ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp16 No. 3 ojú ìwé 3
  • Nígbà Tí Ẹnì Tó O Nífẹ̀ẹ́ Bá Kú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nígbà Tí Ẹnì Tó O Nífẹ̀ẹ́ Bá Kú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́?
    Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
  • ‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbé Pẹ̀lú Ẹ̀dùn-Ọkàn Mi?
    Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
  • Bó O Ṣe Lè Fara Da Ọgbẹ́ Ọkàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
wp16 No. 3 ojú ìwé 3
Obìnrin kan tó ń ṣọ̀fọ̀

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Nígbà Tí Ẹni Tó O Nífẹ̀ẹ́ Bá Kú

“Ọlọ́run ló yé, ọmọ. Yéé sunkún.”

Ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ fún obìnrin kan tó ń jẹ́ Bebe nìyẹn níbi tí wọ́n ti lọ sin bàbá rẹ̀ tó kú nínú ìjàǹbá ọkọ̀.

Mọ̀lẹ́bí tó sún mọ́ ìdílé Bebe bí iṣan ọrùn ló sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Bebe. Àmọ́ kàkà kí ọ̀rọ̀ náà tù ú nínú, ńṣe ló tún dá kún ọgbẹ́ ọkàn rẹ̀ torí pé òun àti bàbá rẹ̀ sún mọ́ ara wọn gan-an. Gbogbo ìgbà ni Bebe máa ń sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Ikú bàbá mi yìí ò dáa.” Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ó kọ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sínú ìwé kan, èyí sì fi hàn pé ọgbẹ́ ọkàn rẹ̀ kò tíì sàn.

Bíi ti Bebe, ó máa ń pẹ́ kéèyàn tó lè gbé ìbànújẹ́ tí ikú ń fà kúrò lára, pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹni tó sún mọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ló kú. Bíbélì tiẹ̀ dìídì pé ikú ní “ọ̀tá ìkẹyìn.” (1 Kọ́ríńtì 15:26) Ìgbà téèyàn kò ronú rẹ̀ ni ikú máa ń ṣọṣẹ́, kò sì sí ohun tá a lè ṣe tí ikú bá dé. Ó máa ń dà bíi pé àwọn tá a fẹ́ràn jù ló ń pa. Kò sì sẹ́ni tó bọ́ lọ́wọ́ ikú. Torí náà, ó lè má rọrùn láti gbé e kúrò lọ́kàn nígbà tẹ́ni tá a fẹ́ràn bá kú.

Ó ṣeé ṣe kó o máa ronú pé: ‘Báwo ló ṣe máa ń pẹ́ tó kéèyàn tó lè gbé ìbànújẹ́ náà kúrò lọ́kàn? Báwo lèèyàn ṣe lè fara da ọgbẹ́ ọkàn yìí? Báwo ni mo ṣe lè tu ẹni téèyàn rẹ̀ kú nínú? Ṣé ìrètí kankan wà fún àwọn èèyàn wa tó ti kú?’

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́