Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
December 15, 2015
© 2015 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
FEBRUARY 1-7, 2016
Jèhófà Máa Ń Bá Àwa Èèyàn Sọ̀rọ̀
OJÚ ÌWÉ 4
FEBRUARY 8-14, 2016
OJÚ ÌWÉ 9
FEBRUARY 15-21, 2016
Máa Fi Ahọ́n Rẹ Sọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró
OJÚ ÌWÉ 18
FEBRUARY 22-28, 2016
OJÚ ÌWÉ 23
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Jèhófà Máa Ń Bá Àwa Èèyàn Sọ̀rọ̀
▪ Bíbélì Tó Rọrùn Láti Lóye
Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni Jèhófà ti ń lo onírúurú èdè láti bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí jẹ́ ká rí i pé báwọn èèyàn ṣe ń sọ onírúurú èdè ò mú kó ṣòro fún Ọlọ́run láti bá wọn sọ̀rọ̀. A tún máa rí bí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, tó fi mọ́ èyí tá a tún ṣe lọ́dún 2013 ṣe ń mú kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run àti ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé.
▪ Máa Fi Ahọ́n Rẹ Sọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró
Ọlọ́run fún gbogbo wa lẹ́bùn àgbàyanu kan, ìyẹn ni ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ. Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò nǹkan mẹ́ta nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wa. Àpilẹ̀kọ yìí tún sọ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ká máa lo ẹ̀bùn tó lágbára yìí láti yin Ọlọ́run ká sì máa fi ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́.
▪ Jèhófà Yóò Gbé Ọ Ró
Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé gbogbo wa la máa ń ṣàìsàn, kí la lè rí kọ́ látinú àwọn ìwòsàn tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ wọn sínú Bíbélì? Tí àwọn èèyàn bá fún wa nímọ̀ràn nípa ìlera wa, kí ló yẹ ká ṣe? Àpilẹ̀kọ yìí máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí á sì tún ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
14 Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Lọ́dún 2013
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Inú aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan ń dùn bó ṣe ń wàásù fún ìyá kan àtàwọn ọmọ rẹ̀. Èdè Sípáníìṣì àti Guarani ni wọ́n ń sọ tí wọ́n sì fi ń wàásù láwọn orílẹ̀-èdè náà
PARAGUAY
IYE ÈÈYÀN
6,800,236
IYE AKÉDE