ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • we ojú ìwé 20-25
  • Báwo Ni Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́?
  • Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Ó Yẹ Láti Ṣe . . .
  • Ohun Tí Kò Yẹ Láti Ṣe . . .
  • Ìrẹ̀lẹ́kún Láti Ọ̀dọ̀ “Ọlọrun Ìtùnú Gbogbo”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Máa Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú bí Jésù Ti Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • ‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Bó O Ṣe Lè Fara Da Ọgbẹ́ Ọkàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
Àwọn Míì
Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
we ojú ìwé 20-25

Báwo Ni Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́?

“BÍ OHUNKÓHUN bá wà ti mo lè ṣe, ṣáà jẹ́ kí n mọ̀.” Èyí ni ohun tí púpọ̀ nínú wa ń sọ fún ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ̀. Óò ohun tí a ní lọ́kàn níyẹn níti tòótọ́. A óò ṣe ohunkóhun láti ṣèrànwọ́. Ṣùgbọ́n ẹni ti ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ha ti pè wá kí ó sì sọ pé: “Mo ti ronú ohun kan tí o lè ṣe láti ràn mi lọ́wọ́”? Kò wọ́pọ̀. Ní kedere, a níláti gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan bí a óò bá ṣètìlẹyìn kí a sì tu ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà nínú ní tòótọ́.

Owe Bibeli kan sọ pé: “Bí èso igi wúrà nínú agbọ̀n fàdákà, bẹ́ẹ̀ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò rẹ̀.” (Owe 15:23; 25:11) Ọgbọ́n wà nínú mímọ ohun tí ó yẹ láti sọ àti ohun tí kò yẹ láti sọ, ohun tí ó yẹ láti ṣe, àti ohun tí kò yẹ láti ṣe. Àwọn àbá mélòókan nìyí tí a gbékarí Ìwé Mímọ́ tí àwọn ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ti rí pé ó ṣèrànwọ́.

Ohun Tí Ó Yẹ Láti Ṣe . . .

Fetísílẹ̀: “Yára láti gbọ́,” ni Jakọbu 1:19 sọ. Ọ̀kan lára àwọn ohun tí ń ṣèrànwọ́ jùlọ tí o lè ṣe láti ṣàjọpín ìrora ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà ni nípa fífetísílẹ̀. Àwọn ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lè fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa olólùfẹ́ wọn tí ó ti kú, nípa jàm̀bá tàbí àìsàn tí ó fa ikú rẹ̀, tàbí nípa ìmọ̀lára wọn láti ìgbà ikú rẹ̀. Nítorí náà béèrè pé: “Ìwọ yóò ha fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bí?” Jẹ́ kí wọn pinnu. Ní rírántí ìgbà tí baba rẹ̀ kú, ọ̀dọ́kùnrin kan sọ pé: “Ó ṣèrànwọ́ fún mi níti gidi nígbà tí àwọn ẹlòmíràn béèrè ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tí wọ́n sì fetísílẹ̀ níti gidi.” Fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti pẹ̀lú ìbákẹ́dùn fetísílẹ̀ láì fi dandan ronú pé o níláti pèsè àwọn ìdáhùn tàbí ojútùú. Fún wọn ni àyè láti sọ ohunkóhun tí wọ́n fẹ́ láti ṣàjọpín.

Pèsè ìdánilójú: Fi dá wọn lójú pé wọ́n ṣe gbogbo ohun tí ó ṣeéṣe (tàbí ohunkóhun mìíràn tí o mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì gbéniró). Fi dá wọn lójú pé ohun tí wọ́n ń nímọ̀lára rẹ̀​—ìbànújẹ́, ìbínú, ẹ̀bi, tàbí èrò-ìmọ̀lára mìíràn​—⁠lè má jẹ́ ohun tí ojú kò rírí. Sọ fún wọn nípa àwọn ẹlòmíràn tí o mọ̀ tí wọ́n fi pẹ̀lú àṣeyọrí jèrè ìkọ́fẹpadà láti inú irú òfò kan náà. Irú àwọn “ọ̀rọ̀ dídùn” bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ìlera fún egungun,” ni Owe 16:24 sọ.​—1 Tessalonika 5:11, 14.

