì hàn ní kíkún fún ohun tí Jèhófà pèsè fún wa yìí, kí sì ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti fi kún ẹwà rẹ̀? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
▪ “Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!
Àpilẹ̀kọ yìí máa ṣàlàyé díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá tá à ń fojú sọ́nà fún. Ó tún máa jẹ́ ká rí ìdí tí àwọn èèyàn Ọlọ́run fi lè fìgboyà kojú ìpọ́njú ńlá.
▪ Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Ìjọba Ọlọ́run
Nínú ayé tí Sátánì ń darí rẹ̀ yìí, ohun tí àwọn èèyàn yàn láàyò yàtọ̀ síra. Àmọ́, àwọn Kristẹni tòótọ́ ti pinnu pé àwọn máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Àpilẹ̀kọ yìí máa ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tó yẹ kó máa wà lọ́kàn wa, ohun tó yẹ ká máa fi kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa àti ìdí tí a kì í fi í lọ́wọ́ sí awuyewuye tó ń lọ nínú ayé ká bàa lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run.
▪ Ibi Ìjọsìn Wa Rèé
Àwọn èèyàn Jèhófà máa ń péjọ pọ̀ fún ìjọsìn ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn ilé míì kárí ayé. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, á máa jíròrò àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́ táá jẹ́ ká mọ irú ojú tó yẹ ká máa fi wo àwọn ibi tá à ń lò fún ìjọsìn, bí a ó ṣe máa rí owó àti bí a ó ṣe máa tún wọn ṣe, ká lè máa fi ògo fún Jèhófà.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Rọ́ṣíà
12 Jọ́sìn Jèhófà ní “Àwọn Ọjọ́ Oníyọnu”
20 Ǹjẹ́ Ó Ṣe Pàtàkì Pé Kí Àwọn Èèyàn Rí Ohun Tó O Bá Ṣe?
32 Ǹjẹ́ O Mọ̀?
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Àwọn kan tó wà lóde ẹ̀rí ń dúró jẹ oúnjẹ ọ̀sán nígbà tí wọ́n lọ wàásù ní àwọn abúlé tó jìnnà réré ní àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù gbígbòòrò tó wà ní àgbègbè Siberia
RỌ́ṢÍÀ
IYE ÈÈYÀN
143,930,000
IYE AKÉDE