Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
September 15, 2015
© 2015 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
OCTOBER 26, 2015–NOVEMBER 1, 2015
Ǹjẹ́ Ò Ń Dé Ìwọ̀n Ìdàgbàsókè Tó Jẹ́ Ti Kristi?
OJÚ ÌWÉ 3
NOVEMBER 2-8, 2015
OJÚ ÌWÉ 8
NOVEMBER 9-15, 2015
‘Ẹ Dúró Gbọn-in Nínú Ìgbàgbọ́’
OJÚ ÌWÉ 13
NOVEMBER 16-22, 2015
Àwọn Ọ̀nà Wo Ni Jèhófà Ń Gbà Fìfẹ́ Hàn sí Wa?
OJÚ ÌWÉ 18
NOVEMBER 23-29, 2015
Báwo La Ṣe Lè Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
OJÚ ÌWÉ 23
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Ǹjẹ́ Ò Ń Dé Ìwọ̀n Ìdàgbàsókè Tó Jẹ́ Ti Kristi?
▪ Ṣé Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Ṣeé Gbára Lé?
Ó yẹ káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa sapá láti dàgbà dénú nípa tẹ̀mí kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ ẹ̀rí ọkàn tí Ọlọ́run fún wọn. Àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí sọ ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. A sì tún jíròrò bá a ṣe lè fi hàn pé a dàgbà dénú nípa tẹ̀mí àtàwọn ibi tó ti yẹ ká lo ẹ̀rí ọkàn wa.
▪ ‘Ẹ Dúró Gbọn-in Nínú Ìgbàgbọ́’
A lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì nípa ìgbàgbọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù nígbà tó gbìyànjú láti rìn lórí Òkun Gálílì. Àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó lè fi hàn bóyá ìgbàgbọ́ wa ti ń jó rẹ̀yìn àti bá a ṣe lè gbé e ró.
▪ Àwọn Ọ̀nà Wo Ni Jèhófà Ń Gbà Fìfẹ́ Hàn sí Wa?
▪ Báwo La Ṣe Lè Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
À ń rí ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ tó ga jù lọ nínú ìgbésí ayé wa torí a mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, àwa náà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí, a máa jíròrò àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fìfẹ́ hàn sí wa àti bó ṣe yẹ káwa náà máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Àwọn ọmọ ilẹ̀ Ítálì tí wọ́n wà ní ìjọ tó ń sọ èdè Chinese ń bá àwọn tó rìnrìn-àjò afẹ́ wá sí ìlú Róòmù sọ̀rọ̀. Lóṣooṣù, ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló ń wá sídìí àwọn ohun tá a fi ń pàtẹ ìwé wa tá a gbé sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ilé àtijọ́
ÍTÁLÌ
IYE ÈÈYÀN
60,782,668
IYE AKÉDE
251,650
IYE ÀWỌN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ
33,073
Àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún [24,000] ń fi èdè ilẹ̀ òkèèrè mẹ́tàdínlógójì [37] wàásù ìhìn rere níbẹ̀