Wà lárọ̀ọ́wọ́tó: Mú araàrẹ wà lárọ̀ọ́wọ́tó, kìí ṣe fún àwọn ọjọ́ díẹ̀ àkọ́kọ́ nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí wà níbẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n ní àwọn oṣù lẹ́yìn náà nígbà tí àwọn mìíràn ti padà sẹ́nu ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́. Ní ọ̀nà yìí ìwọ fi araàrẹ hàn ní “ọ̀rẹ́” tòótọ́, ọ̀kan tí ń dúró ti ọ̀rẹ́ kan nígbà “ìpọ́njú.” (Owe 17:17) “Àwọn ọ̀rẹ́ wa ríi dájú pe àwọn alẹ́ wa kún fún ìgbòkègbodò kí a má baà lo àkókò púpọ̀jù ni àwa nìkan nínú ilé,” ni Teresea ẹni tí ọmọ rẹ̀ kú nínú ìjàm̀bá mọ́tò ṣàlàyé. “Ìyẹn ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìmọ̀lára àìwúlò tí a ní.” Fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ọjọ́ ayẹyẹ ìrántí, bí ayẹyẹ ìrántí ọjọ́ ìgbéyàwó tàbí déètì tí ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ọjọ́ tí ẹni náà kú, lè jẹ́ àkókò lílekoko fún àwọn aláṣẹ̀yìndè. Èéṣe tí o kò sàmì sí àwọn ọjọ́ yẹn lórí kàlẹ́ńdà rẹ kí ó baà lè jẹ́ pé nígbà tí àwọn ọjọ́ yẹn bá pé, ìwọ yóò lè wà ni àrọ́wọ́tó, fún ìbákẹ́dùn onítìlẹyìn?

Tọkọtaya kan ń bá ọkùnrin kan ṣe àwọn iṣẹ́ ilé

Bí o bá fòye mọ àìní pàtàkì kan, máṣe dúró di ìgbà tí a bá bi ọ́​—lo ọgbọ́n àtinúdá tí ó yẹ

Lo ọgbọ́n àtinúdá tí ó yẹ: Àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan ha wà láti bójútó bí? A ha nílò ẹnìkan láti bójútó àwọn ọmọ bí? Àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí tí ń ṣèbẹ̀wò ha nílò ibìkan láti dé sí bí? Àwọn ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ̀ ni jìnnìjìnnì sábà máa ń mú débi pé wọn kò tilẹ̀ mọ ohun tí wọ́n níláti ṣe, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé kí wọn sọ ohun tí àwọn ẹlòmíràn lè ṣe láti ṣèrànwọ́. Nítorí náà bí o bá fòye mọ àìní pàtàkì kan, máṣe dúró di ìgbà tí a bá sọ fún ọ; lo ọgbọ́n àtinúdá. (1 Korinti 10:24; fiwé 1 Johannu 3:17, 18.) Obìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ ti kú rántí pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sọ pé, ‘Bí ohunkóhun bá wà ti mo lè ṣe, jẹ́ kí n gbọ́.’ Ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan kò béèrè. Ó lọ tààràtà sínú iyàrá, ó ká bẹ́ẹ̀dì náà kúrò, ó sì fọ àwọn aṣọ ìtẹ́-bẹ́ẹ̀dì náà ti ikú rẹ̀ ti dọ̀tí. Òmíràn gbé korobá, omi àti àwọn ohun-èèlò fún fífọ nǹkan mọ́, ó sì fọ rọ́ọ̀gì náà níbi ti ọkọ mi ti bì sí. Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ wá pẹ̀lú aṣọ iṣẹ́ àti àwọn irin-iṣẹ́ rẹ̀ ó sì wí pé, ‘Mo mọ̀ pé ohun kan níláti wà tí yóò nílò kíkàn. Kí ni ohun náà?’ Ẹ wo bí ọkùnrin náà ti jẹ́ ọ̀wọ́n fún ọkàn-àyà mi tó fún títún ilẹ̀kùn tí ń mì dirodiro lórí àṣígbè àti ohun-èèlò iná mànàmáná tí ó wà lára ilé ṣe!”​—Fiwe Jakọbu 1:27.

Jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣíṣe: “Ẹ máṣe gbàgbé láti máa ṣe àlejò,” ni Bibeli rán wa létí. (Heberu 13:2) A níláti rántí ní pàtàkì láti ṣe àwọn ẹni tí ń kẹ́dùn ní àlejò. Dípò ìkésíni “wá nígbàkigbà,” dá ọjọ́ àti àkókò. Bí wọ́n bá kọ̀, máṣe jáwọ́ ni kíákíá. Wọ́n lè nílò ìṣírí díẹ̀. Bóyá wọn kọ ìkésíni rẹ sílẹ̀ nítorí pé wọ́n ń bẹ̀rù pípàdánù ìṣàkóso èrò-ìmọ̀lára wọn lójú àwọn ẹlòmíràn. Tàbí wọ́n lè nímọ̀lára ẹ̀bi nípa gbígbádùn oúnjẹ àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ní irú àkókò bẹ́ẹ̀. Rántí obìnrin tí ó jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣíṣe náà Lidia tí a mẹ́nukàn nínú Bibeli. Lẹ́yìn tí ó ti késí wọn wá sí ilé rẹ̀, Luku sọ pé, “Ó sì mú kí a wá ṣáá ni.”​—Iṣe 16:15, NW.

Jẹ́ onísùúrù àti olóye: Máṣe jẹ́ kí ohun tí àwọn ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ sọ lákọ̀ọ́kọ́ yà ọ́ lẹ́nu. Rántí pé, wọ́n lè máa bínú kí wọn sì nímọ̀lára ẹ̀bi. Bí wọ́n bá fi ìkanra mọ́ ọ, yóò gba òye-inú àti sùúrù ní ìhà ọ̀dọ̀ rẹ láti máṣe fi ìbínú dáhùnpadà. “Ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìṣeun, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù, ìpamọ́ra,” ni Bibeli dámọ̀ràn.​—Kolosse 3:12, 13.

Kọ lẹ́tà: Ohun tí a sábà máa ń gbójúfòdá ni ìníyelórí lẹ́tà ìbánidárò tàbí káàdì ìbánikẹ́dùn. Àǹfààní wo ni ó ní? Cindy, ẹni tí àrùn jẹjẹrẹ mú kí ó pàdánù ìyá rẹ̀ dáhùn pé: “Ọ̀rẹ́ kan kọ lẹ́tà dáradára kan sí mi. Ìyẹn ràn mí lọ́wọ́ níti gidi nítorí pé mo lè kà á ní àkàtúnkà.” Irú lẹ́tà tàbí káàdì ìṣírí bẹ́ẹ̀ ni o lè kọ ní ‘ọ̀rọ̀ kúkúrú,’ ṣùgbọ́n ó níláti sọ ohun tí ó wà nínú ọkàn-àyà rẹ. (Heberu 13:22) Ó lè kà pé o bìkítà àti pé o ni àkànṣe ìrántí nípa olóògbé náà, tàbí ó lè ṣàfihàn bí ẹni tí ó kú náà ti ṣe nípalórí ìgbésí-ayé rẹ.

Gbàdúrà pẹ̀lú wọn: Máṣe fojúkéré ìníyelórí àdúrà rẹ pẹ̀lú àti fún àwọn ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Bibeli sọ pé: “Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń ṣe ní agbára púpọ̀.” (Jakọbu 5:16) Fún àpẹẹrẹ, gbígbọ́ tí wọ́n ń gbọ́ pé o ń gbàdúrà nípa wọn lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dín ìmọ̀lára òdì irú bí ẹ̀bi kù.​—Fiwé Jakọbu 5:13-15.

Ohun Tí Kò Yẹ Láti Ṣe . . .

Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ ń tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú ní ilé ìwòsàn

Wíwà tí o wà ní ilé-ìwòsàn lè jẹ́ ìṣírí fún ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀

Máṣe sá nítorí tí ìwọ kò mọ ohun tí o níláti sọ tàbí ṣe: ‘Ó dá mi lójú pé wọn kò fẹ́ ìyọnu báyìí ná,’ ni a lè sọ fún araawa. Ṣùgbọ́n bóyá òtítọ́ náà ni pé a ń sá nítorí pé a ń bẹ̀rù sísọ tàbí ṣíṣe ohun tí kò tọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, fún ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà láti di ẹni tí àwọn ọ̀rẹ́, mọ̀lẹ́bí, tàbí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yẹra fún túbọ̀ lè mú kí ó nímọ̀lára ìdánìkanwà, kí ó sì pakún ìrora náà. Rántí pé, àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe onínúrere jùlọ sábà máa ń jẹ́ àwọn tí ó rọrùn jùlọ. (Efesu 4:32) Wíwà níbẹ̀ rẹ nìkan lè jẹ́ orísun ìṣírí kan. (Fiwé Iṣe 28:15.) Ní rírántí ọjọ́ tí ọmọbìnrin rẹ̀ kú, Teresea sọ pé: “Láàárín wákàtí kan, àwọn ọ̀rẹ́ wa ti kún gbàgede ilé-ìwòsàn náà; gbogbo àwọn alàgbà àti àwọn aya wọn ni wọ́n wà níbẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn obìnrin náà kò tilẹ̀ yọ àwọn róláàsì irun wọn kúrò, àwọn kan wà nínú aṣọ iṣẹ́ wọn. Wọ́n pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì wá. Ọ̀pọ̀ nínú wọn sọ fún wa pé àwọn kò mọ ohun tí wọ́n lè sọ, ṣùgbọ́n kò ṣe nǹkankan, wíwà níbẹ̀ wọn nìkan ti tó.”

Máṣe fipá mú wọn láti dáwọ́ ẹ̀dùn-ọkàn wọn dúró: ‘Ó ti tó, ó ti tó, ó ti tó ná, má sọkún mọ́,’ ni a lè fẹ́ láti sọ. Ṣùgbọ́n ó lè dárajù láti jẹ́ kí omije máa dà. “Mo rò pé ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ kí àwọn ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ fi èrò-ìmọ̀lára wọn hàn kí wọ́n sì tú u jáde,” ni Katherine sọ, ni ríronú lórí ikú ọkọ rẹ̀. Gbéjàko ìtẹ̀sí náà láti sọ bí àwọn ẹlòmíràn ṣe níláti nímọ̀lára fún wọn. Má sì ṣe rò pé o níláti fi ìmọ̀lára tìrẹ pamọ́ láti baà lè dáàbòbò tiwọn. Dípò èyí, “àwọn tí ń sọkún, ẹ máa bá wọn sọkún,” ni Bibeli dámọ̀ràn.​—Romu 12:15.

Máṣe tètè fún wọn ní ìmọ̀ràn láti kó aṣọ tàbí àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti olóògbé náà dànù ṣáájú kí wọ́n tó ṣetán láti ṣe bẹ́ẹ̀: A lè rò pé yóò dárajù fún wọn láti kó àwọn ohun tí yóò fa ìrántí dànù nítorí wọ́n máa ń fa ẹ̀dùn-ọkàn gùn. Ṣùgbọ́n òwe náà “Bí etí kò bá gbọ yìnkìn inú kìí bàjẹ́” lè má wọlé nínú ọ̀ràn yìí. Ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà lè fẹ́ mọ́kàn kúrò lára olóògbé náà ní díẹ̀díẹ̀. Rántí bí Bibeli ṣe ṣàpèjúwe ìhùwàpadà babańlá ìgbàanì Jakobu nígbà tí a mú kí ó gbàgbọ́ pe ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ̀ Josefu ni ẹranko ẹhànnà ti pajẹ. Lẹ́yìn tí a ti fi aṣọ Josefu tí ẹ̀jẹ̀ ti rin gbingbin han Jakobu, “ó ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ púpọ̀. Àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin dìde láti ṣìpẹ̀ fún un; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbìpẹ̀.”​—Genesisi 37:31-35.

