ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp16 No. 3 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ọlọ́run ní orúkọ?
  • Ṣé ó burú tá a bá pe orúkọ Ọlọ́run?
  • Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2017
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Idi Tí A Fi Gbọdọ Mọ Orukọ Ọlọrun
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Kí Ni Orúkọ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
wp16 No. 3 ojú ìwé 16
Orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì àfọwọ́kọ ayé ìgbàanì

Bí wọ́n ṣe kọ orúkọ Ọlọ́run sínú Bíbélì àfọwọ́kọ layé àtijọ́

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ṣé Ọlọ́run ní orúkọ?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ Ọlọ́run kò lórúkọ, àwọn míì sọ pé orúkọ rẹ̀ ni Ọlọ́run tàbí Olúwa, àwọn míì sì sọ pé orúkọ Ọlọ́run pọ̀ lọ súà. Kí lèrò rẹ?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 83:18.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

  • Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ní orúkọ oyè tó pọ̀, orúkọ kan ṣoṣo ló fún ara rẹ̀.—Ẹ́kísódù 3:15.

  • Ọlọ́run kì í ṣe àwámáàrídìí; ó fẹ́ ká mọ òun.—Ìṣe 17:27.

  • Ọ̀nà kan tá a lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run ni pé ká kọ́kọ́ mọ orúkọ rẹ̀.—Jákọ́bù 4:8.

Ṣé ó burú tá a bá pe orúkọ Ọlọ́run?

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́

  • Mi ò mọ̀

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò ní láárí.” (Ẹ́kísódù 20:7) Ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà lo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí kò dáa ni tí kò bá bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀.—Jeremáyà 29:9.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

  • Jésù mọ orúkọ Ọlọ́run, ó sì lò ó. —Jòhánù 17:25, 26.

  • Ọlọ́run fẹ́ ká máa fi orúkọ tí òun jẹ́ pe òun. —Sáàmù 105:1.

  • Àwọn ọ̀tá Ọlọ́run fẹ́ mú kí àwọn èèyàn gbàgbé orúkọ Ọlọ́run.—Jeremáyà 23:27.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 1 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́