Máṣe sọ pé, ‘O lè bí ọmọ mìíràn’: “Inú bí mi nígbà tí àwọn ènìyàn sọ fún mi pé mo lè bí ọmọ mìíràn,” ni ìyá kan tí ó pàdánù ọmọ rẹ̀ nínú ikú rántí. Ó lè jẹ́ ète rere ni wọ́n ní lọ́kàn, ṣùgbọ́n fún òbí tí ń kẹ́dùn náà, àwọn ọ̀rọ̀ tí ó túmọ̀sí pé ọmọ tí kò sí mọ́ náà ni a lè rọ́pò lè ‘gúnni bí idà.’ (Owe 12:18) Ọmọ kan kò lè rọ́pò òmíràn láé. Èéṣe? Nítorí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni olúkúlùkù.

Máṣe fi dandan yẹra fún dídárúkọ olóògbé náà: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò tilẹ̀ dárúkọ ọmọkùnrin mi Jimmy tàbí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀,” ní ìyá kan rántí. “Kí n sòótọ́ ó ta mi lára díẹ̀ nígbà tí àwọn mìíràn ṣe bẹ́ẹ̀.” Nítorí náà máṣe fi dandan yí kókó ọ̀rọ̀ náà padà nígbà tí a bá dárúkọ olóògbé náà. Béèrè lọ́wọ́ ẹni náà bóyá ó fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa olólùfẹ́ rẹ̀. (Fiwé Jobu 1:18, 19 àti 10:1.) Àwọn kan tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ mọrírì gbígbọ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ àrà-ọ̀tọ̀ tí ó mu kí wọn fẹ́ràn olóògbé náà.​—Fiwé Iṣe 9:36-39.

Máṣe tètè sọ pé, ‘Fún ire ni’: Gbígbìyànjú láti wá ohun kan tí ó gbéniró nípa ikú náà kìí fìgbà gbogbo jẹ́ ‘rírẹ awọn ọkàn tí ó soríkọ́’ tí wọ́n ń kẹ́dùn ‘lẹ́kún.’ (1 Tessalonika 5:14, NW) Ní rírántí ìgbà tí ìyá rẹ̀ kú, ọ̀dọ́bìnrin kan sọ pé: “Àwọn mìíràn yóò sọ pé, ‘Kò jìyà mọ́’ tàbí, ‘Ó ṣetán ó ń sinmi ni.’ Ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ láti gbọ́ ìyẹn.” Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè túmọ̀sí pé kí àwọn aláṣẹ̀yìndè máṣe banújẹ́ tàbí pé àdánù náà kò ṣe pàtàkì. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n lè máa banújẹ́ gidigidi nítorí àárò olólùfẹ́ wọn ń sọ wọn.

Ó lè dárajù láti má sọ pé, ‘Mo mọ bí ìmọ̀lára rẹ ṣe rí’: “Ìwọ ha mọ̀ ọ́n níti gidi bí? Fún àpẹẹrẹ, ó ha ṣeéṣe fún ọ láti mọ ohun ti òbí kan ń nímọ̀lára nígbà tí ọmọ kan bá kú bí ìwọ fúnraàrẹ kò bá tíì ní ìrírí irú àdánù bẹ́ẹ̀? Kódà bí ìwọ bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé àwọn ẹlòmíràn lè má nímọ̀lára bíi tìrẹ gẹ́lẹ́. (Fiwé Ẹkún Jeremiah 1:12.) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí o bá ríi pé ó yẹ, ó lè ṣànfààní láti sọ bí o ṣe kọ́fẹpadà láti inú àdánù ẹnìkan tí o fẹ́ràn. Obìnrin kan tí wọ́n pa ọmọbìnrin rẹ̀ rí i pé òun rí ìtùnú gbà nígbà tí ìyá ọmọbìnrin mìíràn tí ó ti kú sọ fún un nípa ìkọ́fẹpadà tirẹ̀ sínú ìgbòkègbodò ìgbésí-ayé ojoojúmọ́. Ó wí pé: “Ìyá tí ọmọbìnrin rẹ̀ kú yìí kò nasẹ̀ ìtàn rẹ̀ ní sísọ pé ‘Mo mọ bí ìmọ̀lára rẹ ṣe rí.’ Ó wulẹ̀ sọ bí nǹkan ṣe rí fún un fún mi ni, ó sì jẹ́ kí ń fi wọ́n wé tèmi.”

Ríran ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lọ́wọ́ ń béèrè fún ìyọ́nú, ìwòyemọ̀, àti ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ ní ìhà ọ̀dọ̀ rẹ. Máṣe dúró de ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà láti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ. Máṣe wulẹ̀ sọ pé, “Bí ohunkóhun bá wà ti mo lè ṣe . . .” Wá “ohunkóhun” yẹn rí fúnraàrẹ kí o sì gbé ìgbésẹ̀ tí ó yẹ.

Àwọn ìbéèrè kan ṣì ṣẹ́kù: Níti ìrètí Bibeli fún àjíǹde ńkọ́? Kí ni ó lè túmọ̀sí fún ọ àti olólùfẹ́ rẹ tí ó ti kú? Báwo ni a ṣe lè ní ìdánilójú pé ìrètí tí ó ṣeé gbọ́kànlé ni?

Àwọn Ìbéèrè Láti Ronú Lé Lórí

  • Èéṣe tí ó fi ṣèrànwọ́ láti ṣàjọpín ìbànújẹ́ ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nípa fífetísílẹ̀?

  • Kí ni àwọn ohun díẹ̀ tí a lè ṣe láti baà lè tu ẹni tí ń kẹ́dùn nínú?

  • Kí ni a níláti yẹra fún ní sísọ tàbí ní ṣíṣe fún ẹnìkan tí ń ṣọ̀fọ̀?

Ríran Àwọn Ọmọ Lọ́wọ́ Láti Kojú Ikú

Nígbà tí ikú bá kọlu ìdílé kan, àwọn òbí àti àwọn mọ̀lẹ́bí àtí àwọn ọ̀rẹ́ pàápàá kìí sábà mọ ohun tí wọn yóò sọ tàbí ṣe láti ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti kojú ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Síbẹ̀, àwọn ọmọ nílò àwọn àgbàlagbà láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú ikú. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tí a sábà máa ń béèrè nípa ríran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti lóye ikú.

Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàlàyé ikú fún àwọn ọmọ? Ó ṣe pàtàkì láti ṣàlàyé àwọn ọ̀ràn ní àwọn èdè tí ó rọrùn. Jẹ́ kí ó jẹ́ òótọ́ pẹ̀lú. Máṣe lọ́tìkọ̀ láti lo àwọn ọ̀rọ̀ gidi náà, bí “òkú” àti “ikú.” Fún àpẹẹrẹ, ìwọ lè jókòó pẹ̀lú ọmọ náà, fi apá gbá a mọ́ra, kí o sì sọ pé: “Ohun ìbànújẹ́ gidigidi kan, tí ó burú ti ṣẹlẹ̀. Baba ṣàìsàn pẹ̀lú àrùn kan tí kìí ṣe ọ̀pọ̀ ènìyàn [tàbí ohunkóhun tí o bá mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́], ó sì ti kú. Kìí ṣe ẹ̀bi ẹnìkankan pé ó kú. A óò ṣàárò rẹ̀ gan-an ni nítorí tí a fẹ́ràn rẹ̀, òun náà sì fẹ́ràn wa.” Bí ó ti wù kí ó rí, ó lè ṣèrànwọ́ láti ṣàlàyé pé ṣíṣàìsàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kò wulẹ̀ túmọ̀sí pé ọmọdé náà tàbí òbí rẹ̀ tí ó wàláàyè yóò kú.

Fún wọn níṣìírí láti béèrè àwọn ìbéèrè. ‘Kí ni ń jẹ́ ikú?’ ni wọ́n lè béèrè. Ìwọ lè dáhùn ní ọ̀nà yìí: “‘Ikú’ túmọ̀sí pé ara ṣíwọ́ iṣẹ́ tí kò sì lè ṣe àwọn ohun tí ó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀​—kò lè sọ̀rọ̀, ríran, tàbí gbọ́rọ̀, kò sì lè nímọ̀lára ohunkóhun.” Òbí kan tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí àjíǹde inú Bibeli lè lo àǹfààní yìí láti ṣàlàyé pé Jehofa Ọlọrun yóò rántí olóògbé náà ó sì lè mú un padà wá sí ìyè nínú Paradise orí ilẹ̀-ayé ní ọjọ́-ọ̀la. (Luku 23:43; Johannu 5:28, 29)​—Wo ẹ̀ka náà “Ìrètí Tí Ó Dájú fún Àwọn Òkú.”

Ohunkóhun ha wà tí ìwọ kò níláti sọ bí? Kò ṣèrànwọ́ láti sọ pé aláìsí náà ti ràjò jíjìnnà. Ìbẹ̀rù dídi ẹni tí a patì jẹ́ àníyàn pàtàkì fún ọmọdé kan, pàápàá nígbà tí òbí kan bá kú. Láti sọ fún un pé aláìsí náà ti ràjò lè wulẹ̀ pakún ìmọ̀lára ìpatì tí ọmọ náà ní ó sì lè ronú pé: ‘Màmá àgbà lọ, kò sì tilẹ̀ lè sọ pé ó dàbọ̀!’ Ṣọ́ra, pẹ̀lú àwọn ọmọdé, nípa sísọ pé olóògbé náà ti lọ sùn. Àwọn ọmọdé máa ń gbà ọ̀rọ̀ ní bí wọ́n ṣe gbọ. Bí ọmọ kan bá ka orun sí ọgbọọgba pẹ̀lú ikú, ó lè yọrísí bíbẹ̀rù láti lọ sùn ní alẹ́.

Àwọn ọmọ ha níláti lọ sí ibi ètò ìsìnkú bí? Àwọn òbí níláti gba àwọn ìmọ̀lára àwọn ọmọ náà yẹ̀wò. Bí wọn kò bá fẹ́ láti lọ, máṣe fi ipá mú wọn tàbí mú kí wọn ní ìmọ̀lára ẹ̀bi fún kíkùnà láti lọ. Bí wọ́n bá fẹ́ láti lọ, ṣàlàyé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún wọn lẹ́kùn-⁠únrẹ́rẹ́, títí kan bóyá pósí yóò wà àti bóyá wọn yóò ṣí i tàbí pa á dé. Ṣàlàyé, pẹ̀lú, pé wọ́n lè rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń sọkún nítorí inú wọn bàjẹ́. Lẹ́ẹ̀kan síi, jẹ́ kí wọn béèrè àwọn ìbéèrè. Sì fi dá wọn lójú pé wọ́n lè fi ibẹ̀ sílẹ̀ bí wọ́n bá fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Báwo ni àwọn ọmọdé ṣe ń hùwàpadà sí ikú? Àwọn ọmọdé sábà máa ń nímọ̀lára pé àwọn ni ó fa ikú olólùfẹ́ kan. Nítorí pé ọmọ náà ti lè bínú rí nígbà kan tàbí òmíràn sí ẹni tí ó kú náà, ọmọ náà lè wá rò pé àwọn ìrònú oníbìínú tàbí àwọn ọ̀rọ̀ ìbínú ní ó fa ikú náà. Ìwọ lè níláti pèsè ìtùnú díẹ̀: ‘Àwọn èrò àti ọ̀rọ̀ rẹ kọ́ ni ó mú kí àwọn ènìyàn ṣàìsàn, wọn kò sì mú kí àwọn ènìyàn kú.’ Ọmọdé kékeré kan lè nílò ìmúdánilójú bẹ́ẹ̀ léraléra.

Ìwọ ha níláti fi ẹ̀dùn-ọkàn rẹ pamọ́ fún àwọn ọmọ bí? Sísọkún lójú àwọn ọmọ bójúmu ó sì dára. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò ṣeéṣe láti fi àwọn ìmọ̀lára rẹ pamọ́ fún àwọn ọmọ pátápátá; wọ́n ní ìtẹ̀sí láti fòye mọ nǹkan wọ́n sì sábà máa ń fura pé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀. Jíjẹ́ olóòótọ́ nípa ẹ̀dùn-ọkàn rẹ ń jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ó bójúmu láti ní ẹ̀dùn-ọkàn àti láti fi àwọn ìmọ̀lára rẹ hàn nígbà mìíràn